YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 20

20
Adura Ìṣẹ́gun
1OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú,
orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́.
2Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá,
yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
3Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ,
yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ.
4Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ,
yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ.
5Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun,
ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀;
OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ.
6Mo wá mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo ran ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ́wọ́;
OLUWA yóo dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá
yóo sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún un ní ìṣẹ́gun ńlá.
7Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun,
àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin,
ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa.
8Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú,
ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin.
9Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA;
kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 20: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy