I. Tes 5:15-24
I. Tes 5:15-24 YBCV
Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia. Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo. Ẹ mã gbadura li aisimi. Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin. Ẹ máṣe pa iná Ẹmí. Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ. Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin. Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi. Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi. Olododo li ẹniti o pè nyin, ti yio si ṣe e.