YouVersion Logo
Search Icon

LEFITIKU 13

13
Àwọn Òfin tí ó Jẹmọ́ Àrùn Ara
1OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, 2“Nígbà tí ibìkan bá lé lára eniyan, tabi tí ara eniyan bá wú tí ọ̀gangan ibẹ̀ sì ń dán, tí ó bá jọ ẹ̀tẹ̀ ní ara rẹ̀, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ Aaroni, alufaa wá; tabi kí wọ́n mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Aaroni, tí ó jẹ́ alufaa. 3Kí alufaa náà yẹ ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà lára ẹni náà wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá di funfun, tí àrùn náà bá jẹ wọ inú ara ẹni náà lọ, tí ó jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, kí ó pè é ní aláìmọ́. 4Ṣugbọn bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun tí kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, kí alufaa ti abirùn náà mọ́lé fún ọjọ́ meje. 5Ní ọjọ́ keje, alufaa náà yóo yẹ abirùn náà wò, bí àrùn náà kò bá tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i. 6Nígbà tí ó bá tún di ọjọ́ keje, kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn náà wà bá bẹ̀rẹ̀ sí wòdú, tí àrùn náà kò sì tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́, ara rẹ̀ wú lásán ni; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì di mímọ́. 7Ṣugbọn bí ibi tí ó wú náà bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ní ara rẹ̀, lẹ́yìn tí ó fi ara rẹ̀ han alufaa fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó tún pada lọ fi ara han alufaa. 8Kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibi tí ó wú náà bá tàn káàkiri sí i ní ara rẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni.
9“Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ẹnìkan, kí wọ́n mú olúwarẹ̀ tọ alufaa lọ. 10Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibìkan bá wú ní ara rẹ̀, tí ó funfun, tí ó sì sọ irun ọ̀gangan ibẹ̀ di funfun, bí ibi tí ó wú yìí bá di egbò, 11a jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ gan-an ni ó wà ní ara ẹni náà. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; kí ó má wulẹ̀ tì í mọ́lé, nítorí pé aláìmọ́ ni. 12Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá bo gbogbo ara eniyan láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀ níwọ̀n bí alufaa ti lérò pé ó lè mọ lára eniyan, 13nígbà náà kí alufaa yẹ olúwarẹ̀ wò, bí àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí bá ti bo gbogbo ara rẹ̀ patapata, kí ó pè é ní mímọ́. Bí gbogbo ara rẹ̀ patapata bá ti di funfun, ó di mímọ́. 14Ṣugbọn gbàrà tí egbò kan bá ti hàn lára rẹ̀, ó di aláìmọ́. 15Kí alufaa yẹ ojú egbò náà wò, kí ó sì pe abirùn náà ní aláìmọ́, irú egbò yìí jẹ́ aláìmọ́ nítorí pé ẹ̀tẹ̀ ni. 16Ṣugbọn tí egbò yìí bá jiná, tí ojú rẹ̀ pada di funfun, kí ẹni náà pada tọ alufaa lọ. 17Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú egbò náà bá ti funfun, nígbà náà ni kí alufaa tó pe abirùn náà ní mímọ́, ó ti di mímọ́.
18“Bí oówo bá sọ eniyan lára, tí oówo náà sì san. 19Bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá wú, tí ó funfun tabi tí ó pọ́n, kí olúwarẹ̀ lọ fihan alufaa. 20Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí wúwú tí ó wú yìí bá jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, tí irun rẹ̀ bá sì funfun; kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni, ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde gẹ́gẹ́ bí oówo. 21Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, tí wúwú tí ó wú kò sì jìn ju awọ ara olúwarẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje. 22Bí àrùn yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri lára olúwarẹ̀, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. 23Ṣugbọn bí àmì yìí kò bá paradà níbi tí ó wà, tí kò sì tàn káàkiri, àpá oówo lásán ni, kí alufaa pe ẹni náà ní mímọ́.
24“Tabi bí iná bá jó eniyan lára, tí ó sì di egbò, tí ọ̀gangan ibẹ̀ bá pọ́n tabi tí ó funfun, 25kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò. Bí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun, tí ó sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; ẹ̀tẹ̀ ni ó jẹ jáde níbi tí iná ti jó olúwarẹ̀. Kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. 26Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò funfun, tí kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje. 27Ní ọjọ́ keje kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà bá ti bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri ara rẹ̀, kí alufaa pe ẹni náà ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. 28Bí ibi tí ó wú yìí bá wà bí ó ṣe wà, tí kò sì tàn káàkiri, ṣugbọn tí ó wòdú; àpá iná lásán ni, kí alufaa pè é ní mímọ́.
29“Bí ọkunrin tabi obinrin bá ní àrùn kan ní orí tabi ní irùngbọ̀n, 30kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá jìn wọnú ju awọ ara lọ, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ bá pọ́n, tí ó sì fẹ́lẹ́, kí alufaa pè é ní aláìmọ́; àrùn ẹ̀yi ni, tíí ṣe àrùn ẹ̀tẹ̀ irun orí tabi ti irùngbọ̀n. 31Bí alufaa bá yẹ àrùn ẹ̀yi yìí wò, tí kò bá jìn ju awọ ara lọ, tí irun dúdú kò sì hù jáde ninu rẹ̀, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje. 32Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ ẹni náà wò. Bí ẹ̀yi náà kò bá tàn káàkiri, tí irun ibẹ̀ kò sì pọ́n, tí ẹ̀yi náà kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ, 33kí ó fá irun orí tabi ti àgbọ̀n olúwarẹ̀, ṣugbọn kí ó má fá irun ọ̀gangan ibi tí ẹ̀yi náà wà. Kí alufaa tún ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i. 34Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ àrùn ẹ̀yi náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri sí i, tí kò sì jìn ju awọ ara lọ, kí alufaa pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì di mímọ́. 35Ṣugbọn bí àrùn ẹ̀yi yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí i tàn káàkiri lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́, 36kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ẹ̀yi náà bá ti gbilẹ̀ lára rẹ̀, kí alufaa má wulẹ̀ wò bóyá irun rẹ̀ pọ́n tabi kò pọ́n mọ́, aláìmọ́ ni. 37Ṣugbọn bí ẹ̀yi yìí bá ti dáwọ́ dúró, tí irun dúdú ti bẹ̀rẹ̀ sí hù ní ọ̀gangan ibẹ̀, ẹ̀yi náà ti san, ẹni náà sì ti di mímọ́. Kí alufaa pè é ní mímọ́.
38“Bí ibìkan lára ọkunrin tabi obinrin bá déédé ṣẹ́ funfun, 39kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun díẹ̀ tí ó dúdú díẹ̀, ara olúwarẹ̀ kàn fín lásán ni, ó mọ́.
40“Bí irun orí ọkunrin bá re, orí rẹ̀ pá ni, ṣugbọn ó mọ́. 41Bí irun orí ẹnìkan bá re, ní gbogbo iwájú títí dé ẹ̀bá etí rẹ̀, orí rẹ̀ pá ni; ó mọ́. 42Ṣugbọn bí ibi tí ó pá ní orí rẹ̀ tabi iwájú rẹ̀ yìí bá lé, tí ó sì pọ́n, ẹ̀tẹ̀ ni ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ jáde níbi tí orí tabi iwájú rẹ̀ ti pá. 43Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, tí ibi tí àrùn yìí ti wú ní orí tabi iwájú rẹ̀ bá pọ́n, tí ó sì dàbí ẹ̀tẹ̀ lára rẹ̀, 44adẹ́tẹ̀ ni ọkunrin náà, kò mọ́; alufaa sì gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́. Orí rẹ̀ ni àrùn yìí wà.
45“Ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ yìí gbọdọ̀ wọ aṣọ tí ó ya, kí ó fi apá kan irun orí rẹ̀ sílẹ̀ játijàti, kí ó bo ètè rẹ̀ òkè, kí ó sì máa ké pé, ‘Aláìmọ́! Aláìmọ́!’ 46Yóo jẹ́ aláìmọ́, níwọ̀n ìgbà tí àrùn yìí bá wà lára rẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́; òun nìkan ni yóo sì máa dá gbé lẹ́yìn ibùdó.
Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Kí Nǹkan Séèébu
47“Nígbà tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá wà lára aṣọ kan, kì báà jẹ́ pé òwú tabi irun tí wọ́n fi hun aṣọ náà, 48tabi lára aṣọkáṣọ, kì báà jẹ́ olówùú tabi onírun, tabi lára awọ, tabi lára ohunkohun tí a fi awọ ṣe. 49Bí ibi tí àrùn yìí wà bá bẹ̀rẹ̀ sí í pọ́n tabi, kí ó ní àwọ̀ bíi ti ewéko, kì báà jẹ́ aṣọ olówùú, tabi ti onírun, tabi kí ó jẹ́ awọ tabi ohunkohun tí a fi awọ ṣe, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni; dandan ni kí wọ́n fihan alufaa. 50Kí alufaa yẹ àrùn náà wò, kí ó sì ti aṣọ tí àrùn náà ràn mọ́ mọ́lé fún ọjọ́ meje. 51Kí ó yẹ àrùn ara aṣọ náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ti tàn káàkiri lára aṣọ tabi awọ náà, ohun yòówù tí wọ́n lè máa fi aṣọ náà ṣe, irú ẹ̀tẹ̀ tí ó máa ń ràn káàkiri ni; kò mọ́. 52Kí alufaa jó aṣọ náà, ibi yòówù tí àrùn náà lè wà lára rẹ̀, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohunkohun tí wọ́n fi awọ ṣe; nítorí pé irú àrùn tí ó máa ń ràn káàkiri ara ni; jíjó ni kí wọ́n jó o níná.
53“Bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà kò bá ràn káàkiri lára aṣọ náà tabi ohun èlò awọ náà, 54alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohun èlò tí àrùn wà lára rẹ̀ yìí, yóo sì tún tì í mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i. 55Alufaa yóo tún yẹ ohun èlò tí àrùn náà ràn mọ́ wò lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọ̀ ọ́. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn yìí ràn mọ́ kò bá mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tàn káàkiri sí i; sibẹ kò mọ́; jíjó ni ó níláti jó o níná, kì báà jẹ́ iwájú, tabi ẹ̀yìn aṣọ tabi awọ náà ni àrùn ràn mọ́. 56Ṣugbọn nígbà tí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí ó sì rí i pé àrùn náà ti wòdú lẹ́yìn tí a fọ aṣọ náà, kí ó gé ọ̀gangan ibẹ̀ kúrò lára ẹ̀wù, tabi aṣọ, tabi awọ náà. 57Bí ó bá tún jẹ jáde lára ẹ̀wù, tabi lára aṣọ, tabi ohun èlò aláwọ náà, a jẹ́ pé ó bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri nìyí, jíjó ni kí ó jó ohun èlò náà níná. 58Ṣugbọn ẹ̀wù tabi aṣọ, tabi ohun èlò awọ, tí àrùn yìí bá lọ kúrò lára rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀ ọ́, kí olúwarẹ̀ tún un fọ̀ lẹẹkeji, yóo sì di mímọ́.”
59Ó jẹ́ òfin tí ó jẹmọ́ àrùn ẹ̀tẹ̀ tí ó bá wà lára ẹ̀wù tabi aṣọ, láti fi mọ̀ bóyá ó mọ́ tabi kò mọ́, kì báà jẹ́ aṣọ onírun tabi olówùú, tabi ohun èlò aláwọ.

Currently Selected:

LEFITIKU 13: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in