JOBU 10
10
1“Ayé sú mi,
nítorí náà n kò ní dákẹ́ ìráhùn;
n óo sọ̀rọ̀ pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn.
2N óo sọ fún Ọlọrun pé
kí ó má dá mi lẹ́bi;
kí ó sì jẹ́ kí n mọ ìdí
tí ó fi ń bá mi jà.
3Ṣé ohun tí ó dára ni, Ọlọrun
pé kí o máa ni eniyan lára,
kí o kórìíra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
kí o sì fẹ́ràn ète ẹni ibi?
4Ǹjẹ́ ojú rẹ dàbí ti eniyan?
Ǹjẹ́ a máa rí nǹkan bí eniyan ṣe rí i?
5Ǹjẹ́ bí ọjọ́ ti eniyan ni ọjọ́ rẹ rí?
Ǹjẹ́ ọdún rẹ rí bíi ti eniyan?
6Tí o fi wá ń wádìí àṣìṣe mi,
tí o sì ń tanná wá ẹ̀ṣẹ̀ mi?
7Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ pé n kò lẹ́bi,
ati pé kò sí ẹnikẹ́ni
tí ó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ.#Ọgb 16:15
8Ọwọ́ rẹ ni o fi dá mi,
ọwọ́ kan náà ni o sì tún fẹ́ fi pa mí run.
9Ranti pé, amọ̀ ni o fi mọ mí,
ṣé o tún fẹ́ sọ mí di erùpẹ̀ pada ni?
10Ṣebí ìwọ ni o dà mí bí omi wàrà,
tí o sì ṣù mí pọ̀ bíi wàrà sísè?#Ọgb 7:1-2
11Ìwọ ni o fi awọ ati ẹran bò mí,
tí o rán egungun ati iṣan mi pọ̀.
12O fún mi ní ìyè,
o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi,
ìtọ́jú rẹ sì ti gbé ẹ̀mí mi ró.
13Sibẹ o pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́ sọ́kàn rẹ,
mo mọ̀ pé èrò ọkàn rẹ ni pé,
14bí mo bá ṣẹ̀, o óo dójú lé mi,
o kò ní jẹ́ kí n lọ láìjìyà.
15Bí mo bá ṣe àìdára, mo gbé,
ṣugbọn bí mo ṣe dáradára, n kò lè yangàn,
nítorí ìbànújẹ́ ati ìtìjú bò mí mọ́lẹ̀.
16Bí mo bá ṣe àṣeyọrí,
o óo máa lépa mi bíi kinniun;
ò ń lo agbára rẹ láti pa mí lára.
17O wá àwọn ẹlẹ́rìí tuntun pé kí wọ́n dojú kọ mí,
O tún bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí mi lọpọlọpọ,
O mú kí ogun mìíràn dó tì mí.
18“Kí ló dé tí o fi mú mi jáde láti inú ìyá mi?
Ìbá sàn kí n ti kú,
kí ẹnikẹ́ni tó rí mi.
19Wọn ìbá má bí mi rárá,
kí wọ́n gbé mi láti inú ìyá mi lọ sinu ibojì.
20Ṣebí ọjọ́ díẹ̀ ni mo níláti lò láyé?
Fi mí sílẹ̀ kí n lè ní ìtura díẹ̀,
21kí n tó pada síbi tí mo ti wá,
sí ibi òkùnkùn biribiri,
22ibi òkùnkùn ati ìdàrúdàpọ̀,
níbi tí ìmọ́lẹ̀ ti dàbí òkùnkùn.”
Currently Selected:
JOBU 10: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010