ORIN SOLOMONI 2
2
1Òdòdó Ṣaroni ni mí,
ati òdòdó Lílì tí ó wà ninu àfonífojì.
Ọkunrin
2Bí òdòdó lílì ti rí láàrin ẹ̀gún,
ni olólùfẹ́ mi rí láàrin àwọn ọmọge.
Obinrin
3Bí igi ápù ti rí láàrin àwọn igi igbó,
ni olùfẹ́ mí rí láàrin àwọn ọmọkunrin.
Pẹlu ìdùnnú ńlá ni mo fi jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀,
èso rẹ̀ sì dùn lẹ́nu mi.
4Ó mú mi wá sí ilé àsè ńlá,
ìfẹ́ ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.
5Fún mi ni èso àjàrà gbígbẹ jẹ,
kí ara mi mókun,
fún mi ní èso ápù jẹ kí ara tù mí,
nítorí pé, àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
6Ó wù mí kí ọwọ́ òsì rẹ̀ wà ní ìgbèrí mi,
kí ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fà mí mọ́ra.
7Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,
ní orúkọ egbin, ati ti àgbọ̀nrín pé,
ẹ kò gbọdọ̀ jí ìfẹ́ títí yóo fi wù ú láti jí.
Orin Keji
Obinrin
8Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀,
ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá,
ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.
9Olólùfẹ́ mi dàbí egbin,
tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín.
Wò ó! Ó dúró lẹ́yìn ògiri ilé wa,
ó ń yọjú lójú fèrèsé,
ó ń yọjú níbi fèrèsé kékeré tí ó wà lókè.
10Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé,
“Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,
jẹ́ kí á máa lọ.”
Ọkunrin
11Àkókò òtútù ti lọ,
òjò sì ti dáwọ́ dúró.
12Àwọn òdòdó ti hù jáde,
àkókò orin kíkọ ti tó,
a sì ti ń gbọ́ ohùn àwọn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13Àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń so èso,
àjàrà tí ń tanná,
ìtànná wọn sì ń tú òórùn dídùn jáde.
Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,
jẹ́ kí á máa lọ.
14Àdàbà mi, tí ó wà ninu pàlàpálá òkúta,
ní ibi kọ́lọ́fín òkúta,
jẹ́ kí n rójú rẹ, kí n gbọ́ ohùn rẹ,
nítorí ohùn rẹ dùn, ojú rẹ sì dára.
15Mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ wọ̀n-ọn-nì,
àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí wọn ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,
nítorí ọgbà àjàrà wa tí ń tanná.
Obinrin
16Olùfẹ́ mi ni ó ni mí, èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi,
ó ń da àwọn ẹran rẹ̀, wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì.
17Tún pada wá! Olùfẹ́ mi,
títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,
tí òjìji kò ní sí mọ́.
Pada wá bí egbin ati akọ àgbọ̀nrín,
lórí àwọn òkè págunpàgun.
Currently Selected:
ORIN SOLOMONI 2: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010