YouVersion Logo
Search Icon

I. A. Ọba 7

7
Ààfin Solomoni
1ṢUGBỌN Solomoni fi ọdun mẹtala kọ́ ile on tikararẹ̀, o si pari gbogbo iṣẹ ile rẹ̀.
2O kọ́ ile-igbó Lebanoni pẹlu; gigùn rẹ̀ jasi ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ adọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọnwọ, lori ọ̀wọ́ mẹrin opó igi kedari, ati idabu igi kedari lori awọn opó na.
3A si fi igi kedari tẹ́ ẹ loke lori iyara ti o joko lori ọwọ̀n marunlelogoji, mẹdogun ni ọ̀wọ́.
4Ferese si wà ni ọ̀wọ́ mẹta, oju si ko oju ni ọ̀na mẹta.
5Gbogbo ilẹkun ati opó si dọgba ni igun mẹrin; oju si ko oju ni ọ̀na mẹta.
6O si fi ọwọ̀n ṣe iloro: gigùn rẹ̀ jẹ adọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ ọgbọ̀n igbọnwọ, iloro kan si wà niwaju rẹ̀: ani ọwọ̀n miran, igi itẹsẹ ti o nipọn si mbẹ niwaju wọn.
7O si ṣe iloro itẹ nibiti yio ma ṣe idajọ, ani iloro idajọ: a si fi igi kedari tẹ ẹ lati iha kan de keji.
8Ile rẹ̀ nibiti o ngbe, ni agbala lẹhin ile titi de ọ̀dẹdẹ, si jẹ iṣẹ kanna. Solomoni si kọ́ ile fun ọmọbinrin Farao, ti o ni li aya, bi iloro yi.
9Gbogbo wọnyi jẹ okuta iyebiye gẹgẹ bi iwọn okuta gbigbẹ́, ti a fi ayùn rẹ́ ninu ati lode, ani lati ipilẹ de ibori-oke ile, bẹ̃ si ni lode si apa agbala nla.
10Ipilẹ na jẹ okuta iyebiye, ani okuta nlanla, okuta igbọnwọ mẹwa, ati okuta igbọnwọ mẹjọ.
11Ati okuta iyebiye wà loke nipa iwọ̀n okuta ti a gbẹ́, ati igi kedari.
12Ati agbàla nla yikakiri pẹlu jẹ ọ̀wọ́ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ọ̀wọ́ kan igi idabu ti kedari, ati fun agbala ile Oluwa ti inu lọhun, ati fun iloro ile na.
Iṣẹ́ Huramu
13Solomoni ọba si ranṣẹ, o si mu Hiramu lati Tire wá.
14Ọmọkunrin opó kan ni, lati inu ẹya Naftali, baba rẹ̀ si ṣe ara Tire, alagbẹdẹ idẹ: on si kún fun ọgbọ́n, ati oye, ati ìmọ lati ṣe iṣẹkiṣẹ ni idẹ. O si tọ̀ Solomoni ọba wá, o si ṣe gbogbo iṣẹ rẹ̀.
Òpó Bàbà Meji
(II. Kro 3:15-17)
15O si dà ọwọ̀n idẹ meji, igbọnwọ mejidilogun ni giga ọkọkan: okùn igbọnwọ mejila li o si yi ọkọkan wọn ka.
16O si ṣe ipari meji ti idẹ didà lati fi soke awọn ọwọ̀n na: giga ipari kan jẹ igbọnwọ marun, ati giga ipari keji jẹ igbọnwọ marun:
17Ati oniruru iṣẹ, ati ohun wiwun iṣẹ ẹ̀wọn fun awọn ipari ti mbẹ lori awọn ọwọ̀n na; meje fun ipari kan, ati meje fun ipari keji.
18O si ṣe ọ̀wọn pomegranate ani ọ̀wọ́ meji yikakiri lara iṣẹ àwọn na, lati fi bò awọn ipari ti mbẹ loke: bẹ̃li o si ṣe fun ipari keji.
19Ati ipari ti mbẹ li oke awọn ọwọ̀n ti mbẹ ni ọ̀dẹdẹ na ti iṣẹ lili, ni igbọnwọ mẹrin.
20Ati awọn ipari lori ọwọ̀n meji na wà loke: nwọn si sunmọ ibi ti o yọ lara ọwọ̀n ti o wà nibi iṣẹ àwọn: awọn pomegranate jẹ igba ni ọ̀wọ́ yikakiri, lori ipari keji.
21O si gbe awọn ọwọ̀n na ro ni iloro tempili: o si gbe ọwọ̀n ọ̀tun ró, o si pe orukọ rẹ̀ ni Jakini: o si gbe ọwọ̀n òsi ró, o si pe orukọ rẹ̀ ni Boasi.
22Lori oke awọn ọwọ̀n na ni iṣẹ lili wà; bẽni iṣẹ ti awọn ọwọ̀n si pari.
Agbada Bàbà
(II. Kro 4:2-5)
23O si ṣe agbada nla didà igbọnwọ mẹwa lati eti kan de ekeji: o ṣe birikiti, giga rẹ̀ si jẹ igbọnwọ marun: okùn ọgbọ̀n igbọnwọ li o si yi i kakiri.
24Ati nisalẹ eti rẹ̀ yikakiri kóko wà yi i ka, mẹwa ninu igbọnwọ kan, o yi agbada nla na kakiri: a dà kóko na ni ẹsẹ meji, nigbati a dà a.
25O duro lori malu mejila, mẹta nwo iha ariwa, mẹta si nwo iwọ-õrun, mẹ̃ta si nwo gusu, mẹta si nwo ila-õrun; agbada nla na si joko lori wọn, gbogbo apa ẹhin wọn si mbẹ ninu.
26O si nipọn to ibú atẹlẹwọ, a si fi itanna lili ṣiṣẹ eti rẹ̀ gẹgẹ bi eti ago, o si gbà ẹgbã iwọ̀n Bati.
Ọkọ̀ Bàbà
27O si ṣe ijoko idẹ mẹwa; igbọnwọ mẹrin ni gigùn ijoko kọkan, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ mẹta ni giga rẹ̀.
28Iṣẹ awọn ijoko na ri bayi: nwọn ni alafo ọ̀na arin, alafo ọ̀na arin na si wà lagbedemeji ipade eti.
29Ati lara alafo ọ̀na arin ti mbẹ lagbedemeji ni aworan kiniun, malu, ati awọn kerubu wà; ati lori ipade eti, ijoko kan wà loke: ati labẹ awọn kiniun, ati malu ni iṣẹ ọṣọ́ wà.
30Olukuluku ijoko li o ni ayika kẹkẹ́ idẹ mẹrin, ati ọpa kẹkẹ́ idẹ: igun mẹrẹrin rẹ̀ li o ni ifẹsẹtẹ labẹ; labẹ agbada na ni ifẹsẹtẹ didà wà, ni iha gbogbo iṣẹ ọṣọ́ na.
31Ẹnu rẹ̀ ninu ipari na ati loke jẹ igbọnwọ kan: ṣugbọn ẹnu rẹ̀ yika gẹgẹ bi iṣẹ ijoko na, si jẹ igbọnwọ kan on àbọ: ati li ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbigbẹ́ wà pẹlu alafo ọ̀na arin wọn, nwọn si dọgba ni igun mẹrẹrin, nwọn kò yika.
32Ati nisalẹ alafo ọ̀na arin, ayika-kẹkẹ́ mẹrin li o wà: a si so ọpa ayika-kẹkẹ́ na mọ ijoko na; giga ayika-kẹkẹ́ kan si jẹ igbọnwọ kan pẹlu àbọ.
33Iṣẹ ayika-kẹkẹ́ na si dabi iṣẹ kẹkẹ́; igi idalu wọn, ati ibi iho, ati ibi ipade, ati abukala wọn, didà ni gbogbo wọn.
34Ifẹsẹtẹ mẹrin li o wà fun igun mẹrin ijoko na: ifẹsẹtẹ na si jẹ ti ijoko tikararẹ̀ papã.
35Ati loke ijoko na, ayika kan wà ti àbọ igbọnwọ: ati loke ijoko na ẹgbẹgbẹti rẹ̀ ati alafo ọ̀na arin rẹ̀ jẹ bakanna.
36Ati lara iha ẹgbẹti rẹ̀, ati leti rẹ̀, li o gbẹ́ aworan kerubu, kiniun, ati igi-ọpẹ gẹgẹ bi aye olukuluku, ati iṣẹ ọṣọ yikakiri.
37Gẹgẹ bayi li o si ṣe awọn ijoko mẹwẹwa: gbogbo wọn li o si ni didà kanna, iwọ̀n kanna ati titobi kanna.
38O si ṣe agbada idẹ mẹwa: agbada kan gbà to òji iwọn Bati: agbada kọ̃kan si jẹ igbọnwọ mẹrin: lori ọkọ̃kan ijoko mẹwẹwa na ni agbada kọ̃kan wà.
39O si fi ijoko marun si apa ọtún ile na, ati marun si apa òsi ile na: o si gbe agbada-nla ka apa ọ̀tún ile na, si apa ila-õrun si idojukọ gusu:
Ìṣírò àwọn ohun èlò tí ó wà ninu ilé OLUWA
(II. Kro 4:11—5:1)
40Hiramu si ṣe ikoko ati ọkọ́, ati awo-koto. Bẹ̃ni Hiramu si pari gbogbo iṣẹ ti o ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba:
41Ọwọ̀n meji, ati ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n meji; ati iṣẹ àwọ̀n meji lati bò ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n;
42Ati irinwo pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n meji, ọ̀wọ́ meji pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n kan, lati bò awọn ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n;
43Ati ijoko mẹwa, ati agbada mẹwa lori awọn ijoko na.
44Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ agbada nla.
45Ati ikoko, ati ọkọ́, ati awo-koto; ati gbogbo ohun-elo wọnyi ti Hiramu ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba, jẹ ti idẹ didan.
46Ni pẹtẹlẹ Jordani ni ọba dà wọn, ni ilẹ amọ̀ ti mbẹ lagbedemeji Sukkoti on Sartani.
47Solomoni si jọwọ gbogbo ohun-elo na silẹ li alaiwọ̀n, nitori ti nwọn papọju: bẹ̃ni a kò si mọ̀ iwọ̀n idẹ na.
48Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Oluwa: pẹpẹ wura, ati tabili wura, lori eyi ti akara ifihan gbe wà.
49Ati ọpa fitila wura daradara, marun li apa ọtún ati marun li apa òsi, niwaju ibi mimọ́-julọ, pẹlu itanna eweko, ati fitila, ati ẹ̀mú wura.
50Ati ọpọ́n, ati alumagaji-fitila, ati awo-koto, ati ṣibi, ati awo turari ti wura daradara; ati agbekọ wura, fun ilẹkun inu ile, ibi mimọ́-julọ, ati fun ilẹkun ile na, ani ti tempili.
51Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ ti Solomoni ọba ṣe fun ile Oluwa pari. Solomoni si mu gbogbo nkan ti Dafidi baba rẹ̀ ti yà si mimọ́ wá; fadaka, ati wura, ati ohun-elo, o si fi wọn sinu iṣura ile Oluwa.

Currently Selected:

I. A. Ọba 7: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy