YouVersion Logo
Search Icon

NỌMBA 8

8
Ìgbékalẹ̀ Fìtílà
1OLUWA rán Mose pé 2kí ó sọ fún Aaroni pé, nígbà tí Aaroni bá tan fìtílà mejeeje, kí ó gbé wọn sórí ọ̀pá fìtílà kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju ọ̀pá náà. 3Aaroni gbé àwọn fìtílà náà ka orí ọ̀pá wọn, kí wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ siwaju, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. 4Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni wọ́n fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà, láti ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ títí dé ìtànná orí rẹ̀. Mose ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí OLUWA fi hàn án.#Eks 25:31-40; 37:17-24
Ìwẹ̀nùmọ́ ati Ìyàsímímọ́ Àwọn Ọmọ Lefi
5OLUWA sọ fún Mose pé, 6“Ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́. 7Kí o wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, kí wọ́n fi abẹ fá gbogbo irun ara wọn, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì di mímọ́. 8Kí wọ́n mú akọ mààlúù kékeré kan ati ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ wá. Kí wọ́n sì mú akọ mààlúù kékeré mìíràn wá, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. 9Lẹ́yìn náà, pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí àwọn ọmọ Lefi sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. 10Kó àwọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, kí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì gbé ọwọ́ lé wọn lórí, 11kí Aaroni alufaa wá ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn OLÚWA. 12Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Lefi yóo gbé ọwọ́ wọn lé àwọn akọ mààlúù náà lórí. O óo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, o óo sì fi ikeji rú ẹbọ sísun sí OLÚWA, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi.
13“Ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli; wọn óo sì máa ṣe iranṣẹ fún Aaroni alufaa ati àwọn ọmọ rẹ̀. 14Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, wọn óo sì jẹ́ tèmi. 15Lẹ́yìn tí o bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́, tí o sì ti yà wọ́n sọ́tọ̀ bí ẹbọ fífì sí OLUWA, ni àwọn ọmọ Lefi tó lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. 16Mo ti gbà wọ́n dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì di tèmi patapata. 17Nígbà tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní Ijipti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ láti jẹ́ tèmi.#Eks 13:2 18Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli. 19Mo ti fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti inú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ ati láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn nígbà tí wọn bá súnmọ́ ibi mímọ́.”
20Mose ati Aaroni ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí wọ́n ṣe. 21Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì fún OLUWA, ó sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́. 22Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ Lefi bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ, wọ́n ń ṣe iranṣẹ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí àwọn ọmọ Israẹli ṣe fun àwọn ọmọ Lefi, ni wọ́n ṣe.
23OLUWA sọ fún Mose pé, 24“Àwọn ọmọ Lefi yóo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn wọn ninu Àgọ́ Àjọ láti ìgbà tí wọ́n bá ti di ẹni ọdún mẹẹdọgbọn. 25Nígbà tí wọ́n bá di ẹni aadọta ọdún, iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Àjọ yóo dópin. Wọn kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ níbẹ̀ mọ́, 26ṣugbọn wọ́n lè máa ran àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́ nípa bíbojú tó wọn; ṣugbọn àwọn gan-an kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe yan iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Lefi fún wọn.”

Currently Selected:

NỌMBA 8: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in