YouVersion Logo
Search Icon

I. A. Ọba 9

9
Ọlọrun tún fara han Solomoni
(II. Kro 7:11-22)
1O si ṣe, bi Solomoni ti pari kikọ́ ile Oluwa, ati ile ọba, ati gbogbo ifẹ Solomoni ti o wù u lati ṣe,
2Oluwa fi ara hàn Solomoni li ẹrinkeji, gẹgẹ bi o ti fi ara hàn a ni Gibeoni.
3Oluwa si wi fun u pe, Mo ti gbọ́ adura rẹ ati ẹ̀bẹ rẹ, ti iwọ ti bẹ̀ niwaju mi, mo ti ya ile yi si mimọ́, ti iwọ ti kọ́, lati fi orukọ mi sibẹ titi lai; ati oju mi ati ọkàn mi yio wà nibẹ titi lai.
4Bi iwọ o ba rìn niwaju mi: bi Dafidi baba rẹ ti rìn, ni otitọ ọkàn, ati ni iduroṣinṣin, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, ti iwọ o si pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́:
5Nigbana li emi o fi idi itẹ́ ijọba rẹ mulẹ lori Israeli titi lai, bi mo ti ṣe ileri fun Dafidi baba rẹ, wipe, Iwọ kì yio fẹ ọkunrin kan kù lori itẹ́ Israeli.
6Ṣugbọn bi ẹnyin o ba yipada lati mã tọ̀ mi lẹhin, ẹnyin, tabi awọn ọmọ nyin, bi ẹnyin kò si pa ofin mi mọ́, ati aṣẹ mi ti mo ti fi si iwaju nyin, ṣugbọn bi ẹ ba lọ ti ẹ si sìn awọn ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn:
7Nigbana ni emi o ké Israeli kuro ni ilẹ ti emi fi fun wọn; ati ile yi, ti mo ti yà si mimọ́ fun orukọ mi li emi o gbe sọnù kuro niwaju mi; Israeli yio si di owe ati ifiṣẹsin lãrin gbogbo orilẹ-ède.
8Ati ile yi, ti o ga, ẹnu o si ya olukuluku ẹniti o kọja lẹba rẹ̀, yio si pòṣe: nwọn o si wipe; ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi ati si ile yi?
9Nwọn o si dahùn wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, ẹniti o mu awọn baba wọn jade ti ilẹ Egipti wá, nwọn gbá awọn ọlọrun miran mú, nwọn si bọ wọn, nwọn si sìn wọn: nitorina ni Oluwa ṣe mu gbogbo ibi yi wá sori wọn.
Solomoni ṣe Àdéhùn pẹlu Hiramu Ọba
(II. Kro 8:1-2)
10O si ṣe lẹhin ogún ọdun, nigbati Solomoni ti kọ́ ile mejeji tan, ile Oluwa, ati ile ọba.
11Hiramu, ọba Tire ti ba Solomoni wá igi kedari ati igi firi, ati wura gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀, nigbana ni Solomoni ọba fun Hiramu ni ogún ilu ni ilẹ Galili.
12Hiramu si jade lati Tire wá lati wò ilu ti Solomoni fi fun u: nwọn kò si wù u.
13On si wipe, Ilu kini wọnyi ti iwọ fi fun mi, arakunrin mi? O si pè wọn ni ilẹ Kabulu titi fi di oni yi.
14Hiramu si fi ọgọta talenti wura ranṣẹ si ọba.
Àwọn Nǹkan pataki mìíràn tí Solomoni ṣe
(II. Kro 8:3-18)
15Idi awọn asìnru ti Solomoni kojọ ni eyi; lati kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀, ati Millo, ati odi Jerusalemu, ati Hasori ati Megiddo, ati Geseri.
16Farao, ọba Egipti ti goke lọ, o si ti kó Geseri, o si ti fi iná sun u, o si ti pa awọn ara Kenaani ti ngbe ilu na, o si fi ta ọmọbinrin rẹ̀, aya Solomoni li ọrẹ.
17Solomoni si kọ́ Geseri, ati Bethoroni-isalẹ.
18Ati Baalati, ati Tadmori ni aginju, ni ilẹ na.
19Ati gbogbo ilu iṣura ti Solomoni ni, ati ilu kẹkẹ́ rẹ̀, ati ilu fun awọn ẹlẹsin rẹ̀, ati eyiti Solomoni nfẹ lati kọ́ ni Jerusalemu, ati ni Lebanoni, ati ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀.
20Gbogbo enia ti o kù ninu awọn ara Amori, ara Hitti, Perisi, Hifi ati Jebusi, ti kì iṣe ti inu awọn ọmọ Israeli.
21Awọn ọmọ wọn ti o kù lẹhin wọn ni ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli kò le parun tũtu, awọn ni Solomoni bù iṣẹ-iru fun titi di oni yi.
22Ṣugbọn ninu awọn ọmọ Israeli, Solomoni kò fi ṣe ẹrú, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ologun ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn balogun rẹ̀, ati awọn olori kẹkẹ́ rẹ̀ ati ti awọn ẹlẹsin rẹ̀.
23Awọn wọnyi ni awọn olori olutọju ti mbẹ lori iṣẹ Solomoni, ãdọta-dilẹgbẹta, ti nṣe akoso lori awọn enia ti nṣe iṣẹ na.
24Ṣugbọn ọmọbinrin Farao goke lati ilu Dafidi wá si ile rẹ̀, ti Solomoni kọ́ fun u: nigbana ni o kọ́ Millo.
25Ati nigba mẹta li ọdun ni Solomoni iru ẹbọ ọrẹ-sisun, ati ẹbọ-ọpẹ lori pẹpẹ ti o tẹ́ fun Oluwa, o si sun turari lori eyi ti mbẹ niwaju Oluwa. Bẹ̃li o pari ile na.
26Solomoni ọba si sẹ ọ̀wọ-ọkọ̀ ni Esioni-Geberi, ti mbẹ li ẹba Eloti, leti Okun-pupa ni ilẹ Edomu.
27Hiramu si rán awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn atukọ ti o ni ìmọ okun, pẹlu awọn iranṣẹ Solomoni ninu ọ̀wọ-ọkọ̀ na.
28Nwọn si de Ofiri, nwọn si mu wura lati ibẹ wá, irinwo talenti o le ogun, nwọn si mu u fun Solomoni ọba wá.

Currently Selected:

I. A. Ọba 9: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy