YouVersion Logo
Search Icon

II. Sam 23

23
Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Dafidi
1WỌNYI si li ọ̀rọ ikẹhin Dafidi. Dafidi ọmọ Jesse, ani ọkunrin ti a ti gbega, ẹni-ami-ororo Ọlọrun Jakobu, ati olorin didùn Israeli wi pe,
2Ẹmi Oluwa sọ ọ̀rọ nipa mi, ọ̀rọ rẹ̀ si mbẹ li ahọn mi.
3Ọlọrun Israeli ní, Apata Israeli sọ fun mi pe, Ẹnikan ti nṣe alakoso enia lododo, ti nṣakoso ni ibẹru Ọlọrun.
4Yio si dabi imọlẹ owurọ nigbati õrun ba là, owurọ ti kò ni ikũku, nigbati koriko tutu ba hù lati ilẹ wa nipa itanṣan lẹhin òjo.
5Lõtọ ile mi kò ri bẹ niwaju Ọlọrun, ṣugbọn o ti ba mi da majẹmu ainipẹkun, ti a tunṣe ninu ohun gbogbo, ti a si pamọ: nitoripe gbogbo eyi ni igbala mi, ati gbogbo ifẹ mi, ile mi kò le ṣe ki o ma dagbà?
6Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Beliali yio dabi ẹgún ẹ̀wọn ti a ṣatì, nitoripe a kò le fi ọwọ́ kó wọn.
7Ṣugbọn ọkunrin ti yio tọ́ wọn yio fi irin ati ọpa ọ̀kọ sagbàra yi ara rẹ̀ ka: nwọn o si jona lulu nibi kanna.
Àwọn Akọni Ọmọ Ogun Dafidi
(I. Kro 11:10-41)
8Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin alagbara ti Dafidi ni: ẹniti o joko ni ibujoko Takmoni ni olori awọn balogun, on si ni Adino Esniti ti o pa ẹgbẹ̀rin enia lẹ̃kan.
9Ẹniti o tẹ̀le e ni Eleasari ọmọ Dodo ara Ahohi, ọkan ninu awọn alagbara ọkunrin mẹta ti o wà pẹlu Dafidi, nigbati nwọn pe awọn Filistini ni ijà, awọn ti o kó ara wọn jọ si ibẹ lati jà, awọn ọmọkunrin Israeli si ti lọ kuro:
10On si dide, o si kọlù awọn Filistini titi ọwọ́ fi kún u, ọwọ́ rẹ̀ si lẹ̀ mọ idà: Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla li ọjọ na; awọn enia si yipada lẹhin rẹ̀ lati ko ikogun.
11Ẹniti o tẹ̀le e ni Samma ọmọ Agee ará Harari. Awọn Filistini si ko ara wọn jọ lati piyẹ, oko kan si wà nibẹ ti o kún fun ẹwẹ: awọn enia si sa kuro niwaju awọn Filistini.
12O si duro lagbedemeji ilẹ na, o si gbà a silẹ, o si pa awọn Filistini: Oluwa si ṣe igbala nla kan.
13Awọn mẹta ninu ọgbọ̀n olori si sọkalẹ, nwọn si tọ Dafidi wá li akoko ikore ninu iho Adullamu: ọ̀wọ́ awọn Filistini si do ni afonifoji Refaimu.
14Dafidi si wà ninu odi, ibudo awọn Filistini si wà ni Betlehemu nigbana.
15Dafidi si k'ongbẹ, o wi bayi pe, Tani yio fun mi mu ninu omi kanga ti mbẹ ni Betlehemu, eyi ti o wà ni ihà ẹnu-bodè?
16Awọn ọkunrin alagbara mẹta si la ogun awọn Filistini lọ, nwọn si fa omi lati inu kanga Betlehemu wá, eyi ti o wà ni iha ẹnu-bode, nwọn si mu tọ Dafidi wá: on kò si fẹ mu ninu rẹ̀, ṣugbọn o tú u silẹ fun Oluwa.
17On si wipe, Ki a ma ri, Oluwa, ti emi o fi ṣe eyi; ṣe eyi li ẹ̀jẹ awọn ọkunrin ti o lọ ti awọn ti ẹmi wọn li ọwọ́? nitorina on kò si fẹ mu u. Nkan wọnyi li awọn ọkunrin alagbara mẹtẹta yi ṣe.
18Abiṣai, arakunrin Joabu, ọmọ Seruia, on na ni pataki ninu awọn mẹta. On li o si gbe ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia, o si pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹtẹta.
19Ọlọlajulọ li on iṣe ninu awọn mẹtẹta: o si jẹ olori fun wọn: ṣugbọn on kò to awọn mẹta iṣaju.
20Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, on pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; o sọkalẹ pẹlu o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno.
21O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o tó wò: ara Egipti na si ni ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn on si sọkalẹ tọ̀ ọ lọ, ton ti ọ̀pá li ọwọ́, o si gba ọ̀kọ na lọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ tirẹ̀ pa a.
22Nkan wọnyi ni Benaia ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn ọkunrin alagbara mẹta nì.
23Ninu awọn ọgbọ̀n na, on ṣe ọlọlajulọ, ṣugbọn on kò to awọn mẹta ti iṣaju. Dafidi si fi i ṣe igbimọ̀ rẹ̀.
24Asaheli arakunrin Joabu si jasi ọkan ninu awọn ọgbọ̀n na; Elhanani ọmọ Dodo ti Betlehemu.
25Ṣamma ara Harodi, Elika ara Harodi.
26Helesi ara Palti, Ira ọmọ Ikkeṣi ara Tekoa,
27Abieseri ara Anetoti, Mebunnai Huṣatiti,
28Salmoni Ahohiti, Maharai ara Netofa,
29Helebu ọmọ Baana, ara Netofa, Ittai ọmọ Ribai ti Gibea ti awọn ọmọ Benjamini,
30Benaia ara Piratoni, Hiddai ti afonifoji,
31Abialboni ara Arba Asmafeti Barhumiti,
32Eliahba ara Saalboni, Jaṣeni Gisoniti, Jonatani,
33Ṣamma Harariti, Ahiamu ọmọ Ṣarari Harariti,
34Elifeleti ọmọ Ahasbai, ọmọ ara Maakha, Eliamu ọmọ Ahitofeli ara Giloni,
35Hesrai ara Kermeli, Paari ara Arba,
36Igali ọmọ Natani ti Soba, Bani ara Gadi,
37Sekeli ara Ammoni, Nahari ara Beeroti, ẹniti o nru ihamọra Joabu ọmọ Seruia.
38Ira ara Jattiri, Garebu ara Jattiri.
39Uria ara Hitti: gbogbo wọn jẹ mẹtadilogoji.

Currently Selected:

II. Sam 23: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in