II. Kro 10
10
Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Àríwá Dìtẹ̀
(I. A. Ọba 12:1-20)
1REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu: nitori gbogbo Israeli wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba.
2O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọmọ Nebati gbọ́, on si wà ni Egipti nibiti o ti salọ kuro niwaju Solomoni ọba, ni Jeroboamu pada ti Egipti wá.
3Nwọn si ranṣẹ pè e. Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo Israeli wá, nwọn si ba Rehoboamu sọ̀rọ, wipe,
4Baba rẹ mu ki àjaga wa ki o wuwo: njẹ nisisiyi iwọ ṣẹkù kuro ninu ìsin baba rẹ ti o nira, ati àjaga wuwo rẹ̀ ti o fi bọ̀ wa lọrùn, awa o si ma sìn ọ.
5On si wi fun wọn pe, Ẹ tun pada tọ̀ mi wá lẹhin ijọ mẹta. Awọn enia na si lọ.
6Rehoboamu ọba si ba awọn àgbagba ti o ti nduro niwaju Solomoni baba rẹ̀; nigbati o wà lãye dá imọran, wipe, imọran kili ẹnyin dá lati da awọn enia yi lohùn?
7Nwọn si ba a sọ̀rọ pe, bi iwọ ba ṣe ire fun enia yi, ti iwọ ba ṣe ohun ti o wù wọn, ti o ba si sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ nigbagbogbo.
8Ṣugbọn o kọ̀ imọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti o dàgba pẹlu rẹ̀ damọran, ti o duro niwaju rẹ̀.
9On si wi fun wọn pe, Imọran kili ẹnyin dá, ki awa ki o le da awọn enia yi lohùn, ti o ba mi sọ̀rọ, wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi bọ̀ wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ?
10Awọn ipẹrẹ ti a tọ́ pẹlu rẹ̀ si sọ fun u wipe, Bayi ni iwọ o da awọn enia na li ohùn ti o sọ fun ọ, wipe, Baba rẹ mu àjaga wa di wuwo, ṣugbọn iwọ ṣe e ki o fẹrẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o wi fun wọn, Ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ.
11Njẹ nisisiyi baba mi ti fi àjaga wuwo bọ̀ nyin lọrùn, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin.
12Jeroboamu ati gbogbo awọn enia si tọ̀ Rehoboamu wá ni ijọ kẹta gẹgẹ bi ọba ti dá, wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta.
13Nigbana ni ọba da wọn li ohùn akọ; Rehoboamu ọba si kọ̀ imọran awọn àgbagba silẹ.
14O si da wọn li ohùn gẹgẹ bi imọran awọn ipẹrẹ, wipe, Baba mi mu àjaga nyin ki o wuwo, ṣugbọn emi o fi kún u; baba mi ti fi paṣan nà nyin, ṣugbọn emi o fi akẽke nà nyin.
15Bẹ̃ni ọba kò si fetisi ti awọn enia na: nitori ṣiṣẹ ọ̀ran na lati ọwọ Ọlọrun wá ni, ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti o sọ nipasẹ Ahijah, ara Ṣilo fun Jeroboamu, ọmọ Nebati.
16Nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kọ̀ lati fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba lohùn, wipe, Ipin kili a ni ninu Dafidi? awa kò si ni ini kan ninu ọmọ Jesse: Israeli, olukuluku sinu agọ rẹ̀: nisisiyi Dafidi, mã bojuto ile rẹ. Bẹ̃ni gbogbo Israeli lọ sinu agọ wọn,
17Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli ti ngbe ilu Juda wọnni, Rehoboamu jọba lori wọn.
18Nigbana ni Rehoboamu ọba ran Hadoramu ti iṣe olori iṣẹ-irú; awọn ọmọ Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Ṣugbọn Rehoboamu ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀ lati salọ si Jerusalemu.
19Bẹ̃ni Israeli si ya kuro lọdọ ile Dafidi titi o fi di oni yi.
Currently Selected:
II. Kro 10: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.