II. A. Ọba 11
11
Atalaya Ayaba Juda
(II. Kro 22:10—23:5)
1NIGBATI Ataliah iyá Ahasiah si ri pe ọmọ on kú, o dide, o si pa gbogbo iru-ọmọ ọba run.
2Ṣugbọn Jehoṣeba ọmọbinrin Joramu ọba, arabinrin Ahasiah, mu Joaṣi ọmọ Ahasiah, o si ji i gbé kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa; nwọn si pa a mọ́ ninu iyẹ̀wu kuro lọdọ Ataliah, on, ati alagbatọ́ rẹ̀, ti a kò si fi pa a.
3A si pa a mọ́ pẹlu rẹ̀ ni ile Oluwa li ọdun mẹfa. Ataliah si jọba lori ilẹ na.
4Li ọdun keje Jehoiada si ranṣẹ o si mu awọn olori lori ọ̀rọrún, pẹlu awọn balogun, ati awọn olùṣọ, o si mu wọn wá si ọdọ rẹ̀ sinu ile Oluwa, o si ba wọn da majẹmu, o si mu wọn bura ni ile Oluwa, o si fi ọmọ ọba hàn wọn.
5O si paṣẹ fun wọn wipe, Eyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin ti nwọle li ọjọ isimi, yio ṣe olùtọju iṣọ ile ọba;
6Idamẹta yio si wà li ẹnu ọ̀na Suri; idamẹta yio si wà li ẹnu-ọ̀na lẹhin ẹ̀ṣọ: bẹ̃li ẹnyin o tọju iṣọ́ ile na, lati da abo bò o.
7Ati idajì gbogbo ẹnyin ti njade lọ li ọjọ isimi, ani awọn ni yio tọju iṣọ ile Oluwa yi ọba ka.
8Ẹnyin o si pa agbo yi ọba ka, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹniti o ba si wọ̀ arin ẹgbẹ́ ogun na, ki a pa a: ki ẹnyin ki o si wà pẹlu ọba bi o ti njade lọ, ati bi o ti mbọ̀wá ile.
9Awọn olori ọrọrun ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada alufa pa li aṣẹ: olukuluku wọn si mu awọn ọkunrin tirẹ̀ ti ibá wọle wá li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti iba jade lọ li ọjọ isimi, nwọn si wá si ọdọ Jehoiada alufa.
10Alufa na si fi ọ̀kọ ati asà Dafidi ọba ti o wà ni ile Oluwa fun awọn olori ọ̀rọrún.
11Awọn ẹ̀ṣọ si duro, olukulùku pẹlu ohun ijà rẹ̀ lọwọ rẹ̀ yi ọba ka, lati igun ọtún ile Oluwa, titi de igun osì ile Oluwa, nihà pẹpẹ ati ile Oluwa.
12On si mu ọmọ ọba na jade wá o si fi ade de e lori, o si fun u ni iwe-ẹ̀ri; nwọn si fi i jọba, nwọn si fi ororo yàn a; nwọn si pàtẹwọ wọn, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ.
13Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn ẹ̀ṣọ ati ti awọn enia, o tọ̀ awọn enia na wá ninu ile Oluwa.
14Nigbati o si wò, kiyesi i, ọba duro ni ibuduro na, gẹgẹ bi iṣe wọn, ati awọn balogun, ati awọn afunpè duro lọdọ ọba; gbogbo enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè: Ataliah si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si kigbe, pe, Ọtẹ̀! Ọtẹ̀!
15Ṣugbọn Jehoiada alufa paṣẹ fun awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade lati inu ile arin ẹgbẹ ogun: ẹniti o ba si tọ̀ ọ lẹhin ni ki ẹ fi idà pa. Nitoriti alufa na ti wipe, Ki a máṣe pa a ninu ile Oluwa.
16Nwọn si gbé ọwọ le e; on si gbà ọ̀na ti awọn ẹṣin ngbà wọ̀ ile ọba: nibẹ ni a si pa a.
Jehoiada Ṣe Àtúnṣe
17Jehoiada si da majẹmu lãrin Oluwa ati ọba ati awọn enia, pe, ki nwọn ki o mã ṣe enia Oluwa; ati lãrin ọba pẹlu awọn enia.
18Gbogbo enia ilẹ na si lọ sinu ile Baali, nwọn si wo o lulẹ: awọn pẹpẹ rẹ̀ ati awọn ere rẹ̀ ni nwọn fọ́ tútu patapata, nwọn si pa Mattani alufa Baali niwaju pẹpẹ na. Alufa na si yàn awọn olori si ile Oluwa.
19On si mu awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, ati awọn ẹ̀ṣọ, ati gbogbo enia ilẹ na; nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá, nwọn si gbà oju ẹnu-ọ̀na ẹ̀ṣọ wọ̀ ile ọba. O si joko lori ìtẹ awọn ọba.
20Gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀, ilu na si tòro; nwọn si fi idà pa Ataliah li eti ile ọba.
21Ẹni ọdun meje ni Jehoaṣi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba.
Currently Selected:
II. A. Ọba 11: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.