YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 131

131
Àṣírí ìfọ̀kànbalẹ̀
1OLUWA, n kò ṣe ìgbéraga,
bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè.
N ò dáwọ́ lé nǹkan ńláńlá,
n ò sì dá àrà tí ó jù mí lọ.
2Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi lọ́kàn balẹ̀, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́,
bí ọmọ ọwọ́ tíí dákẹ́ jẹ́ẹ́ láyà ìyá rẹ̀.
Ọkàn mi balẹ̀ bíi ti ọmọ ọwọ́ tó dákẹ́ jẹ́ẹ́.
3Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA,
láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 131: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in