NEHEMAYA 9
9
Àwọn Eniyan náà Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn
1Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kan náà, àwọn ọmọ Israẹli péjọ pọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì ku eruku sí orí wọn. 2Wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn àlejò, wọ́n dìde dúró, wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ati gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn. 3Wọ́n dúró ní ààyè wọn, wọ́n sì ka ìwé òfin OLUWA Ọlọrun wọn fún bíi wakati mẹta lọ́jọ́ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún nǹkan bíi wakati mẹta, wọ́n sì sin OLUWA Ọlọrun wọn.
4Jeṣua, Bani, ati Kadimieli, Ṣebanaya, Bunni, Ṣerebaya, Bani, ati Kenani dúró lórí pèpéle àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì gbadura sókè sí OLUWA Ọlọrun wọn.
5Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Kadimieli, Bani, Haṣabineya, Ṣerebaya, Hodaya, Ṣebanaya ati Petahaya, pè wọ́n pé, “Ẹ dìde dúró kí ẹ sì yin OLUWA Ọlọrun yín lae ati laelae. Ìyìn ni fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo, tí ó ga ju gbogbo ibukun ati ìyìn lọ.”
Adura Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀
6Ẹsira ní: “Ìwọ nìkan ni OLUWA, ìwọ ni o dá ọ̀run, àní, ọ̀run tí ó ga jùlọ, ati gbogbo àwọn ìràwọ̀ tí ó wà lójú ọ̀run, ìwọ ni o dá ilé ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, ati àwọn òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn. Ìwọ ni o mú kí gbogbo wọn wà láàyè, ìwọ sì ni àwọn ogun ọ̀run ń sìn. 7Ìwọ ni OLUWA, Ọlọrun, tí ó yan Abramu, tí o mú un jáde wá láti ìlú Uri tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea, tí o sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Abrahamu. 8O rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí ọ, O sì bá a dá majẹmu láti fún àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Amori, ti àwọn ará Perisi, ti àwọn ará Jebusi ati ti àwọn ará Girigaṣi, o sì ti mú ìlérí náà ṣẹ nítorí pé olódodo ni ọ́. #(a) Jẹn 11:31; 12:1 (b) Jẹn 17:5 #Jẹn 15:18-21
9“O ti rí ìpọ́njú àwọn baba wa ní ilẹ̀ Ijipti o sì gbọ́ igbe wọn ní etí Òkun Pupa, 10o sì ṣe iṣẹ́ àmì ati ìyanu, o fi jẹ Farao níyà ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà, nítorí pé wọ́n hùwà ìgbéraga sí àwọn baba wa, o gbé orúkọ ara rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ó ti wà lónìí. 11O pín òkun sí meji níwájú wọn, kí wọ́n lè gba ààrin rẹ̀ kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, o sì sọ àwọn tí wọn ń lé wọn lọ sinu ibú bí ẹni sọ òkúta sinu omi. 12Ò ń fi ọ̀wọ̀n ìkùukùu darí wọn lọ́sàn-án, o sì ń fi ọ̀wọ̀n iná darí wọn lóru, ò ń tọ́ wọn sí ọ̀nà tí ó yẹ kí wọ́n rìn. 13O sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai, o bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, o sì fún wọn ní ìlànà ati ìdájọ́ tí ó tọ̀nà ati àwọn òfin tòótọ́, 14O kọ́ wọn láti máa pa ọjọ́ ìsinmi rẹ mọ́, o sì tún pèsè ẹ̀kọ́, ìlànà, ati òfin fún wọn láti ọwọ́ Mose iranṣẹ rẹ. 15O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n, o sì ń fún wọn ní omi mu láti inú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n. O ní kí wọ́n lọ gba ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí láti fún wọn bí ohun ìní wọn. #(a) Eks 3:7 (b) Eks 14:10-12 #Eks 7:8-12:32 #(a) Eks 14:21-29 (b) Eks 15:4-5 #Eks 13:12-22 #Eks 19:18–23:33 #(a) Eks 16:4-15 (b) Eks 17:1-7 (d) Diut 1:21
16“Àwọn ati àwọn baba wa hùwà ìgbéraga, wọn ṣe orí kunkun, wọn kò sì pa òfin náà mọ́. 17Wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì ranti àwọn ohun ìyanu tí o ṣe láàrin wọn, ṣugbọn wọ́n ṣoríkunkun, wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pada sinu ìgbèkùn wọn ní Ijipti. Ṣugbọn Ọlọrun tíí dáríjì ni ni Ọ́, olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú sì ni ọ́, o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kìí yẹ̀, nítorí náà o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. 18Nígbà tí wọ́n tilẹ̀ yá ère ọmọ mààlúù, tí wọn ń sọ pé, ‘Ọlọrun wọn tí ó kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni,’ tí wọ́n sì ń hu ìwà ìmúnibínú, 19nítorí àánú rẹ, o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó ń tọ́ wọn sọ́nà kò fìgbà kan kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀n iná kò sì fi wọ́n sílẹ̀ lóru. Ó ń tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lálẹ́, láti máa tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa rìn. 20O fún wọn ní ẹ̀mí rere rẹ láti máa kọ́ wọn, o kò dá mana rẹ dúró, o fi ń bọ́ wọn. O sì ń fún wọn ni omi mu nígbà tí òùngbẹ bá ń gbẹ wọ́n. 21Ogoji ọdún ni o fi bọ́ wọn ninu aṣálẹ̀, wọn kò sì ṣe àìní ohunkohun, aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ̀ wọn kò sì wú. 22O gba ọpọlọpọ ìjọba ati ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fún wọn, o sì fi ibi gbogbo fún wọn. Wọ́n gba ilẹ̀ ìní Sihoni, ọba Heṣiboni, ati ti Ogu, ọba Baṣani. 23O jẹ́ kí ìrandíran wọn pọ̀ sí i bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, o sì kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wọn pé wọn yóo lọ gbà. 24Àwọn ọmọ wọn lọ sí ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á, o ṣẹgun àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀, o sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, àtàwọn, àtọba wọn, àtilẹ̀ wọn, kí àwọn ọmọ Israẹli lè ṣe wọ́n bí wọ́n bá ti fẹ́. 25Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo àwọn ìlú olódi ati ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, wọ́n sì gba ilé tí ó kún fún ọpọlọpọ àwọn nǹkan dáradára, ati kànga, ọgbà àjàrà, igi olifi ati ọpọlọpọ igi eléso, nítorí náà wọ́n jẹ wọ́n yó, wọ́n sanra, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn ninu oore ńlá rẹ. #Nọm 14:1-4; Diut 1:26-33 #Eks 34:6; Nọm 14:18 #Eks 32:1-4 #Diut 8:2-4 #Nọm 21:21-35 #(a) Jẹn 15:5; 22:17 (b) Joṣ 3:14-17 #Joṣ 11:23 #Diut 6:10-11
26“Ṣugbọn, wọ́n ṣe àìgbọràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Wọ́n pa àwọn òfin rẹ tì sí apákan, wọ́n pa àwọn wolii rẹ tí wọ́n ti ń kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n yipada sí ọ, wọ́n sì ń hùwà àbùkù sí ọ. 27Nítorí náà, o fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá sì jẹ wọ́n níyà, nígbà tí ìyà ń jẹ wọ́n, wọ́n ké pè ọ́, o sì gbọ́ igbe wọn lọ́run, gẹ́gẹ́ bí àánú rẹ ńlá, o gbé àwọn kan dìde bíi olùgbàlà láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. 28Ṣugbọn lẹ́yìn tí wọ́n ti ní ìsinmi tán, wọ́n tún ṣe nǹkan burúkú níwájú rẹ, o sì tún fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn. Sibẹsibẹ, nígbà tí wọ́n ronupiwada tí wọ́n sì gbadura sí ọ, o gbọ́ lọ́run, lọpọlọpọ ìgbà ni o sì gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ. 29Ò sì máa kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n lè yipada sí òfin rẹ. Sibẹ wọn a máa hùwà ìgbéraga, wọn kìí sìí pa òfin rẹ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ wọn a máa ṣẹ̀ sí òfin rẹ, tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá pamọ́, ẹni náà yóo yè. Ṣugbọn wọn ń dágunlá, wọ́n ń ṣe orí kunkun, wọn kò sì gbọ́ràn. 30Ọpọlọpọ ọdún ni o fi mú sùúrù pẹlu wọ́n, tí o sì ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ, láti ẹnu àwọn wolii rẹ, sibẹ wọn kò fetí sílẹ̀. Nítorí náà ni o ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ṣẹgun wọn. 31Ṣugbọn nítorí àánú rẹ ńlá, o kò jẹ́ kí wọ́n parun patapata, bẹ́ẹ̀ ni o kò pa wọ́n tì, nítorí pé Ọlọrun olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni ọ́. #Ọgb 2:10-20 #A. Ada 2:11-16 #Lef 18:5 #2A. Ọba 17:13-18, 2Kron 36:15-16
32“Nítorí náà, nisinsinyii Ọlọrun wa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, Ọlọrun tí ó bani lẹ́rù, Ọlọrun tí máa ń mú ìlérí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣẹ, má fi ojú kékeré wo gbogbo ìnira tí ó dé bá wa yìí, ati èyí tí ó dé bá àwọn ọba wa, ati àwọn olórí wa, àwọn alufaa wa, ati àwọn wolii wa, àwọn baba wa, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ, láti ìgbà àwọn ọba Asiria títí di ìsinsìnyìí. 33Sibẹ, o jàre gbogbo ohun tí ó dé bá wa yìí, nítorí pé o ṣe olóòótọ́ sí wa, àwa ni a hùwà burúkú sí ọ. 34Àwọn ọba wa, ati àwọn ìjòyè wa, àwọn alufaa wa ati àwọn baba wa kọ̀, wọn kò pa òfin rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ, wọn kò sì gbọ́ ìkìlọ̀ rẹ. Pẹlu, bí àwọn nǹkan rere tí o fún wọn ti pọ̀ tó, lórí ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì dára tí o fún wọn. 35Wọn kò sìn ọ́ ní agbègbè ìjọba wọn, ati ninu oore nla rẹ tí o fun wọn, àní ninu ilẹ̀ ẹlẹ́tù lójú nla tí o bùn wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú wọn. 36Wò ó ẹrú ni wá lónìí lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa pé kí wọ́n máa gbádùn àwọn èso inú rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára ibẹ̀. Wò ó, a ti di ẹrú lórí ilẹ̀ náà. 37Àwọn ọrọ̀ inú rẹ̀ sì di ti àwọn ọba tí wọn ń mú wa sìn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, wọ́n ń lo agbára lórí wa ati lórí àwọn mààlúù wa bí ó ṣe wù wọ́n, a sì wà ninu ìpọ́njú ńlá.” #2A. Ọba 15:19,29; 17:3-6; Ẹsr 4:12,10
Àwọn Eniyan náà Fi Ọwọ́ sí Ìwé Àdéhùn
38Nítorí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọnyi, a dá majẹmu, a sì kọ ọ́ sílẹ̀, àwọn ìjòyè wa, ati àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa fi ọwọ́ sí i, wọ́n sì fi èdìdì dì í.
Currently Selected:
NEHEMAYA 9: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010