YouVersion Logo
Search Icon

MAKU 9

9
1Ó tún wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, àwọn kan wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun tí yóo dé pẹlu agbára.”
Jesu Para Dà lórí Òkè
(Mat 17:1-13; Luk 9:28-36)
2Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu lọ sí orí òkè gíga kan, àwọn mẹta yìí nìkan ni ó mú lọ. Ìrísí rẹ̀ bá yipada lójú wọn. 3Ẹ̀wù rẹ̀ ń dán, ó funfun láúláú, kò sí alágbàfọ̀ kan ní ayé tí ó lè fọ aṣọ kí ó funfun tóbẹ́ẹ̀. 4Wọ́n rí Elija pẹlu Mose tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀. 5Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, ó dára tí a wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pàgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.” 6Ẹ̀rù tí ó bà wọ́n pupọ kò jẹ́ kí ó mọ ohun tí ì bá wí.
7Ìkùukùu kan bá ṣíji bò wọ́n, ohùn kan bá wá láti inú ìkùukùu náà tí ó wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”#2 Pet 1:17-18 #Mat 3:17; Mak 1:11; Luk 3:22 8Lójijì, bí wọ́n ti wò yíká, wọn kò rí ẹnìkankan lọ́dọ̀ wọn mọ́, àfi Jesu nìkan.
9Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, Jesu pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ròyìn ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí òun, Ọmọ-Eniyan, yóo fi jí dìde kúrò ninu òkú.
10Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn nípa ìtumọ̀ jíjí dìde kúrò ninu òkú. 11Wọ́n bá bi í léèrè pé, “Kí ló dé tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́ dé?”#Mal 4:5; Mat 11:14
12Ó dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Elija ni ó níláti kọ́ dé láti mú ohun gbogbo bọ̀ sípò.” Ó wá bi wọ́n pé, “Báwo ni a ti ṣe kọ nípa Ọmọ-Eniyan pé ó níláti jìyà pupọ, kí a sì fi àbùkù kàn án?”#Sir 48:10 13Ó sì tún wí fún wọn pé, “Elija ti dé, wọ́n ti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ nípa rẹ̀.”
Jesu Wo Ọmọ Tí Ó Ní Ẹ̀mí Èṣù Sàn
(Mat 17:14-21; Luk 9:37-43a)
14Nígbà tí Jesu dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí ọpọlọpọ eniyan pẹlu àwọn amòfin, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn. 15Lẹsẹkẹsẹ bí gbogbo àwọn eniyan ti rí i, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá sáré lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i. 16Ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀yin ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ń jiyàn lé lórí?”
17Ẹnìkan ninu wọn bá dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, ọmọ mi tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di odi ni mo mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ. 18Níbikíbi tí ó bá ti dé sí i, ẹ̀mí èṣù yìí á gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà yóo máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, yóo wa eyín pọ̀, ara rẹ̀ yóo wá le gbandi. Mo sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọn lé ẹ̀mí náà jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.”
19Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó? N óo ti fara dà á fun yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá.” 20Wọ́n bá mú un lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Nígbà tí ẹ̀mí burúkú yìí rí Jesu, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yí nílẹ̀, ó ń yọ ìfòòfó lẹ́nu. 21Jesu wá bi baba ọmọ náà pé, “Ó ti tó ìgbà wo tí irú èyí ti ń ṣe é?”
Baba rẹ̀ dáhùn pé, “Láti kékeré ni.” 22Ó ní, “Nígbà pupọ ẹ̀mí náà á gbé e sọ sinu iná tabi sinu omi, kí ó lè pa á. Ṣugbọn bí ìwọ bá lè ṣe ohunkohun, ṣàánú wa kí o ràn wá lọ́wọ́.”
23Jesu wí fún un pé, “Ọ̀ràn bí èmi bá lè ṣe é kọ́ yìí, ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.”
24Lẹ́sẹ̀ kan náà baba ọmọ náà kígbe pé, “Mo gbàgbọ́; ràn mí lọ́wọ́ níbi tí igbagbọ mi kù kí ó tó.”
25Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ìjọ eniyan ń sáré bọ̀, ó bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó ní, “Ìwọ ẹ̀mí tí o jẹ́ kí ọmọ yìí ya odi, tí o sì di í létí, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò ninu rẹ̀, kí o má tún wọ inú rẹ̀ mọ́.”
26Ẹ̀mí náà bá kígbe, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó sì jáde. Ọmọ náà wá dàbí ẹni tí ó kú, tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan náà ń sọ pé ó ti kú. 27Ṣugbọn Jesu fà á lọ́wọ́, ó gbé e dìde, ọmọ náà bá nàró.
28Nígbà tí Jesu wọ inú ilé, tí ó ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí náà jáde?”
29Ó dá wọn lóhùn pé, “Irú èyí kò ṣe é lé jáde, àfi pẹlu adura [ati ààwẹ̀.”]
Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀
(Mat 17:22-23; Luk 9:43b-45)
30Láti ibẹ̀ wọ́n jáde lọ, wọ́n ń la Galili kọjá. Jesu kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, 31nítorí ó ń kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń wí fún wọn pé, “A óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́, wọn yóo pa á, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá ti pa á tán, yóo jí dìde lẹ́yìn ọjọ́ mẹta.”
32Ṣugbọn ohun tí ó ń wí kò yé wọn, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
Ta Ni Ẹni Ńlá Jùlọ?
(Mat 18:1-5; Luk 9:46-48)
33Nígbà tí wọ́n dé Kapanaumu, tí wọ́n wọ inú ilé, ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ lọ́nà?”
34Wọ́n bá dákẹ́ nítorí ní ọ̀nà, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn lórí ta ni ó ṣe pataki jùlọ.#Luk 22:24 35Lẹ́yìn tí ó ti jókòó, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ọ̀gá, ó níláti ṣe iranṣẹ fún gbogbo eniyan.”#Mat 20:26-27; 23:11; Mak 10:43-44; Luk 22:26 36Ó bá fa ọmọde kan dìde ní ààrin wọn, ó gbé e sí ọwọ́ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, 37“Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀kan ninu àwọn ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, kì í ṣe èmi ni ó gbà, ṣugbọn ó gba ẹni tí ó rán mi wá sí ayé.”#Mat 10:40; Luk 10:16; Joh 13:20
Ẹni Tí Kò Lòdì sí Wa, Tiwa ni
(Luk 9:49-50)
38Johanu wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a rí ẹnìkan tí ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ṣugbọn a gbìyànjú láti dá a lẹ́kun, nítorí kì í ṣe ara wa.”
39Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Ẹ má ṣe dá a lẹ́kun, nítorí kò sí ẹni tí yóo fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóo yára sọ ọ̀rọ̀ ibi nípa mi. 40Nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí wa, tiwa ni.#Mat 12:30; Luk 11:23 41Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fun yín ní omi mu nítorí tèmi, nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo rí èrè rẹ̀ gbà.#Mat 10:42.
Ẹ̀tàn Sí Ẹ̀ṣẹ̀
(Mat 18:6-9; Luk 17:1-3)
42“Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́ kọsẹ̀, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á gbé e sọ sinu òkun. 43Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àléébù ara, jù pé kí o ní ọwọ́ mejeeji kí o wọ iná àjóòkú,#9:43 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní ẹsẹ 44 tí ó jẹ́ bákan náà pẹlu ẹsẹ 48. [ 44níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.]#Mat 5:30 45Bí ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ kan kí o sì wọ inú ìyè jù pé kí o ní ẹsẹ̀ mejeeji kí á sì sọ ọ́ sinu iná, [ 46níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.] 47Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn fún ọ kí o wọ ìjọba Ọlọrun pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú mejeeji kí a sì sọ ọ́ sinu iná,#Mat 5:29 48níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí iná ibẹ̀ kì í sì í kú.#Ais 66:24
49“Iyọ̀ níí sọ ẹbọ di mímọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó jẹ́ pé iná ni a óo fi sọ gbogbo eniyan di mímọ́.
50“Iyọ̀ dára, ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni yóo ṣe tún lè dùn mọ́?#Mat 5:13; Luk 14:34-35.
“Ẹ ní iyọ̀ ninu ara yín, nígbà náà ni alaafia yóo wà láàrin yín.”

Currently Selected:

MAKU 9: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in