I. Kro 7
7
Àwọn Ìran Isakari
1AWỌN ọmọ Issakari si ni, Tola, ati Pua, Jaṣubu, ati Ṣimroni, mẹrin.
2Ati awọn ọmọ Tola; Ussi, ati Refaiah, ati Jerieli, ati Jamai, ati Jibsamu ati Samueli, awọn olori ile baba wọn, eyini ni ti Tola: akọni alagbara enia ni wọn ni iran wọn; iye awọn ẹniti o jẹ ẹgbã mọkanla o le ẹgbẹta li ọjọ Dafidi.
3Awọn ọmọ Ussi: Israhiah ati awọn ọmọ Israhiah; Mikaeli, ati Obadiah, ati Joeli, ati Iṣiah, marun: gbogbo wọn li olori.
4Ati pẹlu wọn, nipa iran wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, ni awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun fun ogun, ẹgbã mejidilogun enia: nitoriti nwọn ni ọ̀pọlọpọ obinrin ati ọmọ ọkunrin.
5Ati awọn arakunrin wọn ninu gbogbo idile Issakari jẹ akọni alagbara enia, ni kikaye gbogbo wọn nipa iran wọn, nwọn jẹ ẹgbamẹtalelogoji o le ẹgbẹrun.
Àwọn Ìran Bẹnjamini ati Dani
6Awọn ọmọ Benjamini: Bela, ati Bekeri, ati Jediaeli, mẹta.
7Awọn ọmọ Bela; Esboni, ati Ussi, ati Ussieli ati Jerimoti ati Iri, marun; awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia; a si kaye wọn nipa iran wọn si ẹgbãmọkanla enia o le mẹrinlelọgbọ̀n.
8Awọn ọmọ Bekeri: Semira, ati Joaṣi, ati Elieseri, ati Elioeni, ati Omri, ati Jeremotu, ati Abiah, ati Anatoti, ati Alameti. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Bekeri.
9Ati iye wọn, ni idile wọn nipa iran wọn, awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbawa o le igba.
10Awọn ọmọ Jediaeli; Bilhani: ati awọn ọmọ Bilhani: Jeuṣi, ati Benjamini, ati Ehudi, ati Kenaana, ati Setani, ati Tarṣiṣi ati Ahisahari.
11Gbogbo awọn wọnyi ọmọ Jediaeli, nipa olori awọn baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbãjọ o le ẹgbẹfa ọmọ-ogun, ti o le jade lọ si ogun.
12Ati Ṣuppimu, ati Huppimu, awọn ọmọ Iri, ati Huṣimu, awọn ọmọ Aheri.
Àwọn Ìran Nafutali
13Awọn ọmọ Naftali: Jasieli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣallumu, awọn ọmọ Bilha.
Àwọn Ìran Manase
14Awọn ọmọ Manasse; Aṣrieli, ti aya rẹ̀ bi: (ṣugbọn obinrin rẹ̀, ara Aramu, bi Makiri baba Gileadi:
15Makiri si mu arabinrin Huppimu, ati Ṣuppimu li aya, orukọ arabinrin ẹniti ijẹ Maaka,) ati orukọ ekeji ni Selofehadi: Selofehadi si ni awọn ọmọbinrin.
16Maaka, obinrin Makiri, bi ọmọ, on si pè orukọ rẹ̀ ni Pereṣi: orukọ arakunrin rẹ̀ ni Ṣereṣi; ati awọn ọmọ rẹ̀ ni Ulamu ati Rakemu.
17Awọn ọmọ Ulamu: Bedani. Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse.
18Arabinrin rẹ̀, Hammoleketi, bi Iṣodi, ati Abieseri, ati Mahala.
19Ati awọn ọmọ Ṣemida ni, Ahiani, ati Ṣekemu, ati Likki, ati Aniamu.
Àwọn Ìran Efuraimu
20Awọn ọmọ Efraimu: Ṣutela, ati Beredi ọmọ rẹ̀, ati Tahati, ọmọ rẹ̀, ati Elada, ọmọ rẹ̀, ati Tahati ọmọ rẹ̀.
21Ati Sabadi ọmọ rẹ̀, ati Ṣutela ọmọ rẹ̀, ati Eseri, ati Eleadi, ẹniti awọn ọkunrin Gati, ti a bi ni ilẹ na, pa, nitori nwọn sọkalẹ wá lati kó ẹran ọ̀sin wọn lọ.
22Efraimu baba wọn si ṣọ̀fọ li ọjọ pupọ, awọn arakunrin rẹ̀ si wá lati tù u ninu.
23Nigbati o si wọle tọ̀ aya rẹ̀ lọ, o loyun o si bi ọmọ kan, on si pè orukọ rẹ̀ ni Beria, nitoriti ibi ba ile rẹ̀.
24Ọmọ rẹ̀ obinrin ni Sera, ẹniti o tẹ̀ Bet-horoni dó, ti isalẹ ati ti òke, ati Usseni Ṣera.
25Refa si ni ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Reṣefu pẹlu, ati Tela ọmọ rẹ̀, ati Tahani ọmọ rẹ̀.
26Laadani ọmọ rẹ̀, Ammihudi ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀.
27Nuni ọmọ rẹ̀, Joṣua ọmọ rẹ̀,
28Ati awọn ini ati ibugbe wọn ni Beteli, ati ilu rẹ̀, ati niha ìla-õrùn Naarani, niha ìwọ-õrùn Geseri pẹlu ilu rẹ̀: Ṣekemu pẹlu ati ilu rẹ̀, titi de Gasa ilu rẹ̀:
29Ati leti ilu awọn ọmọ Manasse, Betṣeani, ati ilu rẹ̀, Taanaki ati ilu rẹ̀, Megiddo ati ilu rẹ̀, Dori ati ilu rẹ̀. Ninu awọn wọnyi li awọn ọmọ Josefu, ọmọ Israeli, ngbe.
Àwọn Ìran Aṣeri
30Awọn ọmọ Aṣeri: Imna, ati Iṣua, ati Iṣuai, ati Beria, ati Sera, arabinrin wọn.
31Awọn ọmọ Beria: Heberi, ati Malkieli, ti iṣe baba Birsafiti.
32Heberi si bi Jafleti, ati Ṣomeri, ati Hotamu, ati Ṣua, arabinrin wọn.
33Ati awọn ọmọ Jafleti: Pasaki, ati Bimhali, ati Aṣfati. Wọnyi li awọn omọ Jafleti.
34Awọn ọmọ Ṣameri: Ahi, ati Roga, Jehubba, ati Aramu.
35Awọn ọmọ arakunrin rẹ̀ Helemu: Sofa, ati Imna, ati Ṣeleṣi, ati Amali.
36Awọn ọmọ Sofa; Sua, ati Harneferi, ati Ṣuali, ati Beri, ati Imra,
37Beseri, ati Hodi, ati Ṣamma, ati Ṣilṣa, ati Itrani, ati Beera.
38Ati awọn ọmọ Jeteri: Jefunne, ati Pispa, ati Ara.
39Ati awọn ọmọ Ulla: Ara, ati Hanieli, ati Resia.
40Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Aṣeri, awọn olori ile baba wọn, aṣayan alagbara akọni enia, olori ninu awọn ijoye. Iye awọn ti a kà yẹ fun ogun, ati fun ijà ni idile wọn jẹ, ẹgbã mẹtala ọkunrin.
Currently Selected:
I. Kro 7: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.