II. Kro 26
26
Usiah, Ọba Juda
(II. A. Ọba 14:21-22; 15:1-7)
1NIGBANA ni gbogbo enia Juda mu Ussiah ti iṣe ẹni ọdun mẹrindilogun, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀, Amasiah.
2On kọ́ Elotu, o si mu u pada fun Juda; lẹhin ti ọba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀.
3Ẹni ọdun mẹrindilogun ni Ussiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mejilelãdọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jekoliah ti Jerusalemu.
4O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀, Amasiah, ti ṣe.
5O si wá Ọlọrun li ọjọ Sekariah, ẹniti o li oye ninu iran Ọlọrun: niwọn ọjọ ti o wá Oluwa, Ọlọrun si mu u ṣe rere.
6O si jade lọ, o si ba awọn ara Filistia jagun, o si wó odi Gati ati odi Jabne ati odi Aṣdodu, o si kọ́ ilu wọnni ni Aṣdodu, ati lãrin awọn ara Filistia.
7Ọlọrun si ràn a lọwọ si awọn ara Filistia, ati si awọn ara Arabia, ti ngbe ni Gur-Baali, ati awọn ara Mehuni.
8Awọn ara Ammoni ta Ussiah li ọrẹ: orukọ rẹ̀ si tàn lọ kakiri titi de atiwọ Egipti; nitoriti o mu ara rẹ̀ le gidigidi.
9Ussiah si kọ́ ile iṣọ ni Jerusalemu, nibi ẹnu-bode Igun, ati nibi ẹnu-bode Afonifoji, ati nibi iṣẹpo-odi, o si mu wọn le.
10O kọ́ ile iṣọ li aginju pẹlu, o si wà kanga pupọ: nitoriti o li ẹran-ọsin pipọ, ati ni ilẹ isalẹ, ati ni pẹ̀tẹlẹ: o ni àgbẹ ati awọn olutọju àjara lori òke nla, ati lori Karmeli: nitoriti o fẹran àgbẹ-ṣiṣe.
11Ussiah si li ẹgbẹ́-ogun awọn enia ti njagun, ti ima lọ ijagun li ẹgbẹgbẹ gẹgẹ bi iye kikà wọn, nipa ọwọ Jegieli, akọwe, ati Maaseiah, olori labẹ ọwọ Hananiah, ọkan ninu awọn olori ogun ọba.
12Gbogbo iye olori awọn baba, alagbara akọni ogun jẹ ẹgbẹtala.
13Ati li ọwọ wọn li agbara ogun kan wà, ọkẹ mẹdogun enia o le ẹ̃dẹgbãrin ti o mura, ti nfi àgbara nla jagun, lati ràn ọba lọwọ si ọta.
14Ussiah si pesè fun wọn, já gbogbo ogun na, asà ati ọ̀kọ, ati akoro, ati ohun ihamọra-ọrùn, ati ọrun titi de okuta kànakàna.
15O si ṣe ohun ẹrọ-ijagun ni Jerusalemu, ihumọ ọlọgbọ́n enia, lati wà lori ile-iṣọ, ati lori igun odi, lati fi tafa, ati lati fi sọ okuta nla. Orukọ rẹ̀ si tàn lọ jìnajina, nitoriti a ṣe iranlọwọ iyanu fun u, titi o fi li agbara.
Usaya Jìyà nítorí Ìwà Ìgbéraga Rẹ̀
16Ṣugbọn nigbati o li agbara tan, ọkàn rẹ̀ gbé ga soke si iparun; nitoriti o ṣe irekọja si Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si lọ sinu tempili Oluwa, lati sun turari lori pẹpẹ turari.
17Asariah, alufa si wọle tọ̀ ọ lọ ati ọgọrin alufa Oluwa pẹlu rẹ̀, awọn alagbara,
18Nwọn si tako Ussiah ọba, nwọn si wi fun u pe, Ki iṣe tirẹ, Ussiah, lati sun turari fun Oluwa, bikòṣe ti awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ti a yà si mimọ́ lati sun turari: jade kuro ni ibi mimọ́; nitoriti iwọ ti dẹṣẹ; bẹ̃ni kì yio ṣe fun ọlá rẹ lati ọdọ Oluwa Ọlọrun.
19Nigbana ni Ussiah binu, awo-turari si mbẹ lọwọ rẹ̀ lati sun turari: ati nigbati o binu si awọn alufa, ẹ̀tẹ yọ ni iwaju rẹ̀, loju awọn alufa ni ile Oluwa lẹba pẹpẹ turari.
20Ati Asariah, olori alufa, ati gbogbo awọn alufa wò o, si kiyesi i, o dẹtẹ ni iwaju rẹ̀, nwọn si tì i jade kuro nibẹ, nitõtọ, on tikararẹ̀ yara pẹlu lati jade, nitoriti Oluwa ti lù u.
21Ussiah ọba, si di adẹ̀tẹ titi di ọjọ ikú rẹ̀, o si ngbe ile àrun, nitori adẹtẹ ni iṣe, nitoriti a ké e kuro ninu ile Oluwa: Jotamu, ọmọ rẹ̀, si wà lori ile ọba, o nṣe idajọ awọn enia ilẹ na,
22Ati iyokù iṣe Ussiah, ti iṣaju ati ti ikẹhin ni Isaiah woli, ọmọ Amosi, kọ.
23Bẹ̃ni Ussiah sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni oko ìsinkú ti iṣe ti awọn ọba; nitoriti nwọn wipe, Adẹtẹ li on: Jotamu, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
Currently Selected:
II. Kro 26: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.