YouVersion Logo
Search Icon

II. Pet Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Àwọn onigbagbọ àkọ́kọ́ tí wọ́n wà ní oríṣìíríṣìí ààyè ni a kọ Ìwé Keji láti Ọ̀dọ̀ Peteru sí. Pataki ohun tí ó fa kíkọ rẹ̀ ni ọ̀nà láti tako àwọn olùkọ́ni èké, ati irú ìwà ìṣekúṣe tí irú ẹ̀kọ́ èké wọn lè fà. Kí eniyan di ìmọ̀ tòótọ́ Ọlọrun ati ti Jesu Kristi mú nìkan ni òògùn ìṣòro yìí. Àwọn ẹ̀kọ́ yìí gbọdọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ti rí Jesu ní ojúkoojú tí wọ́n sì ti fi etí ara wọn gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Nǹkan kan tí ó gún ẹni tí ó kọ ìwé yìí lọ́kàn ni ohun tí àwọn kan ń sọ, pé Kristi kò ní pada wá mọ́. Ó ṣe àlàyé pé ìdí tí ó fi dàbí ẹni pé Kristi pẹ́ kí ó tó pada ni pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, ó fẹ́ kí gbogbo eniyan yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-2
Ìpè onigbagbọ 1:3-21
Àwọn olùkọ́ni èké 2:1-22
Ìpadàbọ̀ ìkẹyìn Kristi 3:1-18

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in