YouVersion Logo
Search Icon

I. Kro 14

14
Akitiyan Dafidi ní Jerusalẹmu
(II. Sam 5:11-16)
1HIRAMU ọba Tire si ran onṣẹ si Dafidi, ati igi Kedari, pẹlu awọn ọmọle ati gbẹnagbẹna, lati kọ́le fun u.
2Dafidi si woye pe, Oluwa ti fi idi on joko li ọba lori Israeli, nitori a gbé ijọba rẹ̀ ga nitori ti awọn enia rẹ̀, Israeli.
3Dafidi si mu awọn aya si i ni Jerusalemu: Dafidi si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin si i.
4Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ti o ni ni Jerusalemu; Ṣammua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni,
5Ati Ibhari, ati Eliṣua, ati Elpaleti,
6Ati Noga, ati Nefegi, ati Jafia,
7Ati Eliṣama, ati Beeliada, ati Elifaleti.
Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Filistia
(II. Sam 5:17-25)
8Nigbati awọn ara Filistia si gbọ́ pe, a fi ororo yan Dafidi li ọba lori gbogbo Israeli, gbogbo awọn ara Filistia gòke lọ iwá Dafidi: Dafidi si gbọ́, o si jade tọ̀ wọn.
9Awọn ara Filistia si wá, nwọn si tẹ ara wọn ni afonifoji Refaimu.
10Dafidi si bere lọdọ Ọlọrun wipe, Ki emi ki o gòke tọ awọn ara Filistia lọ? Iwọ o ha fi wọn le mi lọwọ? Oluwa si wi fun u pe, Gòke lọ, emi o si fi wọn le ọ lọwọ.
11Bẹ̃ni nwọn gòke lọ si Baal-perasimu; Dafidi si kọlù wọn nibẹ. Dafidi si wipe, Ọlọrun ti ti ọwọ mi yà lu awọn ọta mi bi yiya omi: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ na ni Baal-perasimu.
12Nwọn si fi awọn orisa wọn silẹ nibẹ, Dafidi si wipe, ki a fi iná sun wọn.
13Awọn ara Filistia si tun tẹ ara wọn kakiri ni afonifoji.
14Nitorina ni Dafidi tun bère lọwọ Ọlọrun: Ọlọrun si wi fun u pe, Máṣe gòke tọ̀ wọn; yipada kuro lọdọ wọn, ki o si ja lu wọn niwaju igi mulberi.
15Yio si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lòke igi mulberi, nigbana ni ki iwọ ki o gbogun jade: nitori Ọlọrun jade ṣaju rẹ lọ lati kọlù ogun awọn ara Filistia.
16Dafidi si ṣe gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun u: nwọn si kọlù ogun awọn ara Filistia lati Gibeoni titi de Gaseri.
17Okiki Dafidi si kan yi gbogbo ilẹ ka. Oluwa si mu ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o ba gbogbo orilẹ-ède.

Currently Selected:

I. Kro 14: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in