YouVersion Logo
Search Icon

II. A. Ọba 14

14
Amasaya Ọba Juda
(II. Kro 25:1-24)
1LI ọdun keji Joaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israeli ni Amasiah ọmọ Joaṣi jọba lori Juda.
2Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n li on iṣe nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkandilọgbọ̀n ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a si ma jẹ Jehoadani ti Jerusalemu.
3On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe bi Dafidi baba rẹ̀: o ṣe gẹgẹ bi ohun gbogbo ti Joaṣi baba rẹ̀ ti ṣe.
4Kiki a kò mu ibi giga wọnni kuro; sibẹ awọn enia nṣe irubọ, nwọn si nsun turari ni ibi giga wọnni.
5O si ṣe bi ijọba na ti fi idi mulẹ lọwọ rẹ̀ ni o pa awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o ti pa ọba baba rẹ̀.
6Ṣugbọn awọn ọmọ awọn apania na ni kò pa: gẹgẹ bi eyiti a ti kọ ninu iwe ofin Mose ninu eyiti Oluwa paṣẹ wipe, A kò gbọdọ pa baba fun ọmọ, bẹ̃ni a kò gbọdọ pa ọmọ fun baba; ṣugbọn olukuluku li a o pa fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
7On pa ẹgbãrun ninu awọn ara Edomu ni afonifojì iyọ, o si fi ogun kó Sela, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jokteeli titi di oni yi.
8Nigbana ni Amasiah rán ikọ̀ si Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israeli wipe, Wá, jẹ ki a wò ara wa li oju.
9Jehoaṣi ọba Israeli si ranṣẹ si Amasiah ọba Juda, pe, Igi ẹgún ti mbẹ ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti mbẹ ni Lebanoni pe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ ọkunrin mi li aya: ẹranko igbẹ́ kan ti mbẹ ni Lebanoni kọja lọ, o si tẹ̀ igi ẹ̀gun na mọlẹ.
10Iwọ ti ṣẹgun Edomu nitõtọ, ọkàn rẹ si gbé ọ soke: mã ṣogo, ki o si gbe ile rẹ: nitori kini iwọ ṣe nfiràn si ifarapa rẹ, ki iwọ ki o lè ṣubu, iwọ, ati Juda pẹlu rẹ?
11Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́. Nitorina Jehoaṣi ọba Israeli gòke lọ; on ati Amasiah ọba Juda si wò ara wọn li oju ni Betṣemeṣi, ti iṣe ti Juda.
12A si le Juda niwaju Israeli; nwọn si sá olukuluku sinu agọ rẹ̀.
13Jehoaṣi ọba Israeli si mu Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi ọmọ Ahasiah ni Betṣemeṣi, o si wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu palẹ lati ẹnu bodè Efraimu titi de ẹnu bodè igun, irinwo igbọnwọ.
14O si kó gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun èlo ti a ri ninu ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, ati ògo, o si pada si Samaria.
15Ati iyokù iṣe Jehoaṣi ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, ati bi o ti ba Amasiah ọba Judah jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
16Jehoaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli; Jeroboamu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Ikú Amasaya Ọba Juda
(II. Kro 25:25-28)
17Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda wà li ọdun mẹ̃dogun lẹhin ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israeli.
18Ati iyokù iṣe Amasiah, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
19Nwọn si dì rikiṣi si i ni Jerusalemu: o si salọ si Lakiṣi; ṣugbọn nwọn ranṣẹ tọ̀ ọ ni Lakiṣi, nwọn si pa a nibẹ.
20Nwọn si gbé e wá lori ẹṣin: a si sin i ni Jerusalemu pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi.
21Gbogbo awọn enia Juda si mu Asariah ẹni ọdun mẹrindilogun, nwọn si fi i jọba ni ipò Amasiah baba rẹ̀.
22On si kọ́ Elati, o si mu u pada fun Juda, lẹhin ti ọba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀.
Jeroboamu Keji, Ọba Israẹli
23Li ọdun kẹ̃dogun Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda, Jeroboamu ọmọ Joaṣi ọba Israeli bẹ̀rẹ si ijọba ni Samaria, o si jọba li ọdun mọkanlelogoji.
24O si ṣe buburu li oju Oluwa: kò yà kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.
25O si tun mu agbègbe ilẹ Israeli pada lati atiwọ̀ Hamati titi de okun pẹ̀tẹlẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti sọ nipa ọwọ iranṣẹ rẹ̀ Jona woli, ọmọ Amittai, ti Gat-heferi.
26Nitori Oluwa ri ipọnju Israeli pe, o korò gidigidi: nitori kò si ọmọ-ọdọ, tabi omnira tabi olurànlọwọ kan fun Israeli.
27Oluwa kò si wipe on o pa orukọ Israeli rẹ́ labẹ ọrun: ṣugbọn o gbà wọn nipa ọwọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi.
28Ati iyokù iṣe Jeroboamu ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, bi o ti jagun si, ati bi o ti gbà Damasku, ati Hamati, ti iṣe ti Juda, pada fun Israeli, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
29Jeroboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ani, pẹlu awọn ọba Israeli; Sakariah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Currently Selected:

II. A. Ọba 14: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in