YouVersion Logo
Search Icon

LEFITIKU 22

22
Àwọn Ohun Ìrúbọ Gbọdọ̀ Jẹ́ Mímọ́
1OLUWA rán Mose pé, 2“Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ pé, kí wọ́n máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lo àwọn nǹkan mímọ́ tí àwọn eniyan Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má baà ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni OLUWA. 3Bí èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ wọn bá súnmọ́ àwọn nǹkan mímọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí àwọn eniyan Israẹli ti yà sí mímọ́ fún OLUWA; nígbà tí ó wà ní ipò àìmọ́, a óo mú ẹni náà kúrò lọ́dọ̀ mi. Èmi ni OLUWA.
4“Ẹnikẹ́ni ninu ìran Aaroni tí ó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí ara rẹ̀ bá ń tú, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà, títí tí yóo fi di mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ pé ó fara kan òkú ni, tabi pé ó fara kan ẹni tí nǹkan ọkunrin jáde lára rẹ̀, 5tabi ẹni tí ó bá fara kan èyíkéyìí ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri, èyí tí ó lè sọ eniyan di aláìmọ́, tabi ẹnikẹ́ni tí ó lè kó àìmọ́ bá eniyan, ohun yòówù tí àìmọ́ rẹ̀ lè jẹ́. 6Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tabi irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; kò sì ní jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà títí tí yóo fi wẹ̀. 7Nígbà tí oòrùn bá wọ̀, yóo di mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà nítorí oúnjẹ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́. 8Alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrara rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú bá pa; kí ó má baà fi òkú ẹran yìí sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA.
9“Àwọn alufaa gbọdọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀ nítorí rẹ̀, kí wọ́n sì kú nítorí àwọn òfin mi tí wọ́n bá rú. Èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.
10“Àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni àlejò tabi alágbàṣe tí ń gbé ilé alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu wọn. 11Ṣugbọn bí alufaa bá fi owó ra ẹrú fún ara rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà. Àwọn ọmọ tí ẹrú náà bá sì bí ninu ilé alufaa náà lè jẹ ninu oúnjẹ náà pẹlu. 12Bí ọmọbinrin alufaa kan bá fẹ́ àjèjì, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n bá fi rúbọ. 13Ṣugbọn bí ọmọbinrin alufaa kan bá jẹ́ opó, tabi tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ láì bímọ fún un, tí ó bá pada sí ilé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó wà ní ọdọmọbinrin, ó lè jẹ ninu oúnjẹ baba rẹ̀; sibẹsibẹ àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀.
14“Bí ẹnìkan bá jẹ ohun mímọ́ kan ní ìjẹkújẹ yóo san án pada fún alufaa pẹlu ìdámárùn-ún rẹ̀. 15Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ sọ àwọn ohun mímọ́ àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n fi ń rúbọ sí OLUWA di aláìmọ́. 16Kí wọ́n má baà mú àwọn eniyan náà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kó ẹ̀bi rù wọ́n nípa jíjẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; nítorí èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.”
17OLUWA tún rán Mose pé 18kí ó sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé: “Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn eniyan Israẹli tabi àlejò tí ó wà láàrin wọn bá mú ohun ìrúbọ rẹ̀ wá, kì báà ṣe pé láti fi san ẹ̀jẹ́ kan ni, tabi gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá, láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA, 19kí ohun ìrúbọ náà baà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, ó níláti jẹ́ akọ, tí kò ní àbùkù, ó lè jẹ́ akọ mààlúù, tabi àgbò, tabi òbúkọ. 20Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ó bá ní àbààwọ́n rúbọ, nítorí pé, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gbà á lọ́wọ́ yín. 21Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA láti san ẹ̀jẹ́, tabi fún ọrẹ àtinúwá; kì báà jẹ́ láti inú agbo mààlúù tabi láti inú agbo aguntan ni yóo ti mú ẹran ìrúbọ yìí, ó níláti jẹ́ pípé, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kan lára, kí ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. 22Bí ẹran náà bá jẹ́ afọ́jú, tabi amúkùn-ún, tabi ẹran tí ó farapa, tabi tí ara rẹ̀ ń tú, tabi tí ó ní èkúkú, ẹ kò gbọdọ̀ fi wọ́n fún OLUWA, tabi kí ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ sí OLUWA.#Diut 17:1 23Bí apá tabi ẹsẹ̀ mààlúù tabi àgbò kan bá gùn ju ekeji lọ, ẹ lè mú un wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àtinúwá, ṣugbọn OLUWA kò ní tẹ́wọ́gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹran ìrúbọ láti fi san ẹ̀jẹ́. 24Bí wọ́n bá tẹ ẹran kan lọ́dàá, tabi bí kóró abẹ́ rẹ̀ bá fọ́, tabi tí abẹ́ rẹ̀ fàya, tabi tí wọ́n la abẹ́ rẹ̀, tabi tí wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ ní abẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ mú un wá fún OLUWA, tabi kí ẹ fi rúbọ ninu gbogbo ilẹ̀ yín.
25“Bí ẹ bá gba irú ẹran bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò, ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ ohun jíjẹ sí èmi Ọlọrun yín. Níwọ̀n ìgbà tí àbùkù bá ti wà lára wọn, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gba irú wọn lọ́wọ́ yín, nítorí àbùkù náà.”
26OLUWA sọ fún Mose pé: 27“Nígbà tí mààlúù, aguntan, tabi ewúrẹ́ bá bímọ, ẹ fi ọmọ náà sílẹ̀ pẹlu rẹ̀ fún ọjọ́ meje, láti ọjọ́ kẹjọ lọ ni ó tó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ẹbọ sísun sí OLUWA. 28Ẹ kò gbọdọ̀ fi ìyá ẹran ati ọmọ rẹ̀ rúbọ ní ọjọ́ kan náà; kì báà jẹ́ mààlúù, tabi aguntan, tabi ewúrẹ́. 29Nígbà tí ẹ bá sì ń rú ẹbọ ọpẹ́ sí OLUWA, ẹ gbọdọ̀ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. 30Ẹ níláti jẹ gbogbo rẹ̀ tán ní ọjọ́ kan náà, kò gbọdọ̀ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èmi ni OLUWA.
31“Ẹ gbọdọ̀ ṣàkíyèsí òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́. Èmi ni OLUWA. 32Ẹ kò gbọdọ̀ ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, ẹ gbọdọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún mi láàrin gbogbo eniyan Israẹli. Èmi ni OLUWA tí mo sọ yín di mímọ́, 33tí mo sì ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti máa jẹ́ Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA.”

Currently Selected:

LEFITIKU 22: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in