I. Pet Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ẹni tí ó kọ Ìwé Kinni láti Ọ̀dọ̀ Peteru kọ ọ́ sí àwọn onigbagbọ tí a pè ní “àṣàyàn eniyan Ọlọrun” ninu ìwé yìí tí wọ́n fọ́n káàkiri apá kan ilẹ̀ Esia tí a lè pè ní Esia kékeré ní èdè Yoruba (Asia Minor). Ìdí pataki tí a fi kọ ìwé náà ni láti fún àwọn olùkà rẹ̀ ní ìwúrí ní àkókò tí wọ́n wà ninu inúnibíni ati ìjìyà nítorí igbagbọ wọn. Ọ̀nà tí ẹni tí ó kọ ìwé yìí gbà fún àwọn olùkà rẹ̀ ní ìwúrí ni pé ó rán wọn létí Ìròyìn Ayọ̀ nípa Jesu Kristi, ẹni tí ikú rẹ̀, ajinde rẹ̀, ati ìpadàbọ̀ rẹ̀ fún wọn ní ìrètí. Ó ní ti Jesu yìí ni kí wọ́n wò kí wọ́n fi gba ìjìyà wọn, kí wọ́n fara dà á, pẹlu ìdánilójú pé ìdánwò ní ó jẹ́, láti mọ̀ bí igbagbọ wọn bá jẹ́ ojúlówó, ati pé wọn óo gba èrè rẹ̀ ní “Ọjọ́ tí Jesu bá fara hàn.”
Bí ẹni tí ó kọ ìwé yìí ti ń dá àwọn eniyan lọ́kàn le ní àkókò ìyọnu, ó tún ń rọ̀ wọ́n láti máa gbé ìgbé-ayé irú àwọn eniyan tí wọ́n jẹ́ ti Kristi.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-2
Ìránni létí ìgbàlà Ọlọrun 1:3-12
Ìgbani-níyànjú fún ìgbé-ayé mímọ́ 1:13—2:10
Iṣẹ́ onigbagbọ ní àkókò ìjìyà 2:11—4:19
Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ati iṣẹ́ onigbagbọ 5:1-11
Ọ̀rọ̀ ìparí 5:12-14
Currently Selected:
I. Pet Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.