ORIN DAFIDI 104
104
Yíyin Ẹlẹ́dàá
1Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,
OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ,
ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù.
2Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ,
ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ.
3Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi,
tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ,
tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́.
4Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ,
tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ.#Heb 1:7
5Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀,
tí kò sì le yẹ̀ laelae.
6O fi ibú omi bò ó bí aṣọ,
omi sì borí àwọn òkè ńlá.
7Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá,
nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn.
8Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkè
lọ sí inú àfonífojì,
sí ibi tí o yàn fún wọn.
9O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá,
kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.
10Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì;
omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè.
11Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu,
ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ.
12Lẹ́bàá orísun wọnyi
ni àwọn ẹyẹ ń gbé,
wọ́n sì ń kọrin lórí igi.
13Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá.
Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
14Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ,
ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan,
kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀;
15ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn,
ati epo tí ń mú ojú eniyan dán,
ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun.
16Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn,
àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn.
17Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́
wọn sí,
àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi.
18Òkè gíga ni ilé ewúrẹ́ igbó,
abẹ́ àpáta sì ni ibùgbé ehoro.
19O dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò,
oòrùn sì mọ àkókò wíwọ̀ rẹ̀.
20O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́,
gbogbo ẹranko ìgbẹ́ sì
ń jẹ kiri.
21Àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ń bú fún ìjẹ,
wọ́n ń wo ojú Ọlọrun fún oúnjẹ.
22Nígbà tí oòrùn bá là, wọn á wọ́ lọ;
wọn á lọ dùbúlẹ̀ sinu ihò wọn.
23Ọmọ eniyan á sì jáde lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀,
á lọ síbi làálàá rẹ̀ títí di àṣáálẹ́.
24OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!
Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn.
Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ.
25Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀,
ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá,
nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá.
26Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ,
ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun.#Job 41:1; O. Daf 74:14; Ais 27:1
27Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò,
fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò.
28Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ,
nígbà tí o bá la ọwọ́,
wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó.
29Bí o bá fojú pamọ́,
ẹ̀rù á bà wọ́n,
bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú,
wọn á sì pada di erùpẹ̀.
30Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde,
wọ́n di ẹ̀dá alààyè,
o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun.
31Kí ògo OLUWA máa wà títí lae,
kí OLUWA máa yọ̀ ninu iṣẹ́ rẹ̀.
32Ẹni tí ó wo ilẹ̀, tí ilẹ̀ mì tìtì,
tí ó fọwọ́ kan òkè, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ èéfín.
33N óo kọrin ìyìn sí OLUWA
níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.
N óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi,
níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ń bẹ.
34Kí àṣàrò ọkàn mi kí ó dùn mọ́ ọn ninu
nítorí mo láyọ̀ ninu OLUWA.
35Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé,
kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́.
Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi!
Yin OLUWA!
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 104: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010