SAKARAYA 12
12
Ìlérí ìdáǹdè fún Jerusalẹmu
1Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí Israẹli nìyí, OLUWA tí ó ta ọ̀run bí aṣọ, tí ó dá ayé, tí ó sì dá ẹ̀mí sinu eniyan, ni ó sọ báyìí pé, 2“N óo ṣe ìlú Jerusalẹmu bí ife ọtí àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Wọn óo dojú kọ ilẹ̀ Juda, wọn óo sì dóti ìlú Jerusalẹmu. 3Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, n óo mú kí ilẹ̀ Jerusalẹmu le kankan bí òkúta tí ó wúwo, orílẹ̀-èdè tí ó bá dábàá pé òun óo ṣí i nídìí, yóo farapa yánnayànna. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo sì parapọ̀ láti bá a jà. 4Ní ọjọ́ náà, n óo dẹ́rùba àwọn ẹṣin, n óo sì fi wèrè kọlu àwọn tí wọn ń gùn wọ́n. Ṣugbọn n óo máa ṣọ́ àwọn ará Juda, n óo sì fọ́ ojú ẹṣin àwọn ọ̀tá wọn. 5Àwọn ará Juda yóo wá máa sọ láàrin ara wọn pé, ‘OLUWA, àwọn ọmọ ogun ti sọ àwọn ará Jerusalẹmu di alágbára.’
6“Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ́ kí àwọn ará Juda dàbí ìkòkò iná tí ń jó ninu igbó, àní, bí iná tí ń jó láàrin oko ọkà, wọn yóo jó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri, ṣugbọn Jerusalẹmu yóo wà láàyè rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
7“OLUWA yóo kọ́kọ́ fún àwọn ogun Juda ní ìṣẹ́gun, kí ògo ilé Dafidi ati ògo àwọn ará Jerusalẹmu má baà ju ti Juda lọ. 8Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo dáàbò bo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ẹni tí ó ṣe aláìlera jùlọ ninu wọn yóo lágbára bíi Dafidi. Ìdílé Dafidi yóo dàbí Ọlọrun, yóo máa darí wọn bí angẹli OLUWA. 9Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá gbógun ti ìlú Jerusalẹmu.
10“N óo fi ẹ̀mí àánú ati adura sí ọkàn àwọn ọmọ Dafidi ati àwọn ará Jerusalẹmu, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ pé, bí wọ́n bá wo ẹni tí wọ́n gún lọ́kọ̀, wọn yóo máa ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Wọn yóo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn bí ẹni tí àkọ́bí rẹ̀ ṣàìsí.#Joh 19:37; Ifi 1:7 11Ní àkókò náà, ọ̀fọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu yóo pọ̀ bí ọ̀fọ̀ tí wọ́n ṣe fún Hadadi Rimoni ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido. 12Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ náà yóo ṣọ̀fọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi yóo dá ọ̀fọ̀ tirẹ̀ ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Natani náà yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. 13Ìdílé Lefi yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Ṣimei pàápàá yóo ṣọ̀fọ̀ tirẹ̀ lọ́tọ̀, àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà lọ́tọ̀; 14gbogbo àwọn ìdílé yòókù ni wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn iyawo wọn náà yóo sì ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀.”#Mat 24:20; Ifi 1:7
Currently Selected:
SAKARAYA 12: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010