II. A. Ọba 21
21
Manase, Ọba Juda
(II. Kro 33:1-20)
1ẸNI ọdun mejila ni Manasse nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun marundilọgọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hefsiba.
2O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, bi iṣe-irira ti awọn keferi, ti Oluwa tì jade niwaju awọn ọmọ Israeli.
3Nitoriti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀ ti parun; o si tẹ́ pẹpẹ fun Baali o si ṣe ere-oriṣa, bi Ahabu, ọba Israeli ti ṣe, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn.
4O si tẹ́ pẹpẹ ni ile Oluwa, eyiti Oluwa ti sọ pe, Ni Jerusalemu li emi o fi orukọ mi si.
5On si tẹ́ pẹpẹ fun gbogbo ogun ọrun li agbalá mejeji ile Oluwa.
6On si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná, a si mã ṣe akiyesi afọṣẹ, a si mã ṣe alupàyida, a si mã bá awọn okú ati awọn oṣó lò: o hùwa buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu.
7O si gbé ere oriṣa fifin kalẹ ti o ti ṣe ni ile na ti Oluwa sọ fun Dafidi ati Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, Ni ile yi, ati ni Jerusalemu, ti mo ti yàn ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai:
8Bẹ̃ni emi kì yio si jẹ ki ẹsẹ̀ Israeli ki o yẹ̀ kuro mọ ni ilẹ ti mo fi fun awọn baba wọn; kiki bi nwọn o ba ṣe akiyesi lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo pa li aṣẹ fun wọn, ati gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi pa li aṣẹ fun wọn.
9Ṣugbọn nwọn kò feti silẹ: Manasse si tàn wọn lati ṣe buburu jù eyiti awọn orilẹ-ède ti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli ti ṣe.
10Oluwa si wi nipa awọn woli iranṣẹ rẹ̀ pe,
11Nitoriti Manasse ọba Juda ti ṣe ohun-irira wọnyi, ti o si ti ṣe buburu jù gbogbo eyiti awọn ọmọ Amori ti ṣe, ti o ti wà ṣãju rẹ̀, ti o si mu ki Juda pẹlu ki o fi awọn ere rẹ̀ dẹṣẹ:
12Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Kiyesi i, emi nmu iru ibi bayi wá sori Jerusalemu ati Juda, ti ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ, eti rẹ̀ mejeji yio ho.
13Emi o si nà okùn Samaria lori Jerusalemu, ati òjé-idiwọ̀n ile Ahabu: emi o si nù Jerusalemu bi enia ti nnù awokoto, o nnù u, o si ndori rẹ̀ kodò.
14Emi o si kọ̀ iyokù awọn ini mi silẹ, emi o si fi wọn le awọn ọ̀ta wọn lọwọ; nwọn o si di ikogun ati ijẹ fun gbogbo awọn ọ̀ta wọn.
15Nitori nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju mi, ti nwọn si ti mu mi binu, lati ọjọ ti awọn baba wọn ti jade kuro ni Egipti, ani titi di oni yi.
16Pẹlupẹlu Manasse ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ pupọjù, titi o fi kún Jerusalemu lati ikangun ikini de ekeji; lẹhin ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o mu Juda ṣẹ̀, ni ṣiṣe buburu li oju Oluwa.
17Ati iyokù iṣe Manasse, ati gbogbo eyiti o ṣe, ati ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ṣẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
18Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ninu ọgba-ile rẹ̀, ninu ọgba Ussa: Amoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Amoni Ọba Juda
(II. Kro 33:21-25)
19Ẹni ọdun mejilelogun ni Amoni nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun meji ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Mesullemeti, ọmọbinrin Harusi ti Jotba.
20On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, bi baba rẹ̀ Manasse ti ṣe.
21O si rìn li ọ̀na gbogbo ti baba rẹ̀ rìn, o si sìn awọn ere ti baba rẹ̀ sìn, o si bọ wọn:
22On si kọ̀ OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ, kò si rìn li ọ̀na Oluwa.
23Awọn iranṣẹ Amoni si dìtẹ si i, nwọn si pa ọba ni ile rẹ̀.
24Awọn enia ilẹ na si pa gbogbo awọn ti o dìtẹ si Amoni ọba: awọn enia ilẹ na si fi Josiah ọmọ rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀.
25Ati iyokù iṣe Amoni ti o ti ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
26A si sìn i ni isà okú rẹ̀ ninu ọgba Ussa: Josiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Currently Selected:
II. A. Ọba 21: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.