YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 69

69
Igbe fún Ìrànlọ́wọ́
1Gbà mí, Ọlọrun,
nítorí omi ti mù mí dé ọrùn.
2Mo ti rì sinu irà jíjìn,
níbi tí kò ti sí ohun ìfẹsẹ̀tẹ̀;
mo ti bọ́ sinu ibú,
omi sì ti bò mí mọ́lẹ̀.
3Mo sọkún títí àárẹ̀ mú mi,
ọ̀nà ọ̀fun mi gbẹ,
ojú mi sì di bàìbàì,
níbi tí mo ti dúró, tí mò ń wo ojú ìwọ Ọlọrun mi.
4Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí pọ̀,
wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ.
Àwọn tí ó fẹ́ pa mí run lágbára.
Àwọn ọ̀tá mi ń parọ́ mọ́ mi,
àwọn nǹkan tí n kò jí
ni wọ́n ní kí n fi dandan dá pada.
5Ọlọrun, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi,
àwọn àṣìṣe mi kò sì fara pamọ́ fún ọ.
6Má tìtorí tèmi dójúti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ,
OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,
má sì tìtorí mi sọ àwọn tí ń wá ọ di ẹni àbùkù,
Ọlọrun Israẹli.
7Nítorí tìrẹ ni mo ṣe di ẹni ẹ̀gàn,
tí ìtìjú sì bò mí.
8Mo ti di àlejò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi,
mo sì di àjèjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá mi.#O. Daf 35:19; Joh 15:25
9Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún,
ìwọ̀sí àwọn tí ó ń pẹ̀gàn rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.
10Nígbà tí mo fi omijé gbààwẹ̀,
ó di ẹ̀gàn fún mi.
11Nígbà tí mò ń wọ aṣọ ọ̀fọ̀,
mo di ẹni àmúpòwe.
12Èmi ni àwọn tí ń jókòó lẹ́nu ibodè
fi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ;
àwọn ọ̀mùtí sì ń fi mí ṣe orin kọ.#(a) Joh 2:17 (b) Rom 15:3
13Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura sí
ní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun,
ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn.
14Yọ mí ninu irà yìí, má jẹ́ kí n rì,
gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
15Má jẹ́ kí ìgbì omi bò mí mọ́lẹ̀,
kí ibú omi má gbé mi mì,
kí isà òkú má sì padé mọ́ mi.
16Dá mi lóhùn, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ
tí kì í yẹ̀ dára;
fojú rere wò mí, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ àánú rẹ.
17Má ṣe fi ojú pamọ́ fún èmi, iranṣẹ rẹ,
nítorí tí mo wà ninu ìdààmú,
yára dá mi lóhùn.
18Sún mọ́ mi, rà mí pada,
kí o sì tú mi sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀tá mi!
19O mọ ẹ̀gàn mi,
o mọ ìtìjú ati àbùkù mi;
o sì mọ gbogbo àwọn ọ̀tá mi.
20Ẹ̀gàn ti mú kí inú mi bàjẹ́,
tóbẹ́ẹ̀ tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì
mò ń retí àánú ṣugbọn kò sí;
mò ń retí olùtùnú, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan.
21Iwọ ni wọ́n sọ di oúnjẹ fún mi,
nígbà tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí,
ọtí kíkan ni wọ́n fún mi mu.#Mat 27:48; Mak 15:36; Luk 23:26; Joh 19:28-29
22Jẹ́ kí tabili oúnjẹ tí wọ́n tẹ́ fún ara
wọn di ẹ̀bìtì fún wọn;
kí àsè ẹbọ wọn sì di tàkúté.
23Jẹ́ kí ojú wọn ṣú,
kí wọn má lè ríran;
kí gbogbo ara wọn sì máa gbọ̀n rìrì.
24Rọ òjò ibinu rẹ lé wọn lórí,
kí o sì jẹ́ kí wọ́n rí gbígbóná ibinu rẹ.
25Kí ibùdó wọn ó di ahoro,
kí ẹnikẹ́ni má sì gbé inú àgọ́ wọn.
26Nítorí ẹni tí o ti kọlù ni wọ́n tún gbógun tì;
ẹni tí o ti ṣá lọ́gbẹ́ ni wọ́n sì tún ń pọ́n lójú.
27Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;
má sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdáláre lọ́dọ̀ rẹ.
28Pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè;
kí á má sì kọ orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo.#Rom 11:9-10 #A. Apo 1:20 #Eks 32:32; Ifi 3:5; 13:8; 17:8
29Ojú ń pọ́n mi, mo sì ń jẹ̀rora;
Ọlọrun, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè!
30Èmi ó fi orin yin orúkọ Ọlọrun;
n óo fi ọpẹ́ gbé e ga.
31Èyí yóo tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn ju akọ mààlúù lọ,
àní, akọ mààlúù tòun tìwo ati pátákò rẹ̀.
32Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo rí i,
inú wọn yóo dùn;
ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín sọjí.
33Nítorí OLUWA a máa gbọ́ ti àwọn aláìní,
kì í sìí kẹ́gàn àwọn eniyan rẹ̀ tí ó wà ní ìgbèkùn.
34Jẹ́ kí ọ̀run ati ayé kí ó yìn ín,
òkun ati gbogbo ohun tí ó ń rìn káàkiri ninu wọn.
35Nítorí Ọlọrun yóo gba Sioni là;
yóo sì tún àwọn ìlú Juda kọ́;
àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa gbé inú rẹ̀,
yóo sì di tiwọn.
36Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo jogún rẹ̀;
àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ yóo sì máa gbé inú rẹ̀.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 69: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in