LUKU 23
23
Wọ́n Fa Jesu Lọ Siwaju Pilatu
(Mat 27:1-2, 11-14; Mak 15:1-5; Joh 18:28-38)
1Ni gbogbo àwùjọ bá dìde, wọ́n fa Jesu lọ sọ́dọ̀ Pilatu. 2Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án pé, “A rí i pé ńṣe ni ọkunrin yìí ń ba ìlú jẹ́. Ó ní kí àwọn eniyan má san owó-orí. Ó tún pe ara rẹ̀ ní Mesaya, Ọba.”
3Pilatu bá bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?”
Ó dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí i.”
4Pilatu wá sọ fún àwọn olórí alufaa ati àwọn eniyan pé, “Èmi kò rí àìdára kan tí ọkunrin yìí ṣe.”
5Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ tẹnu mọ́ ẹ̀sùn wọn pé, “Ó ń fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ da àwọn eniyan rú; Galili ni ó ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, ó ti dé gbogbo Judia níhìn-ín nisinsinyii.”
A Mú Jesu Lọ Sọ́dọ̀ Hẹrọdu
6Nígbà tí Pilatu gbọ́ èyí, ó bèèrè bí ará Galili bá ni Jesu. 7Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé lábẹ́ àṣẹ Hẹrọdu ni ó wà, ó rán an sí Hẹrọdu, nítorí pé Hẹrọdu náà kúkú wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà. 8Nígbà tí Hẹrọdu rí Jesu, inú rẹ̀ dùn pupọ. Nítorí ó ti pẹ́ tí ó ti fẹ́ rí i, nítorí ìró rẹ̀ tí ó ti ń gbọ́. Ó ń retí pé kí Jesu ṣe iṣẹ́ ìyanu lójú òun. 9Ó bi Jesu ní ọpọlọpọ ìbéèrè ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn rárá. 10Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin dúró níbẹ̀, wọ́n ń tẹnu mọ́ ẹ̀sùn tí wọn fi kàn án. 11Hẹrọdu ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ń kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n gbé ẹ̀wù dáradára kan wọ̀ ọ́; Hẹrọdu bá tún fi ranṣẹ pada sí Pilatu. 12Ní ọjọ́ náà Hẹrọdu ati Pilatu di ọ̀rẹ́ ara wọn; nítorí tẹ́lẹ̀ rí ọ̀tá ni wọ́n ń bá ara wọn ṣe.
A Dá Jesu Lẹ́bi Ikú
(Mat 27:15-26; Mak 15:5-15; Joh 18:39–19:16)
13Pilatu bá pe àwọn olórí alufaa, ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan jọ, 14ó sọ fún wọn pé, “Ẹ fa ọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ mi bí ẹni tí ó ń ba ìlú jẹ́. Lójú yín ni mo wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, tí n kò sì rí àìdára kan tí ó ṣe, ninu gbogbo ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án. 15Hẹrọdu náà kò rí nǹkankan wí sí i, nítorí ńṣe ni ó tún dá a pada sí wa. Ó dájú pé ọkunrin yìí kò ṣe nǹkankan tí ó fi yẹ kí á dá a lẹ́bi ikú. 16Nítorí náà nígbà tí a bá ti nà án tán, n óo dá a sílẹ̀.” [ 17Nítorí ó níláti dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún wọn ní àkókò àjọ̀dún.]
18Ṣugbọn gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí pariwo pé, “Mú eléyìí lọ! Baraba ni kí o dá sílẹ̀ fún wa.” 19(Baraba ti dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú nígbà kan, ó sì paniyan, ni wọ́n fi sọ ọ́ sẹ́wọ̀n.)
20Pilatu tún bá wọn sọ̀rọ̀, ó fẹ́ dá Jesu sílẹ̀. 21Ṣugbọn wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu! Kàn án mọ́ agbelebu!”
22Ó tún bi wọ́n ní ẹẹkẹta pé, “Kí ni nǹkan burúkú tí ó ṣe? Èmi kò rí ìdí kankan tí ó fi jẹ̀bi ikú. Nígbà tí mo bá ti nà án tán n óo dá a sílẹ̀.”
23Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ múra kankan, wọ́n ń kígbe pé kí ó kàn án mọ́ agbelebu. Ohùn wọn bá borí. 24Pilatu bá gbà láti ṣe bí wọ́n ti fẹ́. 25Ó dá ẹni tí wọ́n ní àwọn fẹ́ sílẹ̀: ẹni tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí pé ó paniyan. Ó bá fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́.
A Kan Jesu Mọ́ Agbelebu
(Mat 27:32-44; Mak 15:21-32; Joh 19:17-27)
26Bí wọ́n ti ń fa Jesu lọ, wọ́n bá fi ipá mú ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene tí ó ń ti ìgbèríko kan bọ̀. Wọ́n bá gbé agbelebu rù ú, wọ́n ní kí ó máa rù ú tẹ̀lé Jesu lẹ́yìn.
27Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé Jesu, pẹlu àwọn obinrin tí wọn ń dárò, tí wọn ń sunkún nítorí rẹ̀. 28Nígbà tí Jesu yipada sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ẹ má sunkún nítorí tèmi mọ́; ẹkún ara yín ati ti àwọn ọmọ yín ni kí ẹ máa sun. 29Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ẹ óo sọ pé, ‘Àwọn àgàn tí kò bímọ rí, tí wọn kò sì fún ọmọ lọ́mú rí ṣe oríire.’ 30Nígbà náà ni wọn yóo bẹ̀rẹ̀ sí máa sọ fún àwọn òkè ńlá pé, ‘Ẹ wó lù wá,’ wọ́n óo sì máa sọ fún àwọn òkè kékeré pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀.’#Hos 10:8; Ifi 6:16 31Nítorí bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí fún igi tútù, báwo ni yóo ti rí fún igi gbígbẹ?”
32Wọ́n tún ń fa àwọn arúfin meji kan pẹlu rẹ̀, láti lọ pa wọ́n. 33Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì. 34Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.”#23:34 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn kò ní gbolohun yìí.
Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.#O. Daf 22:18 35Àwọn eniyan dúró, wọ́n ń wòran. Àwọn ìjòyè ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé, “O gba àwọn ẹlòmíràn là; gba ara rẹ là bí ìwọ bá ni Mesaya, àyànfẹ́ Ọlọrun.”#O. Daf 22:7
36Àwọn ọmọ-ogun náà ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n fún un ní ọtí pé kí ó mu ún.#O. Daf 69:21 37Wọ́n ní, “Bí ìwọ bá ni ọba àwọn Juu, gba ara rẹ là.”
38Wọ́n kọ àkọlé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí òkè orí rẹ̀ pé, “Èyí ni ọba àwọn Juu.”
39Ọ̀kan ninu àwọn arúfin tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ ń sọ ìsọkúsọ pé, “Ṣebí ìwọ ni Mesaya! Gba ara rẹ là kí o sì gba àwa náà là!”
40Ṣugbọn ekeji bá a wí, ó ní, “Ìwọ yìí, o kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ìdájọ́ kan náà ni wọ́n dá fún un bíi tiwa. 41Ní tiwa, ó tọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí èrè iṣẹ́ wa ni à ń jẹ. Ṣugbọn òun ní tirẹ̀ kò ṣẹ̀ rárá.” 42Ó bá sọ fún Jesu pé, “Ranti mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.”
43Jesu bá sọ fún un pé, “Mo wí fún ọ, lónìí yìí ni ìwọ yóo wà pẹlu mi ní ọ̀run rere.”
Ikú Jesu
(Mat 27:45-56; Mak 15:33-41; Joh 19:28-30)
44-45Nígbà tí ó tó bí agogo mejila ọ̀sán, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán. Oòrùn kò ràn. Aṣọ ìkélé Tẹmpili ya sí meji.#Eks 26:31-33 46Jesu kígbe, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó mí kanlẹ̀, ó bá kú.#O. Daf 31:5
47Nígbà tí ọ̀gágun náà rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní, “Lóòótọ́, olódodo ni ọkunrin yìí.”
48Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n péjọ, tí wọn wá wòran, rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wọ́n pada lọ, tí wọ́n káwọ́ lérí pẹlu ìbànújẹ́. 49Gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ati àwọn obinrin tí wọ́n tẹ̀lé e wá láti Galili, gbogbo wọn dúró lókèèrè, wọ́n ń wo gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀.#Luk 8:2-3
Ìsìnkú Jesu
(Mat 27:57-61; Mak 15:42-47; Joh 19:38-42)
50-51Ọkunrin kan wà ninu àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń jẹ́ Josẹfu. Ó jẹ́ eniyan rere ati olódodo. Òun kò bá wọn lóhùn sí ète tí wọ́n pa, ati ohun tí wọ́n ṣe sí Jesu. Ó jẹ́ ará Arimatia, ìlú kan ní Judia. Ó ń retí ìjọba Ọlọrun. 52Òun ni ó lọ sọ́dọ̀ Pilatu, tí ó bèèrè òkú Jesu. 53Ó sọ òkú náà kalẹ̀ lórí agbelebu, ó fi aṣọ funfun wé e, ó bá tẹ́ ẹ sinu ibojì tí wọ́n gbẹ́ sinu àpáta, tí wọn kò ì tíì tẹ́ òkú sí rí. 54Ọjọ́ náà jẹ̀ Ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́, Ọjọ́ Ìsinmi fẹ́rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
55Àwọn obinrin tí wọn bá Jesu wá láti Galili tẹ̀lé Josẹfu yìí, wọ́n ṣe akiyesi ibojì náà, ati bí a ti ṣe tẹ́ òkú Jesu sinu rẹ̀. 56Wọ́n bá pada lọ láti lọ tọ́jú turari olóòórùn dídùn ati ìpara tí wọn fi ń tọ́jú òkú.#Eks 20:10; Diut 5:14
Ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n sinmi gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí.
Currently Selected:
LUKU 23: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010