I. Kro 4
4
Ìran Juda
1AWỌN ọmọ Juda; Faresi, Hesroni, ati Karmi, ati Huri, ati Ṣobali.
2Reaiah ọmọ Ṣobali si bi Jahati; Jahati si bi Ahumai, ati Lahadi. Wọnyi ni idile awọn ara Sora.
3Awọn wọnyi li o ti ọdọ baba Etamu wá; Jesreeli ati Jisma, ati Jidbaṣi: orukọ arabinrin wọn si ni Selelponi:
4Ati Penueli ni baba Gedori, ati Eseri baba Huṣa. Wọnyi ni awọn ọmọ Huri, akọbi Efrata, baba Betlehemu.
5Aṣuri baba Tekoa si li aya meji, Hela ati Naara.
6Naara si bi Ahusamu, ati Heferi, ati Temeni, ati Ahaṣtari fun u. Wọnyi li awọn ọmọ Naara.
7Ati awọn ọmọ Hela ni Sereti, ati Jesoari, ati Etnani.
8Kosi si bi Anubu, ati Sobeba, ati awọn idile Aharheli, ọmọ Harumu.
9Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ.
10Jabesi si ké pè Ọlọrun Israeli, wipe, Iwọ iba jẹ bukún mi nitõtọ, ki o si sọ àgbegbe mi di nla, ki ọwọ rẹ ki o si wà pẹlu mi, ati ki iwọ ki o má si jẹ ki emi ri ibi, ki emi má si ri ibinujẹ! Ọlọrun si mu ohun ti o tọrọ ṣẹ.
Àwọn ìdílé yòókù
11Kelubu arakunrin Ṣua si bi Mehiri, ti iṣe baba Eṣtoni.
12Eṣtoni si bi Bet-rafa, ati Pasea, ati Tehinna baba ilu Nahaṣi. Wọnyi li awọn ọkunrin Reka,
13Ati awọn ọmọ Kenasi; Otnieli, ati Seraiah: ati awọn ọmọ Otnieli; Hatati.
14Meonotai si bi Ofra: Seraiah si bi Joabu, baba Geharasimu; nitori oniṣọnà ni nwọn.
15Ati awọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne; Iru, Ela, ati Naamu: ati awọn ọmọ Ela, ani Kenasi.
16Ati awọn ọmọ Jehaleleeli; Sifu, ati Sifa, Tiria, ati Asareeli.
17Ati awọn ọmọ Esra ni Jeteri, ati Meredi, ati Eferi, ati Jaloni: on si bi Miriamu, ati Ṣammai, ati Iṣba baba Eṣtemoa.
18Aya rẹ̀ Jehudijah si bi Jeredi baba Gedori, ati Heberi baba Soke, ati Jekutieli baba Sanoa. Wọnyi si li awọn ọmọ Bitiah ọmọbinrin Farao ti Meredi mu li aya.
19Ati awọn ọmọ aya Hodiah, arabinrin Nahamu, baba Keila, ara Garmi, ati Eṣtemoa ara Maaka:
20Awọn ọmọ Ṣimoni si ni Amnoni, ati Rinna, Benhanani, ati Tiloni. Ati awọn ọmọ Iṣi ni, Soheti, ati Bensoheti,
Àwọn Ìran Ṣela
21Awọn ọmọ Ṣela, ọmọ Juda ni, Eri baba Leka, ati Laada baba Mareṣa ati idile ile awọn ti nwọn nwun aṣọ ọ̀gbọ daradara, ti ile Aṣbea,
22Ati Jokimu, ati awọn ọkunrin Koseba, ati Joaṣi, ati Sarafu, ti o ni ijọba ni Moabu, ati Jaṣubilehemu. Iwe iranti atijọ ni wọnyi.
23Wọnyi li awọn amọkoko, ati awọn ti ngbe ãrin ọgba ti odi yika; nibẹ ni nwọn ngbe pẹlu ọba fun iṣẹ rẹ̀.
Àwọn Ìran Simeoni
24Awọn ọmọ Simeoni ni, Nemueli, ati Jamini, Jaribi, Sera, Ṣauli:
25Ṣallumu ọmọ rẹ̀, Mibsamu ọmọ rẹ̀, Miṣma ọmọ rẹ̀.
26Ati awọn ọmọ Miṣma; Hammueli ọmọ rẹ̀, Sakkuri ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀.
27Ṣimei si ni ọmọkunrin mẹrindilogun, ati ọmọbinrin mẹfa; ṣugbọn awọn arakunrin rẹ̀ kò ni ọmọkunrin pupọ, bẹ̃ni kì iṣe idile wọn gbogbo li o rẹ̀ gẹgẹ bi awọn ọmọ Juda.
28Nwọn si ngbe Beerṣeba, ati Molada, ati Haṣari-ṣuali,
29Ati ni Bilha, ati ni Esemu, ati ni Toladi,
30Ati ni Betueli, ati ni Horma, ati ni Siklagi,
31Ati ni Bet-markaboti, ati ni Hasar-susimu, ati ni Bet-birei, ati Ṣaaraimu. Awọn wọnyi ni ilu wọn, titi di ijọba Dafidi.
32Ileto wọn si ni, Etamu, ati Aini, Rimmoni, ati Tokeni, ati Aṣani, ilu marun:
33Ati gbogbo ileto wọn, ti o wà yi ilu na ka, de Baali. Wọnyi ni ibugbe wọn, ati itan idile wọn.
34Ati Meṣobabu ati Jamleki, ati Joṣa ọmọ Amasiah.
35Ati Joeli, ati Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,
36Ati Elioenai, ati Jaakoba, ati Jeṣohaiah, ati Asaiah, ati Adieli, ati Jesimieli, ati Benaiah,
37Ati Sisa ọmọ Ṣifi, ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah;
38Awọn ti a darukọ wọnyi, ìjoye ni wọn ni idile wọn: ile baba wọn si tan kalẹ gidigidi.
39Nwọn si wọ̀ oju-ọ̀na Gedori lọ, titi de apa ariwa afonifoji na, lati wá koriko fun agbo ẹran wọn.
40Nwọn si ri koriko tutù ti o si dara; ilẹ na si gbàye, o si gbe jẹ, o si wà li alafia: nitori awọn ọmọ Hamu li o ti ngbe ibẹ li atijọ.
41Ati awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn, dé li ọjọ Hesekiah ọba Juda, nwọn si kọlu agọ wọn, ati pẹlu awọn ara Mehuni ti a ri nibẹ, nwọn si bà wọn jẹ patapata titi di oni yi, nwọn si ngbe ipò wọn: nitori koriko mbẹ nibẹ fun agbo ẹran wọn.
42Omiran ninu wọn, ani ninu awọn ọmọ Simeoni, ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin, lọ si òke Seiri, nwọn ni Pelatiah, ati Neariah, ati Refaiah ati Ussieli, awọn ọmọ Iṣi li olori wọn.
43Nwọn si kọlù iyokù awọn ara Amaleki, ti nwọn salà, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi.
Currently Selected:
I. Kro 4: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.