ORIN DAFIDI 59
59
Adura Ààbò#1Sam 19:11
1Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Ọlọrun mi;
dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì mí.
2Gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi,
kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn apànìyàn.
3Wò ó bí wọ́n ṣe lúgọ dè mí!
OLUWA, àwọn jàǹdùkú eniyan kó ara wọn jọ
láti pa mí lára, láìṣẹ̀, láìrò.
4Láìjẹ́ pé mo ṣẹ̀, wọ́n ń sáré kiri, wọ́n múra dè mí.
Paradà, wá ràn mí lọ́wọ́, kí o sì rí i fúnra rẹ.
5Ìwọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,
Ọlọrun Israẹli,
jí gìrì, kí o jẹ gbogbo orílẹ̀-èdè níyà;
má da ẹnìkan kan sí ninu àwọn tí ń fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ pète ibi.
6Ní alaalẹ́, wọn á pada wá,
wọn á máa hu bí ajá, wọn a sì máa kiri ìlú.
7Ẹ gbọ́ ohun tí wọn ń sọ jáde lẹ́nu,
ẹ wo ahọ́n wọn bí idà;
wọ́n sì ń wí ninu ara wọn pé, “Ta ni yóo gbọ́ ohun tí à ń sọ?”
8Ṣugbọn ìwọ OLUWA ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín,
o sì ń fi gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe yẹ̀yẹ́.
9Ọlọrun, agbára mi, ojú rẹ ni mò ń wò,
nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi.
10Ọlọrun mi óo wá sọ́dọ̀ mi ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀;
Ọlọrun óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi.
11Má pa wọ́n, kí àwọn eniyan mi má baà gbàgbé;
fi ọwọ́ agbára rẹ mì wọ́n,
ré wọn lulẹ̀, OLUWA, ààbò wa!
12Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn dá,
àní, nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ,
jẹ́ kí ìgbéraga wọn kó bá wọn.
Nítorí èpè tí wọ́n ṣẹ́ ati irọ́ tí wọ́n pa,
13fi ibinu pa wọ́n run.
Pa wọ́n run kí wọn má sí mọ́,
kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé Ọlọrun jọba lórí Jakọbu,
ati títí dé òpin ayé.
14Ní alaalẹ́ wọn á pada wá
wọn á máa hu bí ajá, wọn á sì máa kiri ìlú.
15Wọn á máa fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀, wọn á máa wá oúnjẹ kiri,
bí wọn ò bá sì yó wọn á máa kùn.
16Ṣugbọn èmi ó kọrin ìyìn agbára rẹ;
n óo kọrin sókè lówùúrọ̀, nípa ìfẹ́ rẹ tí
kì í yẹ̀.
Nítorí ìwọ ni o ti jẹ́ odi mi
ìwọ sì ni ààbò mi nígbà ìpọ́njú.
17Ọlọrun, agbára mi, n óo kọ orin ìyìn fún ọ,
nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi,
Ọlọrun tí ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn mí.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 59: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010