YouVersion Logo
Search Icon

I. Kor Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Paulu kọ ìwé rẹ̀ kìnnní sí àwọn ará Kọrinti láti ṣe àlàyé nípa ìyọnu kan tí ó bẹ́ sílẹ̀ ninu ìjọ tí Paulu dá sílẹ̀ níbẹ̀. Ohun tí ó fa ìyọnu yìí ni ọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sìn ati ìgbé-ayé onigbagbọ. Ìlú Kọrinti tóbi gan nígbà náà, oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ni ó sì pésẹ̀ sinu ìlú náà. Ìlú Giriki ni, òun sì ni olú-ìlú gbogbo agbègbè Akaya tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ìjọba Romu. Àwọn nǹǹkan bíi mẹrin ni ó mú kí ìlú Kọrinti lókìkí níbi gbogbo ní àkókò náà. Àwọn ni: ìlọsíwájú òwò, àṣà ìbílẹ̀ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, ìwà ìṣekúṣe níbi gbogbo, ati oríṣìíríṣìí ẹ̀sìn.
Ọ̀rọ̀ tí ó jẹ Paulu Aposteli lógún jùlọ ninu ìwé yìí ni ti àwọn ìyọnu tí ó jẹ mọ́ ti ìyapa ati ti ìṣekúṣe láàrin àwọn ọmọ ìjọ, ati ìbéèrè lórí ọ̀rọ̀ igbeyawo ati ìbálòpọ̀ láàrin ọkunrin ati obinrin; lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rí-ọkàn, ètò ninu ìjọ, oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ati ajinde.
Ó sọ̀rọ̀ pẹlu ọpọlọpọ ìrírí ati ìmọ̀, lórí ìdáhùn tí ìròyìn ayọ̀ Jesu Kristi ní sí àwọn ìbéèrè náà.
Orí kẹtàlá (13) ìwé yìí ni ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé mọ̀ jù lọ. Ninu orí yìí ni Paulu ti ṣe àlàyé lórí bí ìfẹ́ ti jẹ́ ẹ̀bùn tí ó dára jùlọ tí Ọlọrun fún àwọn eniyan rẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-9
Ìyapa ninu ìjọ 1:10—4:21
Ìwà àgbèrè ati ìdílé onigbagbọ 5:1—7:40
Àwọn onigbagbọ ati àwọn abọ̀rìṣà 8:1—11:1
Ìsìn ati ìgbé-ayé ninu ìjọ 11:2—14:40
Ajinde Kristi ati ti àwọn onigbagbọ 15:1-58
Ìtọrẹ-àánú àwọn onigbagbọ ní Judia 16:1-4
Ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́ ati ọ̀rọ̀ ìparí 16:5-24

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in