MAKU 5
5
Jesu Mú Wèrè, Ará Geraseni, Lára dá
(Mat 8:28-34; Luk 8:26-39)
1Jesu lọ sí òdìkejì òkun ní ilẹ̀ àwọn ará Geraseni.#5:1 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn pe ilẹ̀ náà ní “Gadara”: àwọn mìíràn pè é ní “Gegeseni.” 2Bí ó ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, ọkunrin wèrè kan wá pàdé rẹ̀ láti inú ibojì pàlàpálá àpáta. 3Ibojì náà ni ò fi ṣe ilé. Kò sí ẹni tí ó lè de wèrè náà mọ́lẹ̀; ẹ̀wọ̀n kò tilẹ̀ ṣe é fi dè é. 4Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀, tí wọ́n tún fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́. Ṣugbọn jíjá ni ó máa ń já ẹ̀wọ̀n, tí ó sì máa ń rún ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè é. Kò sí ẹni tí ó lè fi agbára mú un kí ó fi ara balẹ̀. 5Tọ̀sán-tòru níí máa kígbe láàrin àwọn ibojì ati lórí òkè, a sì máa fi òkúta ya ara rẹ̀.
6Ṣugbọn nígbà tí ó rí Jesu lókèèrè, ó sáré, ó dọ̀bálẹ̀ níwájú rẹ̀. 7Ó ké rara pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ọmọ Ọlọrun tí ó lógo jùlọ? Mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.” 8(Nítorí Jesu tí ń sọ pé kí ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọkunrin náà.)
9Jesu wá bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”
Ó ní, “Ẹgbaagbeje#5:9 Ní Giriki: Legioni. ni mò ń jẹ́, nítorí a kò níye.” 10Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu títí pé kí ó má ṣe lé wọn jáde kúrò ní agbègbè ibẹ̀.
11Agbo ọ̀pọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ kan wà níbẹ̀, wọ́n ń jẹ lẹ́bàá òkè. 12Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó rán wọn sí ààrin ẹlẹ́dẹ̀ náà, kí wọ́n lè wọ inú wọn. 13Ó bá gbà bẹ́ẹ̀ fún wọn. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde lọ, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà bá tú pẹ̀ẹ́, wọ́n sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí òkun, wọ́n bá rì sinu òkun. Wọ́n tó bí ẹgbaa (2,000).
14Àwọn olùtọ́jú wọn bá sálọ sí àwọn ìlú ati àwọn abúlé tí ó wà yíká láti ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn eniyan bá wá fi ojú ara wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀. 15Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin náà tí ó ti jẹ́ wèrè rí, tí ó ti ní ẹgbaagbeje ẹ̀mí èṣù, ó jókòó, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì ti bọ̀ sípò. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí ó rí i. 16Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣe ojú wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà ati àwọn ẹlẹ́dẹ̀.
17Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu pé kí ó kúrò ní agbègbè wọn.
18Bí ó ti ń wọ ọkọ̀ ojú omi pada, ọkunrin tí ó ti jẹ́ wèrè rí yìí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí òun máa bá a lọ.
19Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó sọ fún un pé, “Lọ sí ilé rẹ, sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sọ ohun tí Oluwa ti ṣe fún ọ ati bí ó ti ṣàánú rẹ.”
20Ọkunrin náà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un ní agbègbè Ìlú Mẹ́wàá,#5:20 Ní Giriki: Dekapolisi. ẹnu sì ya gbogbo eniyan tí ó gbọ́.
Ọmọdebinrin Jairu ati Obinrin kan Onísun Ẹ̀jẹ̀
(Mat 9:18-26; Luk 8:40-56)
21Nígbà tí Jesu tún rékọjá lọ sí òdìkejì òkun, ọpọlọpọ eniyan wọ́ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́bàá òkun. 22Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Jairu, aṣaaju kan ni ní ilé ìpàdé ibẹ̀. Nígbà tí ó rí Jesu, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, 23ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́. Ó ní, “Ọmọdebinrin mi ń kú lọ, wá gbé ọwọ́ lé e, kí ó lè yè.”
24Jesu bá bá a lọ. Bí ó ti ń lọ, ọpọlọpọ eniyan ń tẹ̀lé e, wọ́n ń fún un lọ́tùn-ún lósì.
25Obinrin kan wà láàrin wọn tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀ tí kò dá fún ọdún mejila. 26Ojú rẹ̀ ti rí oríṣìíríṣìí lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn. Gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó ti run sórí àìsàn náà. Ṣugbọn kàkà kí ó sàn, ńṣe ni àìsàn náà túbọ̀ ń burú sí i.#Tob 2:10 27Nígbà tí obinrin náà gbọ́ nípa Jesu, ó gba ààrin àwọn eniyan dé ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, 28nítorí ó sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Bí ó bá jẹ́ aṣọ rẹ̀ ni mo lè fi ọwọ́ kàn, ara mi yóo dá.”
29Lẹsẹkẹsẹ tí ó fọwọ́ kàn án ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá dá. Ó sì mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé a ti mú òun lára dá ninu àìsàn náà. 30Lójú kan náà Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé agbára ìwòsàn jáde lára òun. Ó bá yipada sí àwọn eniyan, ó bèèrè pé, “Ta ni fọwọ́ kàn mí láṣọ?”
31Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “O rí i bí àwọn eniyan ti ń fún ọ lọ́tùn-ún lósì, o tún ń bèèrè pé ta ni fọwọ́ kàn ọ́?”
32Ṣugbọn Jesu ń wò yíká láti rí ẹni tí ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. 33Obinrin náà mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun, ó bá yọ jáde. Ẹ̀rù bà á, ó ń gbọ̀n, ó bá wá kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó sọ gbogbo òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un. 34Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní alaafia, o kò ní gbúròó àìsàn náà mọ́.”
35Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, ni àwọn kan bá dé láti ilé olórí ilé ìpàdé tí Jesu ń bá lọ sílé, wọ́n ní, “Ọmọdebinrin rẹ ti kú, kí ni o tún ń yọ olùkọ́ni lẹ́nu sí?”
36Ṣugbọn Jesu kò pé òun gbọ́ ohun tí wọn ń sọ, ó wí fún ọkunrin náà pé, “Má bẹ̀rù, ṣá ti gbàgbọ́.” 37Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun àfi Peteru ati Jakọbu ati Johanu àbúrò Jakọbu. 38Nígbà tí wọ́n dé ilé olórí ilé ìpàdé náà, Jesu rí bí gbogbo ilé ti dàrú, tí ẹkún ati ariwo ń sọ gèè. 39Ó bá wọ inú ilé lọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kígbe, tí ẹ̀ ń sunkún bẹ́ẹ̀? Ọmọde náà kò kú; ó sùn ni.”
40Wọ́n bá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, ó bá lé gbogbo wọn jáde. Ó wá mú baba ati ìyá ọmọ náà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó wà pẹlu rẹ̀, ó wọ yàrá tí ọmọde náà wà lọ. 41Ó bá fa ọmọde náà lọ́wọ́, ó wí fún un pé, “Talita kumi” ìtumọ̀ èyí tíí ṣe, “Ìwọ ọmọde yìí, mo wí fún ọ, dìde.”
42Lẹsẹkẹsẹ ọmọdebinrin náà dìde, ó bá ń rìn, nítorí ọmọ ọdún mejila ni. Ìyàlẹ́nu ńlá ni ó jẹ́ fún gbogbo wọn. 43Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gan-an pé kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Ó ní kí wọn wá oúnjẹ fún ọmọde náà kí ó jẹ.
Currently Selected:
MAKU 5: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010