ROMU 9
9
Ọlọrun Yan Israẹli
1Òtítọ́ ni ohun tí mò ń sọ yìí; n kò purọ́, nítorí Kristi ni ó ni mí. Ọkàn mi tí Ẹ̀mí ń darí sì jẹ́ mi lẹ́rìí pẹlu, pé, 2ohun ìbànújẹ́ ńlá ati ẹ̀dùn ọkàn ni ọ̀ràn àwọn eniyan mi jẹ́ fún mi nígbà gbogbo. 3Mo fẹ́rẹ̀ lè gbadura pé kí á sọ èmi fúnra mi di ẹni ègún, kí á yà mí nípa kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí ti àwọn ará mi, àwọn tí a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà. 4Ọmọ Israẹli ni wọ́n. Àwọn ni Ọlọrun yàn bí ọmọ rẹ̀. Àwọn ni ó fi ògo rẹ̀ hàn fún. Àwọn náà ni ó bá dá majẹmu, tí ó fún ní Òfin rẹ̀, tí ó sì kọ́ lọ́nà ẹ̀sìn rẹ̀. Àwọn ni ó ṣe ìlérí fún.#Eks 4:22 5Àwọn ni irú-ọmọ àwọn baba-ńlá ayé àtijọ́. Láàrin wọn ni Mesaya sì ti wá sáyé gẹ́gẹ́ bí eniyan. Ìyìn ni fún Ọlọrun, ẹni tíí ṣe olùdarí ohun gbogbo, lae ati laelae. Amin.
6Sibẹ, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kùnà patapata. Nítorí kì í ṣe gbogbo àwọn tí a bí sinu ìdílé Israẹli ni ọmọ Israẹli tòótọ́. 7Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ìran Abrahamu ni ọmọ rẹ̀ tòótọ́, nítorí bí Ìwé Mímọ́ ti wí, Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Àwọn ọmọ Isaaki nìkan ni a óo kà sí ìran fún ọ.”#Jẹn 21:12 8Èyí ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ tí a bí nípa ti ara lásán ni ọmọ Ọlọrun. Àwọn ọmọ tí a bí nípa ìlérí Ọlọrun ni a kà sí ìran Abrahamu. 9Nítorí báyìí ni ọ̀rọ̀ ìlérí náà: “Nígbà tí mo bá pada wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóo ti bí ọmọkunrin kan.”#Jẹn 18:10
10Èyí nìkan kọ́. Rebeka bímọ meji fún ẹnìkan ṣoṣo, òun náà ni baba wa Isaaki. 11-12Ṣugbọn kí á tó bí àwọn ọmọ náà, àní sẹ́, kí wọ́n tó dá ohunkohun ṣe, yálà rere ni tabi burúkú, ni Ọlọrun ti sọ fún Rebeka pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo máa ṣe iranṣẹ àbúrò rẹ̀.” Báyìí ni Ọlọrun ti ń ṣe ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé, nígbà tí ó bá yan àwọn kan. Ó wá hàn kedere pé Ọlọrun kì í wo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan kí ó tó yàn wọ́n; àwọn tí ó bá pinnu tẹ́lẹ̀ láti yàn ní í pè.#Jẹn 25:23 13Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Jakọbu ni mo yàn, Esau ni mo kọ̀.”#Mal 1:2-3
14Kí ni kí á wá wí sí èyí? Kí á wí pé Ọlọrun ń ṣe àìdára ni bí? Rárá o! 15Nítorí ó sọ fún Mose pé, “Ẹni tí mo bá fẹ́ ṣàánú ni n óo ṣàánú; ẹni tí mo bá sì fẹ́ yọ́nú sí ni n óo yọ́nú sí.”#Eks 33:19 16Nítorí náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí eniyan ti fẹ́ tabi bí ó ti gbìyànjú tó ni Ọlọrun fi ń yàn án, bí ó bá ti wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ ni. 17Nítorí Ọlọrun sọ ninu Ìwé Mímọ́ nípa Farao pé, “Ìdí tí mo fi fi ọ́ jọba ni pé, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe àpẹẹrẹ bí agbára mi ti tó, ati pé kì ìròyìn orúkọ mi lè tàn ká gbogbo ayé.”#Eks 9:16 18Nítorí náà, ẹni tí ó bá wu Ọlọrun láti ṣàánú, a ṣàánú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì wù ú láti dí lọ́kàn, a dí i lọ́kàn.
Ibinu Ọlọrun ati Àánú Rẹ̀
19Wàyí, ẹnìkan lè sọ fún mi pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí Ọlọrun fi ń bá eniyan wí? Ta ni ó tó takò ó pé kí ó má ṣe ohun tí ó bá wù ú?” 20Ṣugbọn ta ni ọ́, ìwọ ọmọ-eniyan, tí o fi ń gbó Ọlọrun lẹ́nu? Ǹjẹ́ ìkòkò lè wí fún ẹni tí ó ń mọ ọ́n pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí?”#Ais 29:16; 45:9; Ọgb 12:12 21Àbí amọ̀kòkò kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe amọ̀ rẹ̀ bí ó ti wù ú bí? Bí ó bá fẹ́, ó lè fi amọ̀ rẹ̀ mọ ìkòkò tí ó wà fún èèlò ọ̀ṣọ́. Bí ó bá sì tún fẹ́, ó lè mú lára amọ̀ kan náà kí ó fi mọ ìkòkò mìíràn fún èèlò lásán.#Ọgb 15:7; Sir 33:13
22Bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tí Ọlọrun ṣe rí. Ó wù ú láti fi ibinu ati agbára rẹ̀ hàn. Ó wá fi ọ̀pọ̀ sùúrù fara da àwọn tí ó yẹ kí ó fi ibinu parun.#Ọgb 12:20-21 23Báyìí náà ni ó fi ògo ńlá rẹ̀ hàn pẹlu fún àwọn tí ó ṣàánú fún, àní fún àwa tí ó ti pèsè ọlá sílẹ̀ fún. 24Àwa náà ni ó pè láti ààrin àwọn Juu ati láti ààrin àwọn tí kìí ṣe Juu pẹlu; 25bí ó ti sọ ninu Ìwé Hosia pé,#Hos 2:23
“Èmi yóo pe àwọn tí kì í ṣe eniyan mi ní ‘Eniyan mi.’
N óo sì pe àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò náání ní ‘Àyànfẹ́ mi.’
26Ní ibìkan náà tí a ti sọ fún wọn rí pé,#Hos 1:10
‘Ẹ kì í ṣe eniyan mi mọ́’
ni a óo ti pè wọ́n ní
ọmọ Ọlọrun alààyè.”
27Aisaya náà kéde nípa Israẹli pé, “Bí àwọn ọmọ Israẹli tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn òkun, sibẹ díẹ̀ péré ni a óo gbà là.#Ais 10:22-23 28Nítorí ṣókí ati wéré wéré ni ìdájọ́ Ọlọrun yóo jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” 29Ṣiwaju eléyìí, Aisaya sọ bákan náà pé, “Bíkòṣe pé Oluwa alágbára jùlọ dá díẹ̀ sí ninu àwọn ọmọ wa ni, bíi Sodomu ni à bá rí, à bá sì dàbí Gomora.”#Ais 1:9
Ìyìn Rere náà Wà fún Israẹli Pẹlu
30Kí ni èyí já sí? Ó já sí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bìkítà rárá láti wá ojurere Ọlọrun, àwọn náà gan-an ni Ọlọrun wá dá láre, ó dá wọn láre nítorí wọ́n gbàgbọ́; 31ṣugbọn Israẹli tí ó ń lépa òfin tí yóo mú wọn rí ìdáláre gbà níwájú Ọlọrun kò rí irú òfin bẹ́ẹ̀. 32Nítorí kí ni wọn kò ṣe rí òfin náà? Ìdí ni pé, wọn kò wá ìdáláre níwájú Ọlọrun nípa igbagbọ, ṣugbọn wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọ́n bá kọsẹ̀ lórí òkúta ìkọsẹ̀, 33bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,#Ais 28:16
“Mo gbé òkúta kan kalẹ̀ ní Sioni
tí yóo mú eniyan kọsẹ̀,
tí yóo gbé eniyan ṣubú.
Ṣugbọn ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.”
Currently Selected:
ROMU 9: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010