YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 148

148
Kí gbogbo ẹ̀dá Yin OLUWA
1Ẹ yin OLUWA!
Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
ẹ yìn ín lókè ọ̀run.
2Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀;
ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀.
3Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá;
ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn.
4Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ;
yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run.
5Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA,
nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn.
6Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ títí laelae;
ó sì pààlà fún wọn tí wọn kò gbọdọ̀ ré kọjá.
7Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé,
ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi;
8iná ati yìnyín, ati ìrì dídì,
ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ.
9Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké,
ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari;
10ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ ati ẹran ọ̀sìn,
ẹ̀yin ẹ̀dá tí ń fàyà fà ati ẹyẹ tí ń fò.
11Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè,
ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé;
12ẹ̀yin ọdọmọkunrin ati ọlọ́mọge,
ẹ̀yin ọmọde ati ẹ̀yin àgbààgbà.
13Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA,
nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù;
ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ.
14Ó ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára,
ó sì fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ ní ìyìn;
ó fún àwọn eniyan Israẹli, tí ó wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ẹ yin OLUWA!

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 148: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in