YouVersion Logo
Search Icon

I. Kro 2

2
Àwọn Arọmọdọmọ Juda
1WỌNYI ni awọn ọmọ Israeli; Rubeni, Simeoni, Lefi, ati Juda, Issakari, ati Sebuluni,
2Dani, Josefu, ati Benjamini, Naftali, Gadi, ati Aṣeri.
3Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela; awọn mẹta yi ni Batṣua, ara Kenaani, bi fun u. Eri, akọbi Juda, si buru loju Oluwa; on si pa a.
4Tamari aya-ọmọ rẹ̀ si bi Faresi ati Sera fun u. Gbogbo awọn ọmọ Juda jẹ marun.
5Awọn ọmọ Faresi; Hesroni; ati Hamuli.
6Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun.
7Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀.
8Awọn ọmọ Etani; Asariah.
Ìran Dafidi Ọba
9Awọn ọmọ Hesroni pẹlu ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai.
10Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda;
11Naṣoni si bi Salma, Salma si bi Boasi.
12Boasi si bi Obedi, Obedi si bi Jesse,
13Jesse si bi Eliabu akọbi rẹ̀, ati Abinadabu àtẹle, ati Ṣimma ẹkẹta.
14Netanneeli ẹkẹrin, Raddai ẹkarun,
15Osemu ẹkẹfa, Dafidi ekeje:
16Awọn arabinrin wọn ni Seruiah ati Abigaili. Ati awọn ọmọ Seruiah; Abiṣai, ati Joabu, ati Asaeli, mẹta.
17Abigaili si bi Amasa: baba Amasa si ni Jeteri ara Iṣmeeli.
Ìran Hesironi
18Kalebu ọmọ Hesroni si bi ọmọ lati ọdọ Asuba aya rẹ̀, ati lati ọdọ Jeriotu: awọn ọmọ rẹ̀ ni wọnyi; Jeṣeri, ati Ṣohabu, ati Ardoni.
19Nigbati Asuba kú, Kalebu mu Efrati, ẹniti o bi Huri fun u.
20Huri si bi Uru, Uru si bi Besaleeli.
21Lẹhin na Hesroni si wọle tọ̀ ọmọ Makiri obinrin baba Gileadi, on gbe e ni iyawo nigbati o di ẹni ọgọta ọdun, on si bi Segubu fun u.
22Segubu si bi Jairi, ti o ni ilu mẹtalelogun ni ilẹ Gileadi.
23Ṣugbọn Geṣuri, ati Aramu, gbà ilu Jairi lọwọ wọn, pẹlu Kenati, ati ilu rẹ̀: ani ọgọta ilu. Gbogbo wọnyi ni awọn ọmọ Makiri baba Gileadi.
24Ati lẹhin igbati Hesroni kú ni ilu Kaleb-Efrata, ni Abiah aya Hesroni bi Aṣuri baba Tekoa fun u.
Àwọn Ìran Jerameeli
25Ati awọn ọmọ Jerahmeeli, akọbi Hesroni, ni Rama akọbi, ati Buna, ati Oreni, ati Osemu, ati Ahijah.
26Jerahmeeli si ni obinrin miran pẹlu, orukọ ẹniti ijẹ Atara; on ni iṣe iya Onamu.
27Awọn ọmọ Ramu akọbi Jerahmeeli ni, Maasi, ati Jamini, ati Ekeri.
28Awọn ọmọ Onamu si ni, Ṣammai, ati Jada. Awọn ọmọ Ṣammai ni; Nadabu ati Abiṣuri.
29Orukọ aya Abiṣuri si njẹ Abihaili, on si bi Abani, ati Molidi fun u.
30Ati awọn ọmọ Nadabu; Seledi, ati Appaimu: ṣugbọn Seledi kú laini ọmọ.
31Ati awọn ọmọ Appaimu; Iṣi. Ati awọn ọmọ Iṣi; Ṣeṣani. Ati awọn ọmọ Ṣeṣani. Ahlai.
32Ati awọn ọmọ Jada arakunrin Ṣammai; Jeteri, ati Jonatani; Jeteri si kú laini ọmọ.
33Awọn ọmọ Jonatani; Peleti, ati Sasa. Wọnyi ni awọn ọmọ Jerahmeeli.
34Ṣeṣani kò si ni ọmọkunrin, bikọṣe ọmọbinrin. Ṣeṣani si ni iranṣẹ kan, ara Egipti, orukọ, ẹniti ijẹ Jarha.
35Ṣeṣani si fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Jarha iranṣẹ rẹ̀ li aya; on si bi Attai fun u.
36Attai si bi Natani, Natani si bi Sabadi,
37Sabadi si bi Eflali, Eflali si bi Obedi,
38Obedi si bi Jehu, Jehu si bi Asariah,
39Asariah si bi Helesi, Helesi si bi Elasa,
40Elasa si bi Sisamai, Sisamai si bi Ṣallumu,
41Ṣallumu si bi Jekamiah, Jekamiah si bi Eliṣama.
Àwọn Ìran Kalebu Yòókù
42Awọn ọmọ Kalebu arakunrin Jerahmeeli si ni Meṣa akọbi rẹ̀, ti iṣe baba Sifi; ati awọn ọmọ Mareṣa baba Hebroni.
43Awọn ọmọ Hebroni; Kora, ati Tappua, ati Rekemu, ati Ṣema.
44Ṣema si bi Rahamu, baba Jorkeamu: Rekemu si bi Ṣammai.
45Ati ọmọ Ṣammai ni Maoni: Maoni si ni baba Bet-suri.
46Efa obinrin Kalebu si bi Harani, ati Mosa, ati Gasesi: Harani si bi Gasesi.
47Ati awọn ọmọ Jahdai; Regemu, ati Jotamu, ati Geṣamu, ati Peleti, ati Efa, ati Ṣaafu.
48Maaka obinrin Kalebu bi Ṣeberi, ati Tirhana.
49On si bi Ṣaafa baba Madmana, Ṣefa baba Makbena, ati baba Gibea: ọmọbinrin Kalebu si ni Aksa.
50Wọnyi li awọn ọmọ Kalebu ọmọ Huri, akọbi Efrata; Ṣobali baba Kirjat-jearimu,
51Salma baba Bet-lehemu, Harefu baba Bet-gaderi.
52Ati Ṣobali baba Kirjat-jearimu ni ọmọ; Haroe, ati idaji awọn ara Manaheti.
53Ati awọn idile Kirjat-jearimu; awọn ara Itri, ati awọn ara Puti, ati awọn ara Ṣummati, ati awọn ara Misrai; lọdọ wọn li awọn ara Sareati, ati awọn ara Ẹstauli ti wá.
54Awọn ọmọ Salma; Betlehemu, ati awọn ara Netofati, Ataroti, ile Joabu, ati idaji awọn ara Manahati, awọn ara Sori.
55Ati idile awọn akọwe ti ngbe Jabesi; awọn ara Tira, awọn ara Ṣimeati, ati awọn ara Sukati. Wọnyi li awọn ara Keni ti o ti ọdọ Hemati wá, baba ile Rekabu.

Currently Selected:

I. Kro 2: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in