II. A. Ọba 3
3
Ogun láàrin Israẹli ati Moabu
1JEHORAMU, ọmọ Ahabu si bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria li ọdun kejidilogun Jehoṣafati, ọba Juda, o si jọba li ọdun mejila.
2O si ṣe buburu li oju Oluwa; ṣugbọn kì iṣe bi baba rẹ̀, ati bi iya rẹ̀: nitoriti o mu ere Baali ti baba rẹ̀ ti ṣe kuro.
3Ṣugbọn o fi ara mọ ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o mu Israeli dẹ̀ṣẹ; kò si lọ kuro ninu rẹ̀.
4Meṣa, ọba Moabu si nsìn agutan, o si nsan ọkẹ marun ọdọ-agutan, ati ọkẹ marun àgbo irun fun ọba Israeli.
5O si ṣe, nigbati Ahabu kú, ọba Moabu si ṣọ̀tẹ si ọba Israeli.
6Jehoramu ọba si jade lọ kuro ni Samaria li akoko na, o si ka iye gbogbo Israeli.
7O si lọ, o ranṣẹ si Jehoṣafati ọba Juda, wipe, Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ si mi: iwọ o ha bá mi lọ si Moabu lati jagun? On si wipe, Emi o gòke lọ: emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ati ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.
8On si wipe, Ọ̀na wo li awa o gbà gòke lọ? On si dahùn wipe, Ọ̀na aginju Edomu.
9Bẹ̃ni ọba Israeli lọ, ati ọba Juda, ati ọba Edomu: nigbati nwọn rìn àrinyika ijọ meje, omi kò si si nibẹ fun awọn ogun, ati fun ẹranko ti ntọ̀ wọn lẹhin.
10Ọba Israeli si wipe, O ṣe! ti Oluwa fi pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ!
11Jehoṣafati si wipe, Kò ha si woli Oluwa kan nihin, ti awa iba ti ọdọ rẹ̀ bère lọwọ Oluwa? Ọkan ninu awọn iranṣẹ ọba Israeli dahùn wipe, Eliṣa, ọmọ Ṣafati ti ntú omi si ọwọ Elijah mbẹ nihinyi.
12Jehoṣafati si wipe, Ọ̀rọ Oluwa mbẹ pẹlu rẹ̀. Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati ati ọba Edomu sọ̀kalẹ tọ̀ ọ lọ.
13Eliṣa si wi fun ọba Israeli pe, Kini o ṣe mi ṣe ọ? Ba ara rẹ lọ sọdọ awọn woli baba rẹ, ati awọn woli iya rẹ. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃kọ: nitori ti Oluwa ti pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ.
14Eliṣa si wipe, Bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, iba má ṣepe mo bu ọwọ Jehoṣafati ọba Juda, nitõtọ emi kì ba ti bẹ̀ ọ wò, bẹ̃ni emi kì ba ti ri ọ.
15Ṣugbọn ẹ mu akọrin kan fun mi wá nisisiyi. O si ṣe, nigbati akọrin na nkọrin, ọwọ Oluwa si bà le e.
16On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wà iho pupọ li afonifojì yi.
17Nitori bayi li Oluwa wi, pe, Ẹnyin kì o ri afẹfẹ, bẹ̃ni ẹnyin kì o ri òjo; ṣugbọn afonifojì na yio kún fun omi, ki ẹnyin ki o le mu, ati ẹnyin, ati awọn ẹran-ọ̀sin nyin, ati ẹran nyin.
18Ohun kikini si li eyi loju Oluwa: on o fi awọn ara Moabu le nyin lọwọ pẹlu.
19Ẹnyin o si kọlù gbogbo ilu olodi, ati gbogbo ãyò ilu, ẹnyin o si ké gbogbo igi rere lulẹ, ẹnyin o si dí gbogbo kanga omi, ẹnyin o si fi okuta bà gbogbo oko rere jẹ.
20O si ṣe li owurọ, bi a ti nta ọrẹ-ẹbọ onjẹ, si kiyesi i, omi ti ọ̀na Edomu wá, ilẹ na si kún fun omi.
21Nigbati gbogbo ara Moabu gbọ́ pe, awọn ọba gòke wá lati ba wọn jà, nwọn kó gbogbo awọn ti o le hamọra ogun jọ, ati awọn ti o dagba jù wọn lọ, nwọn si duro li eti ilẹ wọn.
22Nwọn si dide li owurọ̀, õrùn si ràn si oju omi na, awọn ara Moabu si ri omi na li apakeji, o pọn bi ẹ̀jẹ:
23Nwọn si wipe, Ẹ̀jẹ li eyi: awọn ọba na run: nwọn si ti pa ara wọn; njẹ nisisiyi, Moabu, dide si ikogun.
24Nigbati nwọn si de ibùdo Israeli, awọn ọmọ Israeli dide, nwọn si kọlù awọn ara Moabu, nwọn si sa kuro niwaju wọn: nwọn si wọ inu rẹ̀, nwọn si pa Moabu run.
25Nwọn si wó gbogbo ilu, olukulùku si jù okuta tirẹ̀ si gbogbo oko rere, nwọn si kún wọn; nwọn si dí gbogbo kanga omi, nwọn si bẹ́ gbogbo igi rere: ni Kirharaseti ni nwọn fi kiki awọn okuta rẹ̀ silẹ ṣugbọn awọn oni-kànakana yi i ka, nwọn si kọlù u.
26Nigbati ọba Moabu ri i pe ogun na le jù fun on, o mu ẹ̃dẹgbẹrin ọkunrin ti o fà idà yọ pẹlu rẹ̀, lati là ogun ja si ọdọ ọba Edomu: ṣugbọn nwọn kò le ṣe e.
27Nigbana li o mu akọbi ọmọ rẹ̀ ti iba jọba ni ipò rẹ̀, o si fi i rubọ sisun li ori odi. Ibinu nla si wà si Israeli: nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, nwọn si pada si ilẹ wọn.
Currently Selected:
II. A. Ọba 3: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.