II. A. Ọba 24
24
1LI ọjọ rẹ̀ ni Nebukadnessari ọba Babeli gòke wá, Jehoiakimu si di iranṣẹ rẹ̀ li ọdun mẹta: nigbana li o pada o si ṣọ̀tẹ si i.
2Oluwa si rán ẹgbẹ́ ogun awọn ara Kaldea si i, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Siria, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Moabu, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ọmọ Ammoni, o si rán wọn si Juda lati pa a run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ nipa awọn iranṣẹ rẹ̀ awọn woli.
3Nitõtọ lati ẹnu Oluwa li eyi ti wá sori Juda, lati mu wọn kuro niwaju rẹ̀, nitori ẹ̀ṣẹ Manasse, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe;
4Ati nitori ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ ti o ta silẹ pẹlu: nitoriti o fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kún Jerusalemu; ti Oluwa kò fẹ darijì.
5Ati iyokù iṣe Jehoiakimu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
6Bẹ̃ni Jehoiakimu sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: Jehoiakini ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
7Ọba Egipti kò si tun jade kuro ni ilẹ rẹ̀ mọ; nitori ọba Babeli ti gbà gbogbo eyiti iṣe ti ọba Egipti lati odò Egipti wá titi de odò Euferate.
Jehoiakini, Ọba Juda
(II. Kro 36:9-10)
8Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Nehuṣta, ọmọbinrin Elnatani ti Jerusalemu.
9On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ ti ṣe.
10Li akokò na, awọn iranṣẹ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá si Jerusalemu, a si dotì ilu na.
11Nebukadnessari ọba Babeli si de si ilu na, nigbati awọn iranṣẹ rẹ̀ si dotì i.
12Jehoiakini ọba Juda si jade tọ̀ ọba Babeli lọ, on, ati iya rẹ̀, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn iwẹfa rẹ̀: ọba Babeli si mu u li ọdun kẹjọ ijọba rẹ̀.
13O si kó gbogbo iṣura ile Oluwa lọ kuro nibẹ, ati iṣura ile ọba, o si ké gbogbo ohun-èlo wura wẹwẹ ti Solomoni ọba Israeli ti ṣe ni tempili Oluwa, bi Oluwa ti sọ.
14O si kó gbogbo Jerusalemu lọ, ati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo awọn alagbara akọni enia, ani ẹgbãrun igbèkun, ati gbogbo awọn oniṣọnà ati awọn alagbẹ̀dẹ: kò kù ẹnikan, bikòṣe iru awọn ti o jẹ talakà ninu awọn enia ilẹ na.
15O si mu Jehoiakini lọ si Babeli, ati iya ọba, ati awọn obinrin ọba, ati awọn iwẹ̀fa rẹ̀, ati awọn alagbara ilẹ na, awọn wọnyi li o kó ni igbèkun lati Jerusalemu lọ si Babeli.
16Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọla, ẹ̃dẹgbãrin, ati awọn oniṣọnà ati awọn alagbẹdẹ ẹgbẹrun, gbogbo awọn ti o li agbara ti o si yẹ fun ogun, ani awọn li ọba Babeli kó ni igbèkun lọ si Babeli.
17Ọba Babeli si fi Mattaniah arakunrin baba rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Sedekiah.
Sedekaya, Ọba Juda
(II. Kro 36:11-12; Jer 52:1-3a)
18Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah ti Libna.
19O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiakimu ti ṣe.
20Nitori nipa ibinu Oluwa li o ṣẹ si Jerusalemu ati Juda, titi o fi ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀; Sedekiah si ṣọ̀tẹ si ọba Babeli.
Currently Selected:
II. A. Ọba 24: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.