LUKU 11
11
Adura Oluwa
(Mat 6:9-13; 7:7-11)
1Nígbà kan, Jesu wà níbìkan, ó ń gbadura. Nígbà tí ó parí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, kọ́ wa bí a ti í gbadura gẹ́gẹ́ bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”
2Ó sọ fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ máa wí pé,
‘Baba, ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ.
Kí ìjọba rẹ dé.
3Máa fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lojoojumọ.
4Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,
nítorí àwa náà ń dáríjì gbogbo ẹni tí ó bá jẹ wá ní gbèsè.
Má ṣe fà wá sinu ìdánwò.’ ”
5Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní ọ̀rẹ́ kan, tí ó wá lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ yìí ní ọ̀gànjọ́ òru, tí ó sọ fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi, yá mi ní burẹdi mẹta, 6nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti ìrìn àjò dé bá mi, n kò sì ní oúnjẹ tí n óo fún un’; 7kí ọ̀rẹ́ náà wá ti inú ilé dáhùn pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu. Mo ti ti ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi sì wà lórí ẹní pẹlu mi, n kò lè tún dìde kí n fún ọ ní nǹkankan mọ́.’ 8Mò ń sọ fun yín pé, bí kò tilẹ̀ fẹ́ dìde kí ó fún ọ nítorí o jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nítorí tí o kò tijú láti wá kan ìlẹ̀kùn mọ́ ọn lórí lóru, yóo dìde, yóo fún ọ ní ohun tí o nílò.
9“Bákan náà mo sọ fun yín, ẹ bèèrè, a óo fi fun yín; ẹ wá kiri, ẹ óo rí; ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín. 10Nítorí gbogbo ẹni tí ó bá bèèrè ni yóo rí gbà; ẹni tí ó bá wá kiri yóo rí; ẹni tí ó bá sì kan ìlẹ̀kùn ni a óo ṣí i fún. 11Baba wo ninu yín ni ó jẹ́ fún ọmọ rẹ̀ ní ejò, nígbà tí ọmọ bá bèèrè ẹja? 12Tabi bí ó bá bèèrè ẹyin tí ó jẹ́ fún un ní àkeekèé? 13Nítorí náà bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fún àwọn ọmọ yín ní ohun tí ó dára, mélòó-mélòó ni Baba yín ọ̀run yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”
Jesu ati Beelisebulu
(Mat 12:22-30; Mak 3:20-27)
14Ní ìgbà kan, Jesu ń lé ẹ̀mí èṣù kan tí ó yadi jáde. Nígbà tí ẹ̀mí Èṣù náà ti jáde tán ọkunrin odi náà sọ̀rọ̀, ẹnu wá ya àwọn eniyan. 15Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”#Mat 9:34; 10:25
16Àwọn ẹlòmíràn ń dẹ ẹ́, wọ́n ń bèèrè àmì ọ̀run láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.#Mat 12:38; 16:1; Mak 8:11 17Ṣugbọn Jesu mọ èrò wọn, ó sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun, ilé tí ó bá dìde sí ara rẹ̀ yóo tú ká. 18Bí Satani bá gbé ogun ti ara rẹ̀, báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró? Nítorí ẹ̀ ń sọ pé agbára Beelisebulu ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. 19Bí ó bá jẹ́ agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ní ti èrò yín yìí, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín. 20Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín.
21“Nígbà tí ọkunrin alágbára bá wà ní ihamọra, tí ó ń ṣọ́ ilé rẹ̀, kò sí ohun tí ó lè ṣe dúkìá rẹ̀. 22Ṣugbọn nígbà tí ẹni tí ó lágbára jù ú lọ bá dé, tí ó ṣẹgun rẹ̀, a gba ohun ìjà tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a sì pín dúkìá rẹ̀ tí ó jí kó.
23“Ẹni tí kò bá sí lẹ́yìn mi, olúwarẹ̀ lòdì sí mi ni, ẹni tí kò bá ti bá mi kó nǹkan jọ, a jẹ́ pé títú ni ó ń tú wọn ká.#Mak 9:40
Ẹ̀mí Èṣù Tí Ó Tún Pada
(Mat 12:43-45)
24“Nígbà tí ẹ̀mí èṣù bá jáde kúrò ninu ẹnìkan, á máa wá ilẹ̀ gbígbẹ kiri láti sinmi. Nígbà tí kò bá rí, á ní, ‘N óo tún pada sí ilé mi níbi tí mo ti jáde kúrò.’ 25Nígbà tí ó bá dé ibẹ̀, tí ó rí i pé a ti gbá a, a sì ti ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, 26ẹ̀mí èṣù náà yóo bá lọ mú àwọn ẹ̀mí meje mìíràn wá tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n óo bá wọ ibẹ̀ wọn óo máa gbébẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà á wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
Ẹni Tí Ó Ṣe Oríire Tòótọ́
27Bí Jesu ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, obinrin kan láàrin àwọn eniyan fọhùn sókè pé, “Ẹni tí ó bí ọ, tí ó wò ọ́ dàgbà náà ṣe oríire lọpọlọpọ.”
28Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Èyí tí ó jù ni pé àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń pa á mọ́ ṣe oríire.”
Àwọn Kan Bèèrè Àmì Lọ́wọ́ Jesu
(Mat 12:38-42; Mak 8:12)
29Nígbà tí ọ̀pọ̀ eniyan péjọ yí i ká, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran burúkú ni ìran yìí; ó ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fún un àfi àmì Jona.#Mat 16:4; Mak 8:12 30Nítorí bí Jona ti di àmì fún àwọn ará Ninefe, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọmọ-Eniyan yóo jẹ́ àmì fún ìran yìí.#Jona 3:4 31Ayaba láti ilẹ̀ gúsù yóo dìde dúró ní ọjọ́ ìdájọ́ láti ko ìran yìí lójú, yóo sì dá wọn lẹ́bi. Nítorí ó wá láti òpin ilẹ̀ ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Solomoni, Ẹ wò ó! Ẹni tí ó ju Solomoni lọ wà níhìn-ín.#1 A. Ọba 10:1-10; 2Kron 9:1-12 32Àwọn eniyan Ninefe yóo dìde dúró ní ọjọ́ ìdájọ́ láti ko ìran yìí lójú, wọn yóo sì dá wọn lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nígbà tí Jona waasu fún wọn. Ẹ wò ó! Ẹni tí ó ju Jona lọ wà níhìn-ín.#Jona 3:5
Ìmọ́lẹ̀ Ara
(Mat 5:15; 6:22-23)
33“Kò sí ẹni tí ó jẹ́ tan fìtílà, tí ó jẹ́ fi pamọ́, tabi kí ó fi igbá bò ó. Ńṣe ni yóo gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà kí àwọn tí ó bá ń wọlé lè ríran.#Mat 5:15; Mak 4:21; Luk 8:16 34Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn. 35Nítorí náà kí ẹ ṣọ́ra kí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu yín má baà jẹ́ òkùnkùn. 36Bí gbogbo ara rẹ bá ní ìmọ́lẹ̀, tí kò sí ibìkan tí ó ṣókùnkùn, ńṣe ni yóo mọ́lẹ̀ bí ìgbà tí àtùpà bá tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.”
Jesu Bá Àwọn Farisi ati Àwọn Amòfin Wí
(Mat 23:1-36; Mak 12:38-40; Luk 20:45-47)
37Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, Farisi kan pè é pé kí ó wá jẹun ninu ilé rẹ̀. Ó bá wọlé, ó jókòó. 38Ẹnu ya Farisi náà nígbà tí ó rí i pé Jesu kò kọ́kọ́ wẹwọ́ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. 39Oluwa wá sọ fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa fọ òde kọ́ọ̀bù ati àwo oúnjẹ, ṣugbọn inú yín kún fún ìwà ipá ati nǹkan burúkú! 40Ẹ̀yin aṣiwèrè wọnyi! Mo ṣebí ẹni tí ó dá òde, òun náà ni ó dá inú. 41Ohun kan ni kí ẹ ṣe: ẹ fi àwọn ohun tí ó wà ninu kọ́ọ̀bù ati àwo ṣe ìtọrẹ àánú; bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan di mímọ́ fun yín.
42“Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ̀ ń ṣe ìdámẹ́wàá lórí ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, gbúre ati oríṣìíríṣìí ewébẹ̀, nígbà tí ẹ kò ka ìdájọ́ òdodo ati ìfẹ́ Ọlọrun sí. Àwọn ohun tí ẹ kò kà sí wọnyi ni ó yẹ kí ẹ ṣe, láì gbàgbé àwọn nǹkan yòókù náà.#Lef 27:30
43“Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ fẹ́ràn ìjókòó iwájú ninu ilé ìpàdé. Ẹ tún fẹ́ràn kí eniyan máa ki yín láàrin ọjà. 44Ẹ gbé! Nítorí ẹ dàbí ibojì tí kò ní àmì, tí àwọn eniyan ń rìn lórí wọn, tí wọn kò mọ̀.”
45Ọ̀kan ninu àwọn amòfin sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ báyìí, ò ń fi àbùkù kan àwa náà!”
46Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin amòfin náà gbé! Nítorí ẹ̀ ń di ẹrù bàràkàtà-bàràkàtà lé eniyan lórí nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò jẹ́ fi ọwọ́ yín kan ẹrù kan. 47Ẹ gbé! Nítorí ẹ̀ ń kọ́ ibojì àwọn wolii, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn baba yín ni wọ́n pa wọ́n. 48Ṣíṣe tí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fi yín hàn bí ẹlẹ́rìí pé ẹ lóhùn sí ìwà àwọn baba yín: wọ́n pa àwọn wolii, ẹ̀yin wá ṣe ibojì sí ojú-oórì wọn. 49Ìdí nìyí tí ọgbọ́n Ọlọrun ṣe wí pé, ‘N óo rán àwọn wolii ati àwọn òjíṣẹ́ si yín, ẹ óo pa ninu wọn, ẹ óo ṣe inúnibíni sí àwọn mìíràn.’ 50Nítorí náà, ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn wolii tí a ti ta sílẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé,#a Jẹn 4:8; b 2Kron 24:20-21 51ohun tí ó ṣẹ̀ lórí Abeli títí dé orí Sakaraya tí a pa láàrin ibi pẹpẹ ìrúbọ ati Ilé Ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo wọn.
52“Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin. Ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ́wọ́, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé. Ẹ tún ń dá àwọn tí ó fẹ́ wọlé dúró!”
53Nígbà tí Jesu jáde kúrò ninu ilé, àwọn amòfin ati àwọn Farisi takò ó, wọ́n ń bi í léèrè ọ̀rọ̀ pupọ, 54wọ́n ń dẹ ẹ́ kí wọn lè ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu.
Currently Selected:
LUKU 11: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010