YouVersion Logo
Search Icon

NEHEMAYA 7

7
1Lẹ́yìn tí a ti mọ odi náà tán, tí mo ti ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, tí mo sì ti yan àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, ati àwọn akọrin ati àwọn ọmọ Lefi, 2mo yan arakunrin mi, Hanani, ati Hananaya, gomina ilé ìṣọ́, láti máa ṣe àkóso Jerusalẹmu, nítorí pé Hananaya jẹ́ olóòótọ́ ó sì bẹ̀rù Ọlọrun ju ọpọlọpọ àwọn yòókù lọ. 3Mo sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ ṣí ẹnu ibodè Jerusalẹmu títí tí oòrùn yóo fi máa ta ni lára, kí wọ́n sì máa ti ibodè náà, kí wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú sí i lẹ́yìn kí àwọn olùṣọ́ tó kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Kí wọ́n yan àwọn olùṣọ́ láàrin àwọn ọmọ Jerusalẹmu, kí olukuluku ní ibùdó tirẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ibi tí ó bá kọjú sí ilé wọn.
Orúkọ Àwọn tí Wọ́n Pada láti Oko Ẹrú
(Ẹsr 2:1-70)
4Ìlú náà fẹ̀, ó sì tóbi, ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ kéré níye, kò sì tíì sí ilé níbẹ̀. 5Nígbà náà ni Ọlọrun fi sí mi lọ́kàn láti ranṣẹ pe àwọn ọlọ́lá jọ, ati àwọn olórí, ati àwọn eniyan yòókù, láti wá ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé tí wọ́n kọ orúkọ àwọn ìdílé tí wọ́n kọ́kọ́ wá sí, mo sì rí ohun tí wọ́n kọ sinu wọn pé:
6Orúkọ àwọn eniyan agbègbè náà, tí wọ́n pada ninu àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati Juda, tí olukuluku wọn sì pada sí ìlú rẹ̀ nìwọ̀nyí. 7Wọ́n jọ dé pẹlu Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Asaraya, Raamaya, Nahamani, Modekai, Biliṣani, Misipereti, Bigifai, Nehumi, ati Baana.
Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli nìyí:
8Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa, ó lé mejilelaadọsan-an (2,172). 9Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọrinlelọọdunrun ó dín mẹjọ (372). 10Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652). 11Àwọn ọmọ Pahati Moabu, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Jeṣua ati Joabu, jẹ́ ẹgbẹrinla ó lé mejidinlogun (2,818). 12Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254). 13Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ojilelẹgbẹrin ó lé marun-un (845). 14Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ojidinlẹgbẹrin (760). 15Àwọn ọmọ Binui jẹ́ ojilelẹgbẹta ó lé mẹjọ (648). 16Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbẹta lé mejidinlọgbọn (628). 17Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbaa ó lé ọọdunrun ati mejilelogun (2,322). 18Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ọtalelẹgbẹta ati meje (667). 19Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹtadinlaadọrin (2,067). 20Àwọn ọmọ Adini jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín marun-un (655). 21Àwọn ọmọ Ateri tí wọn ń jẹ́ Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un. 22Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ ọọdunrun ó lé mejidinlọgbọn (328). 23Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹrinlelogun (324). 24Àwọn ọmọ Harifi jẹ́ aadọfa ó lé meji (112). 25Àwọn ọmọ Gibeoni jẹ́ marundinlọgọrun-un. 26Àwọn ará Bẹtilẹhẹmu ati Netofa jẹ́ ọgọsan-an ó lé mẹjọ (188). 27Àwọn ará Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128). 28Àwọn ará Beti Asimafeti jẹ́ mejilelogoji. 29Àwọn ará Kiriati Jearimu ati Kefira ati Beeroti jẹ́ ọtadinlẹgbẹrin ó lé mẹta (743). 30Àwọn ará Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta lé mọkanlelogun (621). 31Àwọn ará Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122). 32Àwọn ará Bẹtẹli ati Ai jẹ́ mẹtalelọgọfa (123). 33Àwọn ará Nebo keji jẹ́ mejilelaadọta. 34Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254). 35Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320). 36Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345). 37Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mọkanlelogun (721). 38Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ ẹgbaaji ó dín aadọrin (3,930).
39Àwọn alufaa nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jedaaya, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Jeṣua, jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973). 40Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052). 41Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247). 42Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017).
43Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jeṣua, tí wọn ń jẹ́ Kadimieli, ní ìdílé Hodefa, jẹ́ mẹrinlelaadọrin. 44Àwọn akọrin nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ mejidinlaadọjọ (148). 45Àwọn olùṣọ́ ẹnubodè nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Ṣalumu, àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni, àwọn ọmọ Akubu, àwọn ọmọ Hatita, ati àwọn ọmọ Ṣobai. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogoje (138).
46Àwọn iranṣẹ tẹmpili nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa, ati àwọn ọmọ Tabaoti, 47àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Sia, ati àwọn ọmọ Padoni, 48àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba, ati àwọn ọmọ Ṣalimai, 49àwọn ọmọ Hanani, àwọn ọmọ Gideli, ati àwọn ọmọ Gahari, 50àwọn ọmọ Reaaya, àwọn ọmọ Resini, ati àwọn ọmọ Nekoda, 51àwọn ọmọ Gasamu, àwọn ọmọ Usa, ati àwọn ọmọ Pasea, 52àwọn ọmọ Besai, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefuṣesimu, 53àwọn ọmọ Bakibuki, àwọn ọmọ Hakufa, ati àwọn ọmọ Harihuri, 54àwọn ọmọ Basiluti, àwọn ọmọ Mehida, ati àwọn ọmọ Hariṣa, 55àwọn ọmọ Barikosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema, 56àwọn ọmọ Nesaya, ati àwọn ọmọ Hatifa.
57Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Sofereti, ati àwọn ọmọ Perida, 58àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli, 59àwọn ọmọ Ṣefataya, àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu, ati àwọn ọmọ Amoni.
60Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ ninu tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392).
61Àwọn tí wọ́n wá láti Teli Mela, ati láti Teli Hariṣa, Kerubu, Adoni, ati Imeri, ṣugbọn tí wọn kò mọ ilé baba wọn tabi ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀, tí kò sì sí ẹ̀rí tí ó dájú, bóyá ọmọ Israẹli ni wọ́n tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: 62àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Wọ́n jẹ́ ojilelẹgbẹta ó lé meji (642).
63Bákan náà ni àwọn ọmọ alufaa wọnyi: àwọn ọmọ Hobaaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí wọ́n fẹ́ iyawo lára àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi, ṣugbọn tí wọn tún ń jẹ́ orúkọ àwọn àna wọn.) 64Nígbà tí wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí wọn kò rí i, wọ́n yọ wọ́n kúrò lára àwọn alufaa, wọ́n sì kà wọ́n sí aláìmọ́. 65Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fẹnu kan oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu yóo fi dé.#Eks 28:30; Diut 33:8
66Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa ó lé ojidinnirinwo (42,360), 67yàtọ̀ sí àwọn iranṣẹkunrin wọn ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin lé ọọdunrun ati mẹtadinlogoji (7,337), wọ́n sì ní àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245) lọkunrin ati lobinrin. Àwọn ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736), 68àwọn ìbaaka wọn jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245), 69àwọn ràkúnmí wọn jẹ́ ojilenirinwo ó dín marun-un (435), àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sì jẹ́ ẹgbaata ó lé ọrindinlẹgbẹrin (6,720).
70Àwọn olórí ní ìdílé kọ̀ọ̀kan kópa ninu iṣẹ́ náà. Gomina fi ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati aadọta àwo kòtò, ati ẹẹdẹgbẹta ó lé ọgbọ̀n (530) ẹ̀wù alufaa sí i. 71Àwọn kan ninu àwọn baálé baálé fi ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati ẹgbọkanla (2,200) òṣùnwọ̀n mina fadaka. 72Ohun tí àwọn eniyan yòókù fi sílẹ̀ ni ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n diramu wúrà ati ẹgbaa (2,000) ìwọ̀n mina fadaka ati aṣọ àwọn alufaa mẹtadinlaadọrin.
73Bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ìlú Juda, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn aṣọ́bodè, ati àwọn akọrin, ati díẹ̀ lára àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kaluku ń gbé ìlú rẹ̀.#1Kron 9:2; Neh 11:3
Nígbà tí yóo fi di oṣù keje, àwọn ọmọ Israẹli ti wà ní àwọn ìlú wọn.

Currently Selected:

NEHEMAYA 7: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in