ORIN DAFIDI 42
42
Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú
1Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun.
2Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi,
àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè.
Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé?
3Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru,
nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,
“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”
4Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti,
bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde:
bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn,
tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́
lọ sí ilé Ọlọrun;
pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́,
láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.
5Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?
Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?
Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín,
olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.
6Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,
nítorí náà mo ranti rẹ
láti òkè Herimoni,
ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani,
7ìbànújẹ́ ń já lura wọn,
ìdààmú sì ń dà gììrì,
wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun.
8Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn,
ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi,
àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi.
9Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé,
“Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi?
Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri
nítorí ìnilára ọ̀tá?”
10Bí ọgbẹ́ aṣekúpani
ni ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá mi rí lára mi,
nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,
“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”
11Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì?
Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?
Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín,
olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 42: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010