I. Pet 4:7-13
I. Pet 4:7-13 YBCV
Ṣugbọn opin ohun gbogbo kù si dẹ̀dẹ: nitorina ki ẹnyin ki o wà li airekọja, ki ẹ si mã ṣọra ninu adura. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbóna larin ara nyin: nitori ifẹ ni mbò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ. Ẹ mã ṣe ara nyin li alejò laisi ikùn sinu. Bi olukuluku ti ri ẹ̀bun gbà, bẹ̃ni ki ẹ mã ṣe ipinfunni rẹ̀ larin ara nyin, bi iriju rere ti onirũru ore-ọfẹ Ọlọrun. Bi ẹnikẹni ba nsọ̀rọ, ki o mã sọ bi ọ̀rọ Ọlọrun; bi ẹnikẹni ba nṣe iṣẹ iranṣẹ, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fifun u: ki a le mã yìn Ọlọrun logo li ohun gbogbo nipa Jesu Kristi, ẹniti ogo ati ìjọba wà fun lai ati lailai. Amin. Olufẹ, ẹ máṣe ka idanwò iná ti mbẹ larin nyin eyiti o de si nyin lati dan nyin wò bi ẹnipe ohun àjeji li o de bá nyin: Ṣugbọn niwọnbi ẹnyin ti jẹ alabapin ìya Kristi, ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o le yọ̀ ayọ̀ pipọ nigbati a ba fi ogo rẹ̀ hàn.