I. Sam 8
8
Àwọn Ọmọ Israẹli Bèèrè fún Ọba
1O si ṣe, nigbati Samueli di arugbo, on si fi awọn ọmọ rẹ̀ jẹ onidajọ fun Israeli.
2Orukọ akọbi rẹ̀ njẹ Joeli; orukọ ekeji rẹ̀ si njẹ Abia: nwọn si nṣe onidajọ ni Beerṣeba.
3Awọn ọmọ rẹ̀ kò si rin ni ìwa rẹ̀, nwọn si ntọ̀ erekere lẹhin, nwọn ngbà abẹtẹlẹ, nwọn si nyi idajọ po.
4Gbogbo awọn agbà Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn si tọ Samueli lọ si Rama,
5Nwọn si wi fun u pe, Kiye si i, iwọ di arugbo, awọn ọmọ rẹ kò si rin ni ìwa rẹ: njẹ fi ẹnikan jẹ ọba fun wa, ki o le ma ṣe idajọ wa, bi ti gbogbo orilẹ-ède.
6Ṣugbọn ohun na buru loju Samueli, nitori ti nwọn wipe, Fi ọba fun wa ki o le ma ṣe idajọ wa, Samueli si gbadura si Oluwa.
7Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn awọn enia na ni gbogbo eyi ti nwọn sọ fun ọ: nitoripe iwọ ki nwọn kọ̀, ṣugbọn emi ni nwọn kọ̀ lati jẹ ọba lori wọn.
8Gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti nwọn ṣe lati ọjọ ti mo ti mu nwọn jade ti Egipti wá, titi o si fi di oni, bi nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn si nsin awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni nwọn ṣe si ọ pẹlu.
9Njẹ nitorina gbọ́ ohùn wọn: ṣugbọn lẹhin igbati iwọ ba ti jẹri si wọn tan, nigbana ni ki iwọ ki o si fi iwà ọba ti yio jẹ lori wọn hàn wọn.
10Samueli si sọ gbogbo ọ̀rọ Oluwa fun awọn enia na ti o mbere ọba lọwọ́ rẹ̀.
11O si wipe, Eyi ni yio ṣe ìwa ọba na ti yio jẹ lori nyin: yio mu awọn ọmọkunrin nyin, yio si yàn wọn fun ara rẹ̀ fun awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati fun ẹlẹṣin rẹ̀, nwọn o si ma sare niwaju kẹkẹ́ rẹ̀.
12Yio si yan olori ẹgbẹgbẹrun fun ara rẹ̀, ati olori aradọta; yio si yàn wọn lati ma ro oko rẹ̀, ati lati ma kore fun u, ati lati ma ṣe ohun elo-ogun rẹ̀, ati ohun elo-kẹkẹ́ rẹ̀.
13On o si mu ninu ọmọbinrin nyin ṣe olùṣe ikunra õrun didùn, ati ẹniti yio ma ṣe alasè, ati ẹniti yio ma ṣe akara.
14Yio mu ninu oko nyin, ati ninu ọgba ajara nyin, ati ninu igi olifi nyin wọnni, ani eyiti o dara julọ ninu wọn, yio si fi fun awọn ẹrú rẹ̀.
15On o si mu idamẹwa ninu irugbin nyin, ati ọgbà ajara nyin, yio si fi fun awọn ẹmẹ̀wa rẹ̀ ati fun awọn ẹrú rẹ̀.
16Yio mu awọn ẹrúkunrin nyin, ati ẹrubirin nyin, ati awọn aṣàyàn ọdọmọkunrin nyin, ati awọn kẹtẹkẹtẹ nyin, yio si fi nwọn si iṣẹ ara rẹ̀.
17On o si mu idamẹwa ninu awọn agutan nyin: ẹnyin o si jasi ẹrú rẹ̀.
18Ẹnyin o kigbe fun igbala li ọjọ na nitori ọba nyin ti ẹnyin o yàn: Oluwa kì yio gbọ́ ti nyin li ọjọ na.
19Ṣugbọn awọn enia na kọ̀ lati gbọ́ ohùn Samueli; nwọn si wipe, bẹ̃kọ; awa o ni ọba lori wa;
20Ani awa o si dabi gbogbo orilẹ-ède; ki ọba wa ki o si ma ṣe idajọ wa, ki o si ma ṣaju wa, ki o si ma ja ogun wa.
21Samueli si gbọ́ gbogbo ọ̀rọ awọn enia na, o si sọ wọn li eti Oluwa.
22Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn wọn ki o si fi ọba jẹ fun wọn. Samueli sọ fun awọn ọmọ Israeli pe. Lọ, olukuluku si ilu rẹ̀.
Currently Selected:
I. Sam 8: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.