I. A. Ọba 15
15
Abijamu, Ọba Juda
(II. Kro 13:1—14:1)
1NJẸ li ọdun kejidilogun Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, Abijah jọba lori Juda.
2Ọdun mẹta li o jọba ni Jerusalemu: orukọ iya rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu.
3O si rin ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀, ti o ti dá niwaju rẹ̀: ọkàn rẹ̀ kò si pé pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọkàn Dafidi baba rẹ̀.
4Ṣugbọn nitori Dafidi li Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fun u ni imọlẹ kan ni Jerusalemu, lati gbé ọmọ rẹ̀ ró lẹhin rẹ̀, ati lati fi idi Jerusalemu mulẹ:
5Nitori Dafidi ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, kò si yipada kuro ninu gbogbo eyiti o paṣẹ fun u li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, bikoṣe ni kiki ọ̀ran Uriah, ara Hitti.
6Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo.
7Njẹ iyokù iṣe Abijah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ogun si wà lãrin Abijah ati Jeroboamu.
8Abijah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sin i ni ilu Dafidi: Asa, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
Aṣa, Ọba Juda
(II. Kro 15:16—16:6)
9Ati li ogun ọdun Jeroboamu ọba Israeli, ni Asa jọba lori Juda.
10Ọdun mọkanlelogoji li o jọba ni Jerusalemu, orukọ iya nla rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu.
11Asa si ṣe eyiti o tọ loju Oluwa, bi Dafidi baba rẹ̀.
12O si mu awọn ti nṣe panṣaga kuro ni ilẹ na, o si kó gbogbo ere ti awọn baba rẹ̀ ti ṣe kuro.
13Ati Maaka iya rẹ̀ papã, li o si mu kuro lati ma ṣe ayaba, nitori ti o yá ere kan fun oriṣa rẹ̀; Asa si ke ere na kuro; o si daná sun u nibi odò Kidroni.
14Ṣugbọn ibi giga wọnnì ni a kò mu kuro; sibẹ ọkàn Asa pé pẹlu Oluwa li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo.
15O si mu ohun-mimọ́ wọnnì ti baba rẹ̀, ati ohun-mimọ́ wọnnì ti on tikararẹ̀ wọ ile Oluwa, fadaka ati wura, ati ohun-elo wọnnì,
16Ogun si wà lãrin Asa ati Baaṣa, ọba Israeli ni gbogbo ọjọ wọn.
17Baaṣa, ọba Israeli, si goke lọ si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má le jẹ ki ẹnikẹni ki o jade tabi ki o wọle tọ Asa ọba lọ.
18Nigbana ni Asa mu gbogbo fadaka, ati wura ti o kù ninu iṣura ile Oluwa, ati iṣura ile ọba, o si fi wọn si ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀: Asa ọba si rán wọn si ọdọ Benhadadi, ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni, ọba Siria, ti o ngbe Damasku, wipe,
19Jẹ ki majẹmu ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin baba mi ati baba rẹ, kiye si i, emi ran ọrẹ fadaka ati wura si ọ; wá, ki o si dà majẹmu rẹ pẹlu Baaṣa, ọba Israeli, ki o le lọ kuro lọdọ mi.
20Bẹ̃ni Benhadadi fi eti si ti Asa ọba, o si rán awọn alagbara olori-ogun ti o ni, si ilu Israeli wọnnì, o si kọlu Ijoni, ati Dani ati Abel-bet-maaka, ati gbogbo Kenneroti pẹlu gbogbo ilẹ Naftali.
21O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o si ṣiwọ ati kọ́ Rama, o si ngbe Tirsa.
22Nigbana ni Asa ọba kede ká gbogbo Juda, kò da ẹnikan si: nwọn si kó okuta Rama kuro, ati igi rẹ̀, ti Baaṣa fi kọle: Asa ọba si fi wọn kọ́ Geba ti Benjamini, ati Mispa.
23Iyokù gbogbo iṣe Asa, ati gbogbo agbara rẹ̀ ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati ilu wọnnì ti o kọ́, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ṣugbọn li akoko ogbó rẹ̀, àrun ṣe e li ẹsẹ rẹ̀.
24Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
Nadabu, Ọba Israẹli
25Nadabu ọmọ Jeroboamu si bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli li ọdun keji Asa, ọba Juda, o si jọba lori Israeli li ọdun meji.
26O si ṣe buburu niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na baba rẹ̀, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ eyiti o mu Israeli ṣẹ̀.
27Baaṣa ọmọ Ahijah ti ile Issakari, si dìtẹ si i; Baaṣa kọlu u ni Gibbetoni ti awọn ara Filistia: nitori Nadabu ati gbogbo Israeli dó ti Gibbetoni.
28Ani li ọdun kẹta ti Asa ọba Juda, ni Baaṣa pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.
29O si ṣe, nigbati o jọba, o kọlu gbogbo ile Jeroboamu; kò kù fun Jeroboamu ẹniti nmí, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Ọluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah ara Ṣilo:
30Nitori ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ti o ṣẹ̀, ti o si mu ki Israeli ṣẹ̀, nipa imunibinu rẹ̀, eyiti o fi mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli ki o binu.
31Ati iyokù iṣe Nadabu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
32Ogun si wà, lãrin Asa ati Baaṣa ọba Israeli ni gbogbo ọjọ wọn.
Baaṣa, Ọba Israẹli
33Li ọdun kẹta Asa, ọba Juda, ni Baaṣa, ọmọ Ahijah bẹ̀rẹ si ijọba lori gbogbo Israeli ni Tirsa, li ọdun mẹrinlelogun.
34O si ṣe buburu niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na Jeroboamu, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, eyiti o mu Israeli ṣẹ̀.
Currently Selected:
I. A. Ọba 15: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.