YouVersion Logo
Search Icon

LEFITIKU 23

23
Àwọn Àjọ̀dún Ẹ̀sìn
1OLUWA sọ fún Mose 2pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Àwọn àjọ̀dún tí èmi OLUWA yàn tí ó gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí ìpéjọ mímọ́ nìwọ̀nyí: 3Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ati ọjọ́ ìpéjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, ọjọ́ ìsinmi ni fún OLUWA ní gbogbo ibùgbé yín.#Eks 20:8-10; 23:12; 31:15; 34:21; 35:2; Diut 5:12-14, 4Èyí ni àwọn àjọ̀dún ati àpèjọ tí OLUWA yàn, tí wọ́n gbọdọ̀ kéde, ní àkókò tí OLUWA yàn fún wọn.
Àjọ̀dún Ìrékọjá ati Àìwúkàrà
(Nọm 28:16-25)
5“Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni kí ẹ máa ṣe àjọ ìrékọjá OLUWA.#Eks 12:1-3; Diut 16:1-2 6Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kan náà sì ni àjọ àìwúkàrà OLUWA. Ọjọ́ meje gbáko ni ẹ gbọdọ̀ fi máa jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. 7Ní ọjọ́ kinni, ẹ níláti ní àpèjọ, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó bá lágbára. 8Ṣugbọn, ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA fún ọjọ́ meje náà, ọjọ́ àpèjọ mímọ́ ni ọjọ́ keje yóo jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó lágbára.”#Eks 12:14-20; 23:15; 34:18; Diut 16:3-8.
9OLUWA tún rán Mose pé kí ó 10sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, tí ẹ bá sì ń kórè nǹkan inú rẹ̀, ẹ níláti gbé ìtí ọkà kan lára àkọ́so oko yín tọ alufaa lọ. 11Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keji, lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi, alufaa yóo fi ìtí ọkà náà rú ẹbọ fífì níwájú OLUWA, kí ẹ lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 12Ní ọjọ́ tí ẹ bá ń fi ìtí ọkà yín rú ẹbọ fífì, kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ aguntan ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA. 13Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu rẹ̀ nìyí: ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí wọ́n fi òróró pò, ẹ óo fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA, kí ẹ sì fi idamẹrin ìwọ̀n hini ọtí waini rú ẹbọ ohun mímu pẹlu rẹ̀. 14Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tabi ọkà, kì báà jẹ́ ọkà yíyan tabi tútù títí di ọjọ́ yìí, tí ẹ óo fi mú ẹbọ Ọlọrun yín wá, ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún ìrandíran yín, ní gbogbo ilẹ̀ yín.
Àjọ̀dún Ìkórè
(Nọm 28:26-31)
15“Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi tí ẹ mú ìtí ọkà fún ẹbọ fífì wá fún OLUWA. 16Ẹ óo ka aadọta ọjọ́ títí dé ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi keje, lẹ́yìn náà, ẹ óo mú ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ fi ọkà titun ṣe wá fún OLUWA. 17Ẹ óo mú burẹdi meji tí wọ́n fi ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára ṣe wá fún ẹbọ fífì; àwọn àkàrà náà yóo ní ìwúkàrà ninu, ẹ óo mú wọn tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí àkọ́so oko yín. 18Ẹ óo mú ọ̀dọ́ aguntan meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù lọ́wọ́, pẹlu ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati àgbò meji, nígbà tí ẹ bá ń kó àwọn ìṣù àkàrà meji náà bọ̀. Àwọn ni ẹ óo fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA; pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu, ẹbọ tí a fi iná sun, olóòórùn dídùn, tí OLUWA gbádùn ni. 19Ẹ óo fi òbúkọ kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹ óo sì fi àgbò meji ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ alaafia. 20Alufaa yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, pẹlu burẹdi tí ẹ fi àkọ́so ọkà ṣe, ati àgbò meji náà, wọn yóo jẹ́ ọrẹ mímọ́ fún OLUWA, tí a óo yà sọ́tọ̀ fún àwọn alufaa. 21Ẹ pe àpèjẹ mímọ́ ní ọjọ́ náà; ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà. Ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún arọmọdọmọ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín títí lae.#Eks 23:16; 34:22; Diut 16:9-12
22“Nígbà tí ẹ bá ń kórè oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè títí dé ààlà patapata. Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè tán, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ gbọdọ̀ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”#Lef 19:9-10; Diut 24:19-22
Àjọ̀dún Ọdún Titun
(Nọm 29:1-6)
23OLUWA sọ fun Mose 24pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ ya ọjọ́ kinni oṣù keje sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ẹ óo kéde rẹ̀ pẹlu ìró fèrè, ẹ óo sì ní àpèjọ mímọ́. 25Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kan, ẹ sì níláti rú ẹbọ sísun sí OLUWA.”
Ọjọ́ Ètùtù
(Nọm 29:7-11)
26OLUWA sọ fún Mose pé, 27“Ọjọ́ kẹwaa oṣù keje ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ní ìpéjọpọ̀ mímọ́ ní ọjọ́ náà, kí ẹ gbààwẹ̀, kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA. 28Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ ètùtù ni, tí wọn yóo ṣe ètùtù fun yín níwájú OLUWA Ọlọrun yín. 29Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀. 30Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, n óo pa á run láàrin àwọn eniyan rẹ̀. 31Ẹ kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, ìlànà ni ó jẹ́ títí lae fún ìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín. 32Yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀. Ọjọ́ ìsinmi náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsan-an títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹwaa.”#Lef 16:29-34
Àjọ Àgọ́
(Nọm 29:12-40)
33OLUWA sọ fún Mose 34pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, ẹ óo ṣe àjọ̀dún Àgọ́ fún OLUWA; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi ṣe é. 35Ìpéjọpọ̀ mímọ́ yóo wà ní ọjọ́ kinni, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà. 36Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ óo ní ìpéjọpọ̀ mímọ́, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ìpéjọpọ̀ tí ó lọ́wọ̀ ni, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.#Diut 16:13-15.
37“Àwọn àjọ̀dún wọnyi ni OLUWA ti yà sọ́tọ̀; ẹ óo máa kéde wọn gẹ́gẹ́ bí àkókò ìpéjọpọ̀ mímọ́, láti máa rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA, ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ; ati ẹbọ ohun mímu, olukuluku ní ọjọ́ tí a ti yàn fún wọn. 38Àwọn ẹbọ wọnyi wà lọ́tọ̀ ní tiwọn, yàtọ̀ sí ti àwọn ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA, ati àwọn ẹ̀bùn yín, ati àwọn ẹbọ ẹ̀jẹ́ yín, ati àwọn ọrẹ ẹbọ àtinúwá tí ẹ óo máa mú wá fún OLUWA.
39“Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè àwọn èso ilẹ̀ yín tán, láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, kí ẹ máa ṣe àjọ àjọ̀dún OLUWA fún ọjọ́ meje; ọjọ́ kinni ati ọjọ́ kẹjọ yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀. 40Ní ọjọ́ kinni, ẹ óo mú ninu àwọn èso igi tí ó bá dára, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka igi tí ó ní ewé dáradára, ati ẹ̀ka igi wilo etí odò, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín fún ọjọ́ meje. 41Ọjọ́ meje láàrin ọdún kan ni ẹ óo máa fi ṣe àjọ̀dún fún OLUWA; Ìlànà títí lae ni èyí jẹ́ fún arọmọdọmọ yín. Ninu oṣù keje ọdún ni ẹ óo máa ṣe àjọ àjọ̀dún náà. 42Inú àgọ́ ni ẹ óo máa gbé fún gbogbo ọjọ́ meje náà; gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọ Israẹli ni ó gbọdọ̀ gbé inú àgọ́, 43kí àwọn arọmọdọmọ yín lè mọ̀ pé, inú àgọ́ ni mo mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa gbé nígbà tí mo kó wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”
44Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe ṣàlàyé àwọn Àjọ àjọ̀dún tí OLUWA yàn, fún àwọn ọmọ Israẹli.

Currently Selected:

LEFITIKU 23: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in