YouVersion Logo
Search Icon

FILIPI 2

2
Jesu Rẹ Ara Rẹ̀ Sílẹ̀
1Nítorí náà, bí ẹ bá ní ìwúrí kankan ninu Kristi, bí ìfẹ́ rẹ̀ bá fun yín ní ìtùnú, bí ẹ bá ní ìrẹ́pọ̀ ninu Ẹ̀mí, bí ẹ bá ní ojú àánú, 2ẹ mú kí ayọ̀ mi kún nípa pé kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí ẹ fẹ́ nǹkankan náà, kí ẹ ní inú kan, kí èrò yín sì papọ̀. 3Ẹ má ṣe ohunkohun pẹlu ẹ̀mí àṣehàn tabi láti gba ìyìn eniyan, ṣugbọn pẹlu ọkàn ìrẹ̀lẹ̀, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣiwaju ara yín. 4Ẹ má máa mójútó nǹkan ti ara yín nìkan, ṣugbọn ẹ máa mójútó nǹkan àwọn ẹlòmíràn náà. 5Ẹ máa ní èrò yìí ninu ara yín, irú èyí tí ó wà ninu Kristi Jesu, 6ẹni tí ó wá ní àwòrán Ọlọrun, sibẹ kò ka ipò jíjẹ́ ọ̀kan pẹlu Ọlọrun sí ohun tí ìbá gbé léjú. 7Ṣugbọn ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó gbé àwòrán ẹrú wọ̀, ó wá farahàn ní àwọ̀ eniyan.
8Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu títí dé ojú ikú, àní ikú lórí agbelebu.
9Nítorí náà ni Ọlọrun ṣe gbé e ga ju ẹnikẹ́ni lọ; ó sì fún un ní orúkọ tí ó ga ju gbogbo orúkọ yòókù lọ, 10pé ní orúkọ Jesu ni gbogbo ẹ̀dá yóo máa wólẹ̀, lọ́run ati láyé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀;#Ais 45:23 11gbogbo ẹ̀dá yóo sì máa jẹ́wọ́ pé, “Jesu Kristi ni Oluwa,” fún ògo Ọlọrun Baba.
Onigbagbọ Jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ ninu Ayé
12Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń gbọ́ràn nígbà gbogbo, tí kì í ṣe nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣugbọn pàápàá jùlọ ní àkókò yìí tí n kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣe iṣẹ́ ìgbàlà yín pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì. 13Nítorí pé Ọlọrun ní ń fun yín ní agbára, láti fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ati láti lè ṣe ohun tí ó wù ú.
14Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú tabi iyàn jíjà, 15kí ẹ lè jẹ́ Ọmọ Ọlọrun, tí kò lẹ́bi tí kò sì ní àléébù, ọmọ Ọlọrun tí ó pé, láàrin àwọn ìran tí ọ̀nà wọn wọ́, tí ìwà wọn sì ti bàjẹ́. Láàrin irú àwọn eniyan wọnyi ni ẹ̀ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ ninu ayé,#Diut 32:5 16tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo.
17Ṣugbọn bí a bá fi mí ṣe ohun ìrúbọ ati ohun èèlò ninu ìsìn nítorí igbagbọ yín, ó dùn mọ́ mi, n óo sì máa yọ̀ pẹlu gbogbo yín. 18Nítorí náà, kí inú yín kí ó máa dùn, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.
Timoti ati Epafiroditu
19Lágbára Oluwa, mò ń gbèrò ati rán Timoti si yín láì pẹ́, kí n lè ní ìwúrí nígbà tí mo bá gbúròó yín. 20N kò ní ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀ tí ọkàn wa rí bákan náà, tí ó sì tún ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe àwọn nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ tiyín. 21Nítorí nǹkan ti ara wọn ni gbogbo àwọn yòókù ń wá, wọn kò wá nǹkan ti Jesu Kristi. 22Ṣugbọn ẹ mọ bí Timoti ti wúlò tó, nítorí bí ọmọ tíí ṣe pẹlu baba rẹ̀ ni ó ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ pẹlu mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere. 23Nítorí náà, òun ni mo lérò pé n óo rán nígbà tí mo bá mọ bí ọ̀rọ̀ mi yóo ti já sí. 24Ṣugbọn mo ní igbẹkẹle ninu Oluwa pé èmi fúnra mi yóo wá láìpẹ́.
25Mo kà á sí pé ó di dandan pé kí n rán Epafiroditu pada si yín. Ó jẹ́ arakunrin mi, alábàáṣiṣẹ́ pẹlu mi, ati ọmọ-ogun pẹlu mi. Ó tún jẹ́ òjíṣẹ́ ati aṣojú yín tí ó ń mójútó àìní mi. 26Nítorí ọkàn gbogbo yín ń fà á, ọkàn rẹ̀ kò sì balẹ̀ nítorí gbígbọ́ tí ẹ ti gbọ́ pé ó ṣàìsàn. 27Òtítọ́ ni, ó ṣàìsàn, ó tilẹ̀ fẹ́rẹ̀ kú! Ṣugbọn Ọlọrun ṣàánú rẹ̀, kì í sìí ṣe òun nìkan ni, Ọlọrun ṣàánú èmi náà, kí n má baà ní ìbànújẹ́ kún ìbànújẹ́. 28Nítorí náà, ní wéréwéré yìí ni mò ń rán an bọ̀ kí ẹ lè tún rí i, kí inú yín lè dùn, kí ọkàn tèmi náà sì lè balẹ̀. 29Kí ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀ ninu Oluwa, kí ẹ máa bu ọlá fún irú àwọn bẹ́ẹ̀. 30Nítorí pé ó fẹ́rẹ̀ kú nítorí iṣẹ́ Kristi. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu, kí ó lè rọ́pò yín ninu ohun tí ó kù tí ó yẹ kí ẹ ṣe gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ fún mi.

Currently Selected:

FILIPI 2: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in