II. Kro 24
24
Joaṣi, Ọba Juda
(II. A. Ọba 12:1-16)
1ẸNI ọdun meje ni Joaṣi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ogoji ọdun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Sibia ti Beer-ṣeba.
2Joaṣi si ṣe eyiti o tọ li oju Oluwa ni gbogbo ọjọ Jehoiada, alufa.
3Jehoiada si fẹ obinrin meji fun u, o si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
4O si ṣe lẹhin eyi, o wà li ọkàn Joaṣi lati tun ile Oluwa ṣe.
5O si kó awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi jọ, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ si ilu Juda wọnni, ki ẹ si gbà owo jọ lati ọwọ gbogbo Israeli, lati tun ile Ọlọrun nyin ṣe li ọdọdun, ki ẹ si mu ọ̀ran na yá kankan. Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi kò mu ọ̀ran na yá kánkan.
6Ọba si pè Jehoiada, olori, o si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ kò bère li ọwọ awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ki o mu owo ofin Mose, iranṣẹ Oluwa, lati Juda ati lati Jerusalemu wá, ati ti ijọ-enia Israeli fun agọ ẹri?
7Nitori Ataliah, obinrin buburu nì ati awọn ọmọ rẹ ti fọ ile Ọlọrun; ati pẹlu gbogbo ohun mimọ́ ile Oluwa ni nwọn fi ṣe ìsin fun Baalimu.
8Ọba si paṣẹ, nwọn si kàn apoti kan, nwọn si fi si ita li ẹnu-ọ̀na ile Oluwa.
9Nwọn si kede ni Juda ati Jerusalemu, lati mu owo ofin fun Oluwa wá, ti Mose iranṣẹ Ọlọrun, fi le Israeli lori li aginju.
10Gbogbo awọn ijoye ati gbogbo awọn enia si yọ̀, nwọn si mu wá, nwọn fi sinu apoti na, titi o fi kún.
11O si ṣe, nigbati akokò de lati mu apoti na wá sọdọ olutọju iṣẹ ọba nipa ọwọ awọn ọmọ Lefi, nigbati nwọn si ri pe, owo pọ̀, akọwe ọba ati olori ninu awọn alufa a wá, nwọn a si dà apoti na, nwọn a mu u, nwọn a si tun mu u pada lọ si ipò rẹ̀. Bayi ni nwọn nṣe li ojojumọ, nwọn si kó owo jọ li ọ̀pọlọpọ.
12Ati ọba ati Jehoiada fi i fun iru awọn ti nṣiṣẹ ile Oluwa, nwọn si fi gbà àgbaṣe awọn oniṣọ̀nà okuta, ati awọn gbẹnàgbẹna, lati tun ile Oluwa ṣe, ati pẹlu awọn alagbẹdẹ irin, ati idẹ, lati tun ile Oluwa ṣe.
13Bẹ̃li awọn ti o nṣiṣẹ ṣiṣẹ na, iṣẹ na si lọ siwaju ati siwaju li ọwọ wọn, nwọn si tun mu ile Ọlọrun duro si ipò rẹ̀, nwọn si mu u le.
14Nigbati nwọn si pari rẹ̀ tan, nwọn mu owo iyokù wá si iwaju ọba ati Jehoiada, a si fi i ṣe ohun-elo fun ile Oluwa, ani ohun-elo fun ìsin ati fun ẹbọ, pẹlu ọpọ́n, ani ohun-elo wura ati fadakà. Nwọn si ru ẹbọ sisun ni ile Oluwa nigba-gbogbo ni gbogbo ọjọ Jehoiada.
Wọ́n Yí Ètò ìjọba Jehoiada pada
15Ṣugbọn Jehoiada di arugbo, o si kún fun ọjọ, o si kú, ẹni ãdoje ọdun ni nigbati o kú.
16Nwọn si sìn i ni ilu Dafidi pẹlu awọn ọba, nitoriti o ṣe rere ni Israeli, ati si Ọlọrun, ati si ile rẹ̀.
17Lẹhin ikú Jehoiada awọn ijoye Juda de, nwọn si tẹriba fun ọba. Nigbana li ọba si gbọ́ ti wọn.
18Nwọn si kọ̀ ile Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, nwọn si nsìn òriṣa ati ere: ibinu si wá sori Juda ati Jerusalemu nitori ẹ̀ṣẹ wọn yi.
19Sibẹ o rán awọn woli si wọn, lati mu wọn pada tọ̀ Oluwa wá; nwọn si jẹri gbè wọn; ṣugbọn nwọn kò fi eti si i.
20Ẹmi Ọlọrun si bà le Sakariah, ọmọ Jehoiada alufa, ti o duro ni ibi giga jù awọn enia lọ, o si wi fun wọn pe, Bayi li Ọlọrun wi pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ru ofin Oluwa, ẹnyin kì yio ri ire? nitoriti ẹnyin ti kọ̀ Oluwa silẹ, on pẹlu si ti kọ̀ nyin.
21Nwọn si di rikiṣi si i, nwọn si sọ ọ li okuta nipa aṣẹ ọba li agbala ile Oluwa.
22Bẹ̃ni Joaṣi, ọba, kò ranti õre ti Jehoiada, baba rẹ̀, ti ṣe fun u, o si pa ọmọ rẹ̀. Nigbati o si nkú lọ, o wipe, Ki Oluwa ki o wò o, ki o si bère rẹ̀.
Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Joaṣi
23O si ṣe li opin ọdun ni ogun Siria gòke tọ̀ ọ wá: nwọn si de Juda ati Jerusalemu, nwọn si pa gbogbo awọn ijoye enia run kuro ninu awọn enia na, nwọn si rán gbogbo ikógun wọn sọdọ ọba Damasku.
24Nitori ogun awọn ara Siria dé pẹlu ẹgbẹ diẹ, Oluwa si fi ogun ti o pọ̀ gidigidi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ. Bẹ̃ni nwọn si ṣe idajọ Joaṣi.
25Nigbati nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, (nwọn sa ti fi i silẹ ninu àrun nla) awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nitori ẹ̀jẹ awọn ọmọ Jehoiada alufa, nwọn si pa a lori akete rẹ̀, o si kú: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi, ṣugbọn nwọn kò sìn i ni iboji awọn ọba.
26Wọnyi li awọn ti o di rikiṣi si i, Sabadi, ọmọ Simeati, obinrin ara Ammoni, ati Jehosabadi, ọmọ Ṣimriti, obinrin ara Moabu.
27Njẹ niti awọn ọmọ rẹ̀, ati titobi owo-ọba, ti a fi le e lori, ati atunṣe ile Ọlọrun, kiyesi i, a kọ wọn sinu itan iwe awọn ọba. Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Currently Selected:
II. Kro 24: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.