YouVersion Logo
Search Icon

LUKU 14

14
Jesu Wo Ọkunrin Tí Ara Rẹ̀ Wú Sàn
1Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, Jesu lọ jẹun ní ilé ọ̀kan ninu àwọn olóyè láàrin àwọn Farisi. Wọ́n bá ń ṣọ́ ọ. 2Ọkunrin kan wà níwájú rẹ̀ níbẹ̀ tí gbogbo ara rẹ̀ wú bòmù-bòmù. 3Jesu bi àwọn amòfin ati àwọn Farisi tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ṣé ó dára láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, tabi kò dára?”
4Wọ́n bá dákẹ́. Jesu bá mú ọkunrin náà, ó wò ó sàn, ó bá ní kí ó máa lọ. 5Ó wá bi wọ́n pé, “Ta ni ninu yín tí ọmọ rẹ̀, tabi mààlúù rẹ̀ yóo já sinu kànga ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á yọ lẹsẹkẹsẹ?”#Mat 12:11
6Wọn kò sì lè dá a lóhùn.
Ẹ̀kọ́ Nípa Ìrẹ̀lẹ̀
7Nígbà tí Jesu ṣe akiyesi bí àwọn tí a pè sí ibi àsè ti ń yan ipò ọlá, ó wá pa òwe kan fún wọn. Ó ní, 8“Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ sí ibi iyawo, má ṣe lọ jókòó ní ipò ọlá. Bóyá ẹni tí ó pè ọ́ tún pe ẹlòmíràn tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ. 9Ẹni tí ó pè ọ́ yóo wá tọ̀ ọ́ wá, yóo sọ fún ọ pé, ‘Fi ààyè fún ọkunrin yìí,’ Ìwọ yóo wá fi ìtìjú bẹ̀rẹ̀ sí máa wá ààyè lẹ́yìn. 10Tí wọn bá pè ọ́, lọ jókòó lẹ́yìn, kí ẹni tí ó pè ọ́ lè wá sọ fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi súnmọ́ iwájú.’ Nígbà náà ìwọ yóo ní iyì lójú gbogbo àwọn tí ó wà níbi àsè.#Òwe 25:6-7 11Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”#Mat 23:12; Luk 18:14
12Ó wá sọ fún ẹni tí ó pè é fún oúnjẹ pé, “Nígbà tí o bá se àsè, ìbáà jẹ́ lọ́sàn-án tabi lálẹ́, má ṣe pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tabi àwọn arakunrin rẹ tabi àwọn ẹbí rẹ tabi àwọn aládùúgbò rẹ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀. Bí o bá pè wọ́n, àwọn náà yóo pè ọ́ wá jẹun níjọ́ mìíràn, wọn yóo sì san oore tí o ṣe wọ́n pada fún ọ. 13Ṣugbọn bí o bá se àsè, pe àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú. 14Èyí ni yóo fún ọ láyọ̀, nítorí wọn kò lè san án pada fún ọ. Ṣugbọn Ọlọrun yóo san án pada fún ọ nígbà tí àwọn olódodo bá jí dìde kúrò ninu òkú.”
Òwe Nípa Àsè Ńlá
(Mat 22:1-10)
15Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn tí ó wà níbi àsè gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ fún Jesu pé, “Ẹni tí ó bá jẹun ní ìjọba ọ̀run ṣe oríire!”
16Jesu sọ fún un pé, “Ọkunrin kan se àsè ńlá kan; ó pe ọ̀pọ̀ eniyan sibẹ. 17Nígbà tí àkókò ati jẹun tó, ó rán iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn tí ó ti pè láti sọ fún wọn pé, ‘Ó yá o! A ti ṣetán!’ 18Ni gbogbo wọn patapata láìku ẹnìkan bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí. Ekinni sọ fún un pé, ‘Mo ra ilẹ̀ kan, mo sì níláti lọ wò ó. Mo tọrọ àforíjì, yọ̀ǹda mi.’ 19Ẹnìkejì ní, ‘Mo ra mààlúù fún ẹ̀rọ-ìroko. Mò ń lọ dán an wò, dákun, yọ̀ǹda mi.’ 20Ẹnìkẹta ní, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé iyawo ni, nítorí náà n kò lè wá.’
21“Iranṣẹ náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún oluwa rẹ̀. Inú wá bí baálé ilé náà. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Tètè lọ sí gbogbo títì ati ọ̀nà ẹ̀bùrú ìlú, kí o lọ kó àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú, ati àwọn arọ wá síhìn-ín.’ 22Nígbà tí iranṣẹ náà ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, ó ní, ‘Alàgbà, a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, sibẹ àyè tún kù.’ 23Oluwa iranṣẹ náà sọ fún un pé, ‘Lọ sí ọ̀nà oko, kí o bẹ àwọn ẹni tí o bá rí, kí wọ́n wọlé wá, kí inú ilé mi baà kún. 24Nítorí kò sí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọ̀n-ọn-nì tí a ti kọ́kọ́ pè tí yóo tọ́ wò ninu àsè mi!’ ”
Ohun Tí Eniyan Gbọdọ̀ Ṣe Kí Ó Tó Lè Jẹ́ Ọmọ-ẹ̀yìn
(Mat 10:37-38)
25Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan péjọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá yíjú pada sí wọn, ó ní, 26“Bí ẹnìkan bá fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi, bí kò bá kórìíra baba rẹ̀ ati ìyá rẹ̀, ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati ẹ̀gbọ́n, ati àbúrò rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, tí ó fi mọ́ ẹ̀mí òun pàápàá, kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.#Mat 10:37 27Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.#Mat 10:38; 16:24; Mak 8:34; Luk 9:23
28“Nítorí ta ni ninu yín tí yóo fẹ́ kọ́ ilé ńlá kan, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye tí yóo ná òun, kí ó mọ̀ bí òun bá ní ohun tí òun yóo fi parí rẹ̀? 29Kí ó má wá jẹ́ pé yóo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ tán, kò ní lè parí rẹ̀ mọ́. Gbogbo àwọn tí ó bá rí i yóo wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe yẹ̀yẹ́. 30Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọkunrin yìí bẹ̀rẹ̀ ilé, kò lè parí rẹ̀!’
31“Tabi ọba wo ni yóo lọ ko ọba mìíràn lójú ogun tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó gba ìmọ̀ràn bí òun yóo bá lè ko ẹni tí ó ní ọ̀kẹ́ kan ọmọ-ogun lójú? 32Bí kò bá ní lè kò ó lójú, kí ọ̀tá rẹ̀ tó dé ìtòsí, yóo tètè rán ikọ̀ sí i pé òun túúbá. 33Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni ninu yín tí kò bá kọ gbogbo ohun tí ó ní sílẹ̀, kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.
Iyọ̀ Tí Ó Di Òbu
(Mat 5:13; Mak 9:50)
34“Iyọ̀ dára. Ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni a ti ṣe lè mú kí ó tún dùn? 35Kó wúlò fún oko tabi fún ààtàn mọ́ àfi kí á dà á sóde. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

Currently Selected:

LUKU 14: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in