TITU 2
2
Ẹ̀kọ́ tí ó Yè Kooro
1Ní tìrẹ, àwọn ohun tí ó bá ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro mu ni kí ó máa ti ẹnu rẹ jáde. 2Àwọn àgbà ọkunrin níláti jẹ́ ẹni tí ó ń ṣe pẹ̀lẹ́, ẹni ọ̀wọ̀, ọlọ́gbọ́n, tí ó jinná ninu igbagbọ, ninu ìfẹ́ ati ninu ìfaradà. 3Bákan náà, àwọn àgbà obinrin níláti jẹ́ ẹni tí gbogbo ìgbé-ayé wọn bá ti ìsìn Ọlọrun mu. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ onísọkúsọ tabi ẹrú ọtí. Wọ́n níláti máa kọ́ni ní ohun rere. 4Kí wọn máa fi òye kọ́ àwọn ọdọmọbinrin wọn láti fẹ́ràn ọkọ wọn ati ọmọ wọn. 5Kí wọn máa fara balẹ̀, kí wọn sì fara mọ́ ọkọ wọn nìkan. Kí wọn má ya ọ̀lẹ ninu iṣẹ́ ilé, kí wọn sì jẹ́ onínú rere. Kí wọn máa gbọ́ràn sí ọkọ wọn lẹ́nu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè sọ ìsọkúsọ sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
6Bákan náà, máa gba àwọn ọdọmọkunrin níyànjú láti fara balẹ̀. 7Kí o ṣe ara rẹ ní àpẹẹrẹ rere ní gbogbo ọ̀nà. Ninu ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ àwọn eniyan, kí wọn rí òtítọ́ ninu rẹ, kí wọn sì rí ìwà àgbà lọ́wọ́ rẹ. 8Kí gbolohun ẹnu rẹ jẹ́ ti ọmọlúwàbí, tí ẹnìkan kò ní lè fi bá ọ wí. Èyí yóo mú ìtìjú bá ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe alátakò nígbà tí kò bá rí ohun burúkú kan sọ nípa wa.
9Kí àwọn ẹrú fi ara wọn sí abẹ́ àṣẹ ọ̀gá wọn ninu ohun gbogbo. Kí wọn máa ṣe nǹkan tí yóo tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọn má máa fún wọn lésì. 10Kí wọn má máa ja ọ̀gá wọn lólè. Ṣugbọn kí wọn jẹ́ olóòótọ́ ati ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀nà gbogbo. Báyìí ni wọn yóo fi ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́ ninu ohun gbogbo.
11Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti farahàn fún ìgbàlà gbogbo eniyan. 12Ó ń tọ́ wa sọ́nà pé kí á kọ ìwà aibikita fún Ọlọrun ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé sílẹ̀, kí á máa farabalẹ̀. Kí á máa gbé ìgbé-ayé òdodo, kí á sì jẹ́ olùfọkànsìn ní ayé yìí. 13Kí á máa dúró de ibukun tí à ń retí, ati ìfarahàn ògo Ọlọrun ẹni ńlá, ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi, 14ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere.#a O. Daf 130:8; b Eks 19:5; Diut 4:20, 7:6; 14:2; 1 Pet 2:9.
15Báyìí ni kí o máa wí fún wọn, kí o máa fi gbà wọ́n níyànjú kí o sì máa bá wọn wí nígbà gbogbo pẹlu àṣẹ. Má gbà fún ẹnikẹ́ni láti fojú tẹmbẹlu rẹ.
Currently Selected:
TITU 2: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010