YouVersion Logo
Search Icon

I. Kor 13:1-6

I. Kor 13:1-6 YBCV

BI mo tilẹ nfọ oniruru ede ati ti angẹli, ti emi kò si ni ifẹ, emi dabi idẹ ti ndún, tabi bi kimbali olohùn goro. Bi mo si ni ẹbun isọtẹlẹ, ti mo si ni oye gbogbo ohun ijinlẹ, ati gbogbo ìmọ; bi mo si ni gbogbo igbagbọ́, tobẹ̃ ti mo le ṣí awọn òke nla nipò, ti emi kò si ni ifẹ, emi kò jẹ nkan. Bi mo si nfi gbogbo ohun ini mi bọ́ awọn talaka, bi mo si fi ara mi funni lati sun, ti emi kò si ni ifẹ, kò li ere kan fun mi. Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀, Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu; Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ

Video for I. Kor 13:1-6