YouVersion Logo
Search Icon

I. A. Ọba 21

21
Ọgbà Àjàrà Naboti
1O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, Naboti, ara Jesreeli, ni ọgba-ajara ti o wà ni Jesreeli, ti o sunmọ ãfin Ahabu, ọba Samaria girigiri.
2Ahabu si ba Naboti sọ wipe, Fun mi ni ọgba-ajara rẹ, ki emi ki o fi ṣe ọgba-ewebẹ̀, nitori ti o sunmọ ile mi: emi o si fun ọ li ọgba-ajara ti o san jù u lọ dipò rẹ̀; bi o ba si dara li oju rẹ, emi o fi iye-owo rẹ̀ fun ọ.
3Naboti si wi fun Ahabu pe, Oluwa má jẹ ki emi fi ogún awọn baba mi fun ọ.
4Ahabu si wá si ile rẹ̀, o wugbọ, inu rẹ̀ si bajẹ nitori ọ̀rọ ti Naboti, ara Jesreeli, sọ fun u: nitoriti on ti wipe, emi kì o fun ọ ni ogún awọn baba mi. On si dubulẹ lori akete rẹ̀, o si yi oju rẹ̀ padà, kò si fẹ ijẹun.
5Jesebeli, aya rẹ̀ si tọ̀ ọ wá o si wi fun u pe, Ẽṣe ti inu rẹ fi bajẹ́ ti iwọ kò fi jẹun?
6O si wi fun u pe, Nitoriti mo ba Naboti, ara Jesreeli sọ, mo si wi fun u pe, Fun mi ni ọgba-àjara rẹ fun owo; tabi bi o ba wù ọ, emi o fun ọ ni ọgba-àjara miran ni ipò rẹ̀: o si dahùn wipe, Emi kì o fun ọ ni ọgba-àjara mi.
7Jesebeli, aya rẹ̀ si wi fun u pe, iwọ kò ha jọba lori Israeli nisisiyi? Dide, jẹun, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn! emi o fun ọ ni ọgba-àjara Nãboti ara Jesreeli.
8Bẹ̃ni o kọwe li orukọ Ahabu, o si fi èdidi rẹ̀ di i, o si fi iwe na ṣọwọ sọdọ awọn àgbagba ati awọn ọlọla ti mbẹ ni ilu rẹ̀, ti o si mba Naboti gbe.
9O si kọ sinu iwe na pe, Ẹ kede àwẹ, ki ẹ si fi Naboti si ipò ọla lãrin awọn enia.
10Ki ẹ fi enia meji, ẹni buburu, siwaju rẹ̀ lati jẹri pa a, wipe, Iwọ bu Ọlọrun ati ọba. Ẹ mu u jade, ki ẹ si sọ ọ li okuta ki o le kú.
11Awọn ọkunrin ilu rẹ̀, ati awọn àgbagba, ati awọn ọlọla ti nwọn iṣe ara-ilu rẹ̀, ṣe bi Jesebeli ti ranṣẹ si wọn, gẹgẹ bi a ti kọ ọ sinu iwe ti o ti fi ranṣẹ si wọn.
12Nwọn si kede àwẹ, nwọn si fi Naboti si ipò ọla lãrin awọn enia.
13Ọkunrin meji si de, awọn ẹni buburu, nwọn si joko niwaju rẹ̀: awọn ọkunrin buburu si jẹri pa a, ani si Naboti, niwaju awọn enia wipe: Naboti bu Ọlọrun ati ọba. Nigbana ni nwọn mu u jade kuro ni ilu, nwọn si sọ ọ li okuta, o si kú.
14Nigbana ni nwọn ranṣẹ si Jesebeli wipe, A sọ Naboti li okuta, o si kú.
15O si ṣe, nigbati Jesebeli gbọ́ pe, a sọ Naboti li okuta, o si kú, Jesebeli sọ fun Ahabu pe, Dide! ki o si jogun ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli, ti o kọ̀ lati fi fun ọ fun owo; nitori Naboti kò si lãye ṣugbọn o kú.
16O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ pe, Naboti kú, ni Ahabu dide lati sọkalẹ lọ si ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli lati jogun rẹ̀.
17Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe,
18Dide, sọkalẹ, lọ ipade Ahabu, ọba Israeli, ti o wà ni Samaria: wò o, o wà ni ọgba-ajara Naboti, nibiti o sọkalẹ lọ lati jogun rẹ̀.
19Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi: Iwọ ti pa, iwọ si ti jogun pẹlu? Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi pe, Ni ibi ti ajá gbe lá ẹ̀jẹ Naboti, ni awọn ajá yio lá ẹ̀jẹ rẹ, ani tirẹ.
20Ahabu si wi fun Elijah pe, Iwọ ri mi, Iwọ ọta mi? O si dahùn wipe, Emi ri ọ; nitoriti iwọ ti tà ara rẹ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa.
21Kiyesi i, Emi o mu ibi wá si ori rẹ, emi o si mu iran rẹ kuro, emi o si ke kuro lọdọ Ahabu, gbogbo ọmọde ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ, ati omnira ni Israeli.
22Emi o si ṣe ile rẹ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa, ọmọ Ahijah, nitori imunibinu ti iwọ ti mu mi binu, ti iwọ si mu ki Israeli ki o dẹ̀ṣẹ.
23Ati niti Jesebeli pẹlu Oluwa sọ wipe, Awọn ajá yio jẹ Jesebeli ninu yàra Jesreeli.
24Ẹni Ahabu ti o kú ni ilu, ni awọn ajá o jẹ; ati ẹniti o kú ni igbẹ ni awọn ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ.
25Ṣugbọn kò si ẹnikan bi Ahabu ti o tà ara rẹ̀ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa, ẹniti Jesebeli aya rẹ̀ ntì.
26O si ṣe ohun irira gidigidi ni titọ̀ oriṣa lẹhin, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awọn ara Amori ti ṣe, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.
27O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si gbàwẹ, o si dubulẹ ninu aṣọ ọ̀fọ, o si nlọ jẹ́.
28Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe,
29Iwọ ri bi Ahabu ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi? Nitori ti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju mi, emi kì yio mu ibi na wá li ọjọ rẹ̀: li ọjọ ọmọ rẹ̀ li emi o mu ibi na wá sori ile rẹ̀.

Currently Selected:

I. A. Ọba 21: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in