YouVersion Logo
Search Icon

ORIN SOLOMONI 7

7
1Ẹsẹ̀ rẹ ti dára tó ninu bàtà,
ìwọ, ọmọ aládé.
Itan rẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́,
tí ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà ṣe.
2Ìdodo rẹ dàbí abọ́,
tí kì í gbẹ fún àdàlú waini,
ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà,
tí a fi òdòdó lílì yíká.
3Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji,
tí wọn jẹ́ ìbejì.
4Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́.
Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni,
tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu.
Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni,
tí ó dojú kọ ìlú Damasku.
5Orí rẹ dàbí adé lára rẹ, ó rí bí òkè Kamẹli,
irun rẹ dàbí aṣọ elése-àlùkò tí ó ṣẹ́ léra, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́
irun orí rẹ ń dá ọba lọ́rùn.
6O dára, o wuni gan-an,
olùfẹ́ mi, ẹlẹgẹ́ obinrin.
7Ìdúró rẹ dàbí igi ọ̀pẹ,
ọyàn rẹ ṣù bí ìdì èso àjàrà.
8Mo ní n óo gun ọ̀pẹ ọ̀hún,
kí n di odi rẹ̀ mú.
Kí ọmú rẹ dàbí ìdì èso àjàrà,
kí èémí ẹnu rẹ rí bí òórùn èso ápù.
9Ìfẹnukonu rẹ dàbí ọtí waini tí ó dára jùlọ,
tí ń yọ́ lọ lọ́nà ọ̀fun,
tí ń yọ́ lọ láàrin ètè ati eyín.
Obinrin
10Olùfẹ́ mi ló ni mí,
èmi ni ọkàn rẹ̀ sì fẹ́.
11Máa bọ̀, olùfẹ́ mi,
jẹ́ kí á jáde lọ sinu pápá,
kí á lọ sùn ní ìletò kan.
12Kí á lọ sinu ọgbà àjàrà láàárọ̀ kutukutu,
kí á wò ó bóyá àjàrà ti ń rúwé,
bóyá ó ti ń tanná;
kí á wò ó bóyá igi Pomegiranate ti ń tanná,
níbẹ̀ ni n óo ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13Èso Mandirake ń tú òórùn dídùn jáde,
ẹnu ọ̀nà wa kún fún oríṣìíríṣìí èso tí ó wuni,
tí mo ti pèsè wọn dè ọ́, olùfẹ́ mi,
ati tuntun ati èyí tó ti pẹ́ nílé.

Currently Selected:

ORIN SOLOMONI 7: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in