YouVersion Logo
Search Icon

LUKU 4

4
Ìdánwò Jesu
(Mat 4:1-11; Mak 1:12-13)
1Jesu pada láti odò Jọdani, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí bá darí rẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀. 2Ogoji ọjọ́ ni èṣù fi dán an wò. Kò jẹ ohunkohun ní gbogbo àkókò náà. Lẹ́yìn náà, ebi wá ń pa á.
3Èṣù sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni ọ́ nítòótọ́, sọ fún òkúta yìí pé kí ó di àkàrà.”
4Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè.’ ”#Diut 8:33
5Èṣù bá mú un lọ sí orí òkè kan, ó fi gbogbo ìjọba ayé hàn án ní ìṣẹ́jú kan. 6Ó sọ fún Jesu pé, “Ìwọ ni n óo fún ní gbogbo àṣẹ yìí ati ògo rẹ̀, nítorí èmi ni a ti fi wọ́n lé lọ́wọ́, ẹni tí ó bá sì wù mí ni mo lè fún. 7Tí o bá júbà mi, tìrẹ ni gbogbo rẹ̀ yóo dà.”
8Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o sì máa sìn!’ ”#Diut 6:13
9Èṣù tún mú un lọ sí Jerusalẹmu. Ó gbé e ka téńté òrùlé Tẹmpili. Ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀ láti ìhín. 10Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ pé kí wọn pa ọ́ mọ́.’ 11Ati pé, ‘Kí wọn tẹ́wọ́ gbà ọ́ kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ”#O. Daf 91:11-12
12Jesu dá a lóhùn pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”#Diut 6:16
13Nígbà tí Satani parí gbogbo ìdánwò yìí, ó fi Jesu sílẹ̀ títí di àkókò tí ó bá tún wọ̀.
Jesu Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Rẹ̀ ní Galili
(Mat 4:12-17; Mak 1:14-15)
14Jesu pada sí Galili pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo ìgbèríko. 15Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. Gbogbo eniyan sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere.
Àwọn Ará Nasarẹti Kọ Jesu
(Mat 13:53-58; Mak 6:1-6)
16Ó wá dé Nasarẹti, ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí ilé ìpàdé. Ó bá dìde láti ka Ìwé Mímọ́. 17Wọ́n fún un ní ìwé wolii Aisaya. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé,
18“Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu mi
nítorí ó ti fi òróró yàn mí
láti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.
Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀
fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn,
ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran;
láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia,
19ati láti waasu ọdún tí Oluwa yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là.”#Ais 61:1-2
20Ó bá pa ìwé náà dé, ó fi í fún olùtọ́jú ilé ìpàdé, ó bá jókòó. Gbogbo àwọn eniyan tí ó wà ninu ilé ìpàdé tẹjú mọ́ ọn; 21ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé, “Lónìí ni àkọsílẹ̀ yìí ṣẹ ní ojú yín.”
22Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?”
23Ó sọ fún wọn pé, “Ní òtítọ́ ẹ lè pa òwe yìí fún mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn! Ohun gbogbo tí a gbọ́ pé o ṣe ní Kapanaumu, ṣe wọ́n níhìn-ín, ní ìlú baba rẹ.’ ” 24Ó tún fi kún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí wolii kan tíí ní iyì ní ìlú baba rẹ̀.#Joh 4:44
25“Òtítọ́ ni mo sọ fun yín pé opó pọ̀ ní Israẹli ní àkókò Elija, nígbà tí kò fi sí òjò fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ìyàn fi mú níbi gbogbo.#1 A. Ọba 17:1 26A kò rán Elija sí ọ̀kankan ninu wọn. Ọ̀dọ̀ ẹni tí a rán an sí ni opó kan ní Sarefati ní agbègbè Sidoni.#1 A. Ọba 17:8-16 27Àwọn adẹ́tẹ̀ pọ̀ ní Israẹli ní àkókò wolii Eliṣa. Kò sí ọ̀kan ninu wọn tí a wòsàn, àfi Naamani ará Siria.”#2 A. Ọba 5:1-14
28Nígbà tí àwọn tí ó wà ninu ilé ìpàdé gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí gbogbo wọn. 29Wọ́n dìde, wọ́n tì í sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ibi tí ìlú wọn wà, wọ́n fẹ́ taari rẹ̀ ní ogedengbe. 30Ṣugbọn ó la ààrin wọn kọjá, ó bá tirẹ̀ lọ.
Ọkunrin Tí Ó Ní Ẹ̀mí Èṣù
(Mak 1:21-28)
31Jesu bá lọ sí Kapanaumu, ìlú kan ní ilẹ̀ Galili. Ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi. 32Ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí pẹlu àṣẹ ni ó fi ń sọ̀rọ̀.#Mat 7:28-29 33Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò, 34ó ní, “Háà! Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ ti Ọlọrun ni ọ́.”
35Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí!” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbé ọkunrin náà ṣánlẹ̀ lójú gbogbo wọn, ó bá jáde kúrò lára rẹ̀, láì pa á lára.
36Ẹnu ya gbogbo eniyan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Irú ọ̀rọ̀ wo ni èyí? Nítorí pẹlu àṣẹ ati agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì ń jáde!” 37Òkìkí Jesu sì kàn ká gbogbo ìgbèríko ibẹ̀.
Jesu Wo Ọpọlọpọ Eniyan Sàn
(Mat 8:14-17; Mak 1:29-34)
38Nígbà tí Jesu dìde kúrò ní ilé ìpàdé, ó wọ ilé Simoni lọ. Ìyá iyawo Simoni ń ṣàìsàn akọ ibà. Wọ́n bá sọ fún Jesu. 39Ó bá lọ dúró lẹ́bàá ibùsùn ìyá náà, ó bá ibà náà wí, ibà sì fi ìyá náà sílẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún wọn.
40Nígbà tí oòrùn wọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n ní oríṣìíríṣìí àrùn ni wọ́n mú wá sọ́dọ̀ Jesu. Ó bá gbé ọwọ́ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó wò wọ́n sàn. 41Àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan, wọ́n ń kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.”
Jesu ń bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé Jesu ni Mesaya.
Jesu Ń Waasu Kiri
(Mak 1:35-39)
42Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jesu jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí ẹnìkankan. Àwọn eniyan ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fẹ́ dá a dúró kí ó má kúrò lọ́dọ̀ wọn. 43Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Dandan ni fún mi láti waasu ìyìn rere ìjọba ọ̀run ní àwọn ìlú mìíràn, nítorí ohun tí Ọlọrun rán mi wá ṣe nìyí.”
44Ni ó bá ń waasu ní gbogbo àwọn ilé ìpàdé ní Judia.

Currently Selected:

LUKU 4: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in